كَذَٰلِكَ نَقُصُّ عَلَيۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ مَا قَدۡ سَبَقَۚ وَقَدۡ ءَاتَيۡنَٰكَ مِن لَّدُنَّا ذِكۡرٗا 99
Apejuwe itan ti a sọ fun ọ -ire ojise- nipa itan Musa ati fir'aona ati iro nipa ijọ awọn mejeeji, a nsọ fun ọ iro awọn ti wọn ti siwaju ninu awọn Anọbi Ọlọhun ati awọn ijọ wọn ki o le jẹ itutu ẹmin fun ọ, paapaa a si ti fun ọ ni Alukuraani ki o le maa fi se iranti lati ọdọ wa fun ẹniti o ba fẹ se iranti.
مَّنۡ أَعۡرَضَ عَنۡهُ فَإِنَّهُۥ يَحۡمِلُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وِزۡرًا 100
Ẹnikẹni ti o ba gunri kuro nibi Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ ti ko nigbagbọ si i, ti ko si lo ohun ti o wa nibẹ; yoo wa ni ọjọ igbende ni ẹniti yoo gbe ẹsẹ ti o tobi, yoo si tun lẹtọ si ijiya inira.
خَٰلِدِينَ فِيهِۖ وَسَآءَ لَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ حِمۡلٗا 101
Wọn yoo maa wa ninu ijiya naa lọ lailai, bẹẹni ẹru ti wọn gbe yii buru ni ọjọ igbende.
يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِۚ وَنَحۡشُرُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ يَوۡمَئِذٖ زُرۡقٗا 102
Ọjọ ti Malaika yoo fan fere si inu iwo ni ifanfere ẹlẹẹkeji fun ajinde, ti a o si ko awọn keferi jọ ni ọjọ naa, ti wọn yoo di awọ aweko nitori yiyipada awọn wọn ati oju wọn nibi lile koko ohun ti wọn ba pade nibi ipaya ọjọ ikẹyin.
يَتَخَٰفَتُونَ بَيۡنَهُمۡ إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا عَشۡرٗا 103
Wọn yoo maa sọrọ kẹlẹkẹlẹ pẹlu gbolohun wọn, awa ko lo ninu isẹmin agede meji lẹyin iku ayaafi oru mẹwa.
نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَقُولُونَ إِذۡ يَقُولُ أَمۡثَلُهُمۡ طَرِيقَةً إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا يَوۡمٗا 104
Awa ni amọ ohun ti wọn nsọ ni kẹlẹ kẹlẹ, nkankan ko pamọ fun Wa nibẹ, nigbati ẹniti o ni laakaye ninu wọn sọ wipe, a ko lo ninu agede meji aye ayaafi ọjọ kan ti ko pọ ju bẹẹ lọ.
وَيَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡجِبَالِ فَقُلۡ يَنسِفُهَا رَبِّي نَسۡفٗا 105
Wọn yoo bi ọ leere - irẹ ojisẹ - nipa oke ni ọjọ igbende ki o sọ fun wọn: oke ẹniti yoo wu u tidi tidi ni lati ipilẹ rẹ ati egbo rẹ ni Ọlọhun mi, yoo wa ku danu.
فَيَذَرُهَا قَاعٗا صَفۡصَفٗا 106
Yoo wa fi ile ti o gbe dani silẹ ni pẹrẹsẹ, ti ko nii si nkan mimọ kankan ni ori rẹ tabi irugbin.
لَّا تَرَىٰ فِيهَا عِوَجٗا وَلَآ أَمۡتٗا 107
Iwọ ko nii ri - irẹ ti o nwo o - ni ori ilẹ nibi sise pẹrẹsẹ rẹ tan yan yan ibusọ kan tabi ibi giga kan tabi isọkalẹ si kankan.
يَوۡمَئِذٖ يَتَّبِعُونَ ٱلدَّاعِيَ لَا عِوَجَ لَهُۥۖ وَخَشَعَتِ ٱلۡأَصۡوَاتُ لِلرَّحۡمَٰنِ فَلَا تَسۡمَعُ إِلَّا هَمۡسٗا 108
Ni ọjọ yii awọn eniyan yoo tẹle ohun olupepe lọsi ibi akojọ, ko si nii si ohun ti yoo maa gun wọn lori kuro nibi titẹle e, gbogbo ohun yoo si dakẹ fun Ọba Ajọkẹ Aye niti iwariri, iwọ ko nii gbọ ni ọjọ yii ju ohun kẹlẹkẹlẹ lọ.
يَوۡمَئِذٖ لَّا تَنفَعُ ٱلشَّفَٰعَةُ إِلَّا مَنۡ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَرَضِيَ لَهُۥ قَوۡلٗا 109
Ni ọjọ ti o tobi yii ipẹ ko nii se anfaani ni ọdọ olusipẹ kankan ayaafi olusipẹ ti Allah ba yọnda fun pe ki o sipẹ, ti o si yọnu si gbolohun rẹ nibi ipẹ.
يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَلَا يُحِيطُونَ بِهِۦ عِلۡمٗا 110
Allah ti mimọ nbẹ fun mọ ohun ti ọmọniyan yoo ba pade nnu ọrọ ikẹyin, O si mọ ohun ti wọn fi sẹyin ni ile aye wọn, gbogbo ẹru ko le mọ titobi Ọlọhun ati iroyin Rẹ niti imọ gan an.
۞وَعَنَتِ ٱلۡوُجُوهُ لِلۡحَيِّ ٱلۡقَيُّومِۖ وَقَدۡ خَابَ مَنۡ حَمَلَ ظُلۡمٗا 111
Gbogbo oju ẹru yoo si yẹpẹrẹ, wọn yoo kọlẹ fun Ọba Alaaye ẹniti kii ku, ẹniti O wa lori alamọri ọrọ ẹru Rẹ nibi didari ati yiyii pada, paapaa ẹniti o gbe ẹsẹ dani pẹlu didari ẹmin rẹ si ibi iparun.
وَمَن يَعۡمَلۡ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَا يَخَافُ ظُلۡمٗا وَلَا هَضۡمٗا 112
Ẹniti o ba se awọn isẹẹre, ti o si nigbagbọ ninu Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, ọwọ rẹ yoo tẹ ẹsan rẹ ni pipe, ko ni paya abosi debi ki wọn fi iya ẹsẹ ti ko sẹ jẹ ẹ, bẹẹni ko nii si ẹdinku fun ẹsan isẹ rere rẹ.
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا وَصَرَّفۡنَا فِيهِ مِنَ ٱلۡوَعِيدِ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ أَوۡ يُحۡدِثُ لَهُمۡ ذِكۡرٗا 113
Apejuwe iru ohun ti a sọkalẹ ninu itan awọn ti o siwaju, a sọ Alukuraani yii kalẹ pẹlu ahọn larubawa ti o fi oju han, a si se alaye oniranran adehun iya bi idẹruba ati ipani laya; ni ireti ki wọn le paya Allah ati ki Alukuraani bi igba isiti ati iwoye fun wọn.
Alukuraani ti o tobi gbogbo rẹ jẹ iranti ati isiti fun awọn ijọ, ọdọ ati ẹnikọọkan, o si tun jẹ iyi ati iyanran fun ọmọniyan.
Ipẹ ko le se anfaani fun ẹnikẹni ayaafi ipẹ ẹniti Ọlọhun Ọba Ajọkẹ Aye ba yọnda fun, ti o si yọnu si gbolohun rẹ nibi ipẹ.
Alukuraani kun fun eyi ti o dara ju ninu idajọ, eyiti laakaye ati adamọ yoo tọka si didara rẹ ati pipe rẹ.
Ninu ẹkọ ibalopọ pẹlu Alukuraani ni ki eniyan maa gba pẹlu gbigba wọle ati jijupa jusẹ silẹ fun un ati gbigbe titobi fun un ati wiwa imọna pẹlu imọlẹ rẹ si oju ọna ti o duro tọ, ati dida oju kọ pẹlu kikọ ọ ati fifi kọ ẹlomiran.
Abamọ awọn ẹlẹsẹ ni ọjọ igbende nitoris rira ọpọlọpọ asiko lare, ti wọn si lo o niti igbagbe ati ere ni ẹniti ngunri nibi ohun ti yoo se wọn lanfaani, ti wọn si da oju kọ ohun ti yoo ko inira ba wọn.