قَالَ هَٰذَا رَحۡمَةٞ مِّن رَّبِّيۖ فَإِذَا جَآءَ وَعۡدُ رَبِّي جَعَلَهُۥ دَكَّآءَۖ وَكَانَ وَعۡدُ رَبِّي حَقّٗا 98
Dhul-Qarnayn sọpe: idigaga yoo jẹ ikẹ lati ọdọ Ọlọhun mi, ti yoo kọdi laarin yaajuuja ati maajuuja ati ibajẹ si ori ilẹ, yoo si kọ fun wọn kuro nibẹ, ti asiko ti Ọlọhun Allah fi lelẹ lati jade nibẹ ba to siwaju ọjọ igbende, yoo sọ di pẹrẹsẹ ni ori ilẹ, adehun Allah jẹ ohun ti ko nii yapa pẹlu lori sisọ ilẹ di pẹrẹsẹ ati jijade yaajuuja ati maajuja ti o rinlẹ.
۞وَتَرَكۡنَا بَعۡضَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ يَمُوجُ فِي بَعۡضٖۖ وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَجَمَعۡنَٰهُمۡ جَمۡعٗا 99
A fi apakan ninu awọn ẹda di ọjọ ikeyin, ti wọn yoo maa daamun, ti yoo si maa lu papọ mọ ara wọn, ti a ba fọn fere, ti a si ko gbogbo ẹda jọ fun isiro ati ẹsan.
وَعَرَضۡنَا جَهَنَّمَ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡكَٰفِرِينَ عَرۡضًا 100
Ti a si mu jahannamo hande niti hihande fun awọn keferi, ti ko si iroju nibẹ lati le ri ni rimi nri ọ.
ٱلَّذِينَ كَانَتۡ أَعۡيُنُهُمۡ فِي غِطَآءٍ عَن ذِكۡرِي وَكَانُواْ لَا يَسۡتَطِيعُونَ سَمۡعًا 101
A fi han awọn keferi ti wọn jẹ afọju si iranti Allah ni ile aye; nitori gaga ti nbẹ ni oju wọn ti o kọ fun nibi eleyi, wọn jẹ ẹniti ko nikapa lati gbọ awọn aayah Allah nigbigbọ gbigba.
أَفَحَسِبَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَن يَتَّخِذُواْ عِبَادِي مِن دُونِيٓ أَوۡلِيَآءَۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا جَهَنَّمَ لِلۡكَٰفِرِينَ نُزُلٗا 102
Se awọn keferi si Allah lero wipe Allah wipe awọn yoo sọ awọn ẹru Mi ninu awọn Malaika ati awọn ojisẹ ati awọn esu di olujọsin fun yatọ si Emi Allah ni?! Dajudaju Awa se jahannamo ni ipalese fun awọn keferi gẹgẹ bi ibusọkalẹ ti wọn yoo duro si.
قُلۡ هَلۡ نُنَبِّئُكُم بِٱلۡأَخۡسَرِينَ أَعۡمَٰلًا 103
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: se a fun yin niro -ẹyin eniyan- nipa ẹniti o sofo ju ninu awọn eniyan nitori isẹ rẹ?
ٱلَّذِينَ ضَلَّ سَعۡيُهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُمۡ يَحۡسَبُونَ أَنَّهُمۡ يُحۡسِنُونَ صُنۡعًا 104
Awọn ti yoo ri ọjọ igbende wipe isẹ wọn ti wọn ni ile aye di ohun ti o ti rare, wọn si jẹ ẹniti o le wipe awọn se daadaa nibi igbesẹ wọn tabi awọn yoo se anfaani nibi isẹ wọn sugbọn ohun ti yoo sẹlẹ yapa si eleyi.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَِٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ وَلِقَآئِهِۦ فَحَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فَلَا نُقِيمُ لَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَزۡنٗا 105
Awọn wọnyi ni wọn se keferi si awọn aayah Ọlọhun Ọba wọn eyiti o ntọka si ọkan soso Rẹ, wọn si se keferi si pipade Rẹ, isẹ wọn bajẹ nitori sise keferi wọn si I, wọn ko waa ni ni ipin kankan ni ọjọ igbende ni ọdọ Allah.
ذَٰلِكَ جَزَآؤُهُمۡ جَهَنَّمُ بِمَا كَفَرُواْ وَٱتَّخَذُوٓاْ ءَايَٰتِي وَرُسُلِي هُزُوًا 106
Eleyi ni ẹsan ti a pese fun wọn tii se jahannamo nitori sise keferi wọn si Allah ati mimu awọn amin wa ti a sọkalẹ ati awọn ojisẹ Wa ni yẹyẹ. si wipe:
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah sọ ẹsan awọn keferi, O tun sọ ẹsan awọn olugbagbọ ododo, O
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ كَانَتۡ لَهُمۡ جَنَّٰتُ ٱلۡفِرۡدَوۡسِ نُزُلًا 107
Dajudaju awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nse ọpọlọpọ isẹẹre, eyiti o ga ninu Alujannah nbẹ fun wọn ni ibudesi lati se apọnle fun wọn.
خَٰلِدِينَ فِيهَا لَا يَبۡغُونَ عَنۡهَا حِوَلٗا 108
Wọn yoo maa wa nibẹ lailai, wọn ko nii wa igberakuro nibẹ; nitoripe ẹsan kankan ko sun mọ ọ.
قُل لَّوۡ كَانَ ٱلۡبَحۡرُ مِدَادٗا لِّكَلِمَٰتِ رَبِّي لَنَفِدَ ٱلۡبَحۡرُ قَبۡلَ أَن تَنفَدَ كَلِمَٰتُ رَبِّي وَلَوۡ جِئۡنَا بِمِثۡلِهِۦ مَدَدٗا 109
Sọ wipe - ire ojise -: dajudaju awọn gbolohun Ọlọhun Ọba mi pọ, ti odo ba jẹ tadaa fun un, ti wọn fi kọ ọ, omin odo naa yoo tan siwaju titan awọn gbolohun Rẹ ti mimọ nbẹ fun, koda bi a ba mu awọn odo miran wa, paapaa ohun naa yoo tan bakanaa.
قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُوحَىٰٓ إِلَيَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ فَمَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ رَبِّهِۦ فَلۡيَعۡمَلۡ عَمَلٗا صَٰلِحٗا وَلَا يُشۡرِكۡ بِعِبَادَةِ رَبِّهِۦٓ أَحَدَۢا 110
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: dajudaju emi jẹ abara gẹgẹ bi yin, ti imisi nwa ba mi wipe dajudaju ẹni ijọsin fun yin ni tootọ jẹ ẹni ijọsin fun kan soso, ko si orogun fun Un, Oun si ni Allah, ẹniti o ba npaya ipade Ọlọhun Ọba rẹ ki o ya maa se isẹ eyiti yoo se deedee ofin Rẹ, ki o si maa se afọmọ nibẹ fun Ọlọhun Ọba rẹ, ko gbọdọ mu nkan miran nibi ijọsin Ọlọhun Ọba rẹ.
Fifi igbende ati ikojọ rinlẹ lati ibi pipa alujannu ati eniyan pọ si igbagede igbende pẹlu fifan fere ẹlẹẹkeji si inu iwo.
Dajudaju eniyan ti o sofo ju ni ọjọ igbende ni awọn ti wahala wọn rare ni ile aye, ti wọn si nlero wipe awọn se daadaa ni isẹ nibẹ ijọsin fun ẹniti o yatọ si Allah.
Ko rọrun kika awọn gbolohun Allah ti O ga julọ ati imọ Rẹ ati ọgbọn Rẹ ati awọn asiri Rẹ koda bi awọn odo ati awọn omin miran ti o rọkirika ati awọn nkan miran ti o yatọ si i ti a ko le fi aala si bajẹ tadaa ti wọn fi kọ ọ.