يَقۡدُمُ قَوۡمَهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَأَوۡرَدَهُمُ ٱلنَّارَۖ وَبِئۡسَ ٱلۡوِرۡدُ ٱلۡمَوۡرُودُ 98
Fir'aona yoo gbawaju awọn ijọ rẹ ni ọjọ igbende losi inu ina titi yoo fi ti wọn wo ibẹ, ibukosi aburu eyi ti o mu wọn ko si yii.
وَأُتۡبِعُواْ فِي هَٰذِهِۦ لَعۡنَةٗ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ بِئۡسَ ٱلرِّفۡدُ ٱلۡمَرۡفُودُ 99
Ọlọhun Ọba Allah yoo tun fi igbejina si ikẹ ati ilenijinna ati imunijinna si ikẹ Rẹ tẹle e ni isẹmi aye pẹlu ohun ti o sẹlẹ si wọn ninu iparun itẹle, yoo si tun fi lile wọn ati mimu wọn jinaa si tẹle e ni ọjọ igbende naa, nkan ti o sẹlẹ si wọn yii buru lati ara si sisẹ ntẹle igbejinna si ikẹ meji ati ijiya ile aye ati ọrun.
ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡقُرَىٰ نَقُصُّهُۥ عَلَيۡكَۖ مِنۡهَا قَآئِمٞ وَحَصِيدٞ 100
Eyiti a sọ yii ninu suura yii ninu awọn iroyin abule ti a fi to ọ leti - ire ojise -, o wa ninu awọn abule yii eyiti awọn amin wa nibẹ, o si wa ninu rẹ eyiti awọn amin ibẹ ti parẹ, ti oripa kankan ko sẹku nibẹ.
وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡۖ فَمَآ أَغۡنَتۡ عَنۡهُمۡ ءَالِهَتُهُمُ ٱلَّتِي يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖ لَّمَّا جَآءَ أَمۡرُ رَبِّكَۖ وَمَا زَادُوهُمۡ غَيۡرَ تَتۡبِيبٖ 101
Awa ko se abosi si wọn latara iparun ti a fi kan wọn sugbọn awọn ni wọn se abosi ẹmin ara wọn lati ara mimu lọ si ibi iparun lati ara sise keferi si Allah, awọn ọlọhun wọn ti wọn nsin ko si daabobo wọn kuro nibi iya ti o sọkalẹ nigbati asẹ Ọlọhun Ọba rẹ de –ire ojise- pẹlu pipa wọn run, awọn ọlọhun wọn ko se alekun nkankan fun wọn ju ofo ati iparun lọ.
وَكَذَٰلِكَ أَخۡذُ رَبِّكَ إِذَآ أَخَذَ ٱلۡقُرَىٰ وَهِيَ ظَٰلِمَةٌۚ إِنَّ أَخۡذَهُۥٓ أَلِيمٞ شَدِيدٌ 102
Bayi ni igbamun ati ipani finfin eyiti Ọlọhun Ọba fi gba awọn abule onirọ mu ni gbogbo asiko ati aaye se ri, dajudaju igbamun Rẹ fun awọn abule alabosi jẹ igbamun inira ti o lagbara.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّمَنۡ خَافَ عَذَابَ ٱلۡأٓخِرَةِۚ ذَٰلِكَ يَوۡمٞ مَّجۡمُوعٞ لَّهُ ٱلنَّاسُ وَذَٰلِكَ يَوۡمٞ مَّشۡهُودٞ 103
Dajudaju nibi igbamun lile eyiti o sẹlẹ si awọn ijọ alabosi jẹ ariwoye ati isiti fun ẹniti o ba npaya ọjọ igbende, ọjọ yii ni Ọlọhun Ọba Allah yoo ko gbogbo awọn eniyan jọ lati se isiro isẹ wọn, ọjọ naa jẹ ọjọ ẹri ti gbogbo awọn ẹni ikojọ yoo jẹri si.
وَمَا نُؤَخِّرُهُۥٓ إِلَّا لِأَجَلٖ مَّعۡدُودٖ 104
Awa ko nii lọ ọjọ ẹri yii lara ayaafi pẹlu idi ti a mọ ti o ni onka.
يَوۡمَ يَأۡتِ لَا تَكَلَّمُ نَفۡسٌ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ فَمِنۡهُمۡ شَقِيّٞ وَسَعِيدٞ 105
Ọjọ ti ọjọ yii yoo wa ẹmin kankan ko nii le sọ awijare tabi sipẹ ayaafi lẹyin iyọnda Rẹ bẹẹ ni awọn neiyan yoo jẹ iran meji nibẹ: olori buruku ti yoo wọna ati oloriire ti yoo wọ Alujannah.
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ شَقُواْ فَفِي ٱلنَّارِ لَهُمۡ فِيهَا زَفِيرٞ وَشَهِيقٌ 106
Awọn oloriibu nitori keferi wọn ni ati isẹ ibajẹ wọn, wọn yoo wa wọ ina, wọn yoo maa gbe ohun wọn soke ati imisi wọn nitori lilekoko ohun ti wọn nfi ara kin nitori ahọn ina ibẹ.
خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَۚ إِنَّ رَبَّكَ فَعَّالٞ لِّمَا يُرِيدُ 107
Wọn yoo maa wa nibẹ gbere, wọn ko si nii le jade nibẹ niwọn ba igba ti sanmọ ati ilẹ ba nbẹ ayaafi ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba gbero lati mu jade ninu awọn ẹlẹsẹ ti o nigbagbọ ọkan soso, dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ -ire ojise- oluse ohun ti o wu nii se, olujẹni nipa kan ko si fun.
۞وَأَمَّا ٱلَّذِينَ سُعِدُواْ فَفِي ٱلۡجَنَّةِ خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَۖ عَطَآءً غَيۡرَ مَجۡذُوذٖ 108
Sugbọn awọn oloriire ni awọn ti oriire ti gbawaju fun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nitori igbagbọ wọn ati isẹẹre wọn, wọn yoo maa wa ninu alujannah gbere ni ẹniti yoo maa gbebẹ lailai niwọn igba ti sanmọ ati ilẹ ba nbẹ ayaafi ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba gbero lati ki wọ inu ina siwaju alujannah ninu awọn ẹlẹsẹ olugbagbọ ododo, dajudaju idẹkun Allah fun awọn ẹni Alujannah kii se nkan ti yoo lopin.
Sise ikilọ lati mase tẹle awọn adari aburu ati ibajẹ ati sise alaye alamọri ọrọ awọn olutẹle wọn ni aye ati lọrun.
Ọlọhun Ọba Allah ti o ga mọ kanga kuro nibi abosi lori pipa awọn ẹni ẹbọ run ati awọn ẹlẹsẹ.
ọlọhun awọn ẹlẹbọ ko nii se anfaani fun awọn ti nsin in ni ọjọ igbende, ko si ni mu iya kuro fun wọn.
Pinpin awọn neiyan ni ọjọ igbende alukiyamọ si oloriire ti yoo maa gbe inu alujannah ati oloriibu ti yoo maa gbe inu ina lọ gbere.