فَلَوۡلَا كَانَتۡ قَرۡيَةٌ ءَامَنَتۡ فَنَفَعَهَآ إِيمَٰنُهَآ إِلَّا قَوۡمَ يُونُسَ لَمَّآ ءَامَنُواْ كَشَفۡنَا عَنۡهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ 98
Ko sẹlẹ wipe abule kan ninu awọn abule ti a ran awọn ojisẹ wa si wọn yoo ni igbagbọ ni igbagbọ olumura silẹ siwaju ki wọn o to fi oju ri iya, ti igbagbọ wọn yoo waa se wọn ni anfaani nitori dide rẹ siwaju riri iya ayaafi ijọ yuunus nigbati wọn ni igbagbọ ododo, a gbe iya iyẹpẹrẹ ati idojuti kuro fun wọn ni isẹmin aye, a si fun wọn ni idẹkun titi ti asiko wọn fi tan.
وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ لَأٓمَنَ مَن فِي ٱلۡأَرۡضِ كُلُّهُمۡ جَمِيعًاۚ أَفَأَنتَ تُكۡرِهُ ٱلنَّاسَ حَتَّىٰ يَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ 99
Ti Ọlọhun Ọba rẹ ba fẹ -ire ojise- igbagbọ gbogbo ẹniti nbb lori ilẹ, wọn ko ba nigbagbọ sugbọn ko fẹ eleyi nitori ọgbọn kan, o nfi ẹniti o wu U sinu isina lati ara deedee Rẹ, O si nfi ẹniti o Wu U mọ ọna lati ara ọla Rẹ, ko si ninu ikapani rẹ ki o jẹ ẹniyan nipa ki wọn o jẹ olugbagbọ, sise kongẹ igbagbọ wọn wa ni ọwọ Allah nikan.
وَمَا كَانَ لِنَفۡسٍ أَن تُؤۡمِنَ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَيَجۡعَلُ ٱلرِّجۡسَ عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يَعۡقِلُونَ 100
Ko tọ fun ẹmin kan ki o nigbagbọ lati ọdọ ara rẹ ayaafi pẹlu iyọnda Allah, igbagbọ ko le sẹlẹ ayaafi pẹli ikẹ Rẹ, mase mu ẹmin rẹ lọ si ibi ofo ki Ọlọhun Ọba Allah mase fi iya ati idojuti si ọdọ awọn ti ko mọ awọn ẹri Rẹ ati awọn asẹ Rẹ ati awọn nkan ti O kọ.
قُلِ ٱنظُرُواْ مَاذَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَا تُغۡنِي ٱلۡأٓيَٰتُ وَٱلنُّذُرُ عَن قَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ 101
Sọ - ire ojise - fun awọn ẹlẹbọ ti wọn nbi ọ leere nipa awọn amin tabi awọn aayah: ẹ ronu si ohun ti nbẹ ninu sanma ati ilẹ ninu awọn amin ti ntọka si ijọkan soso Allah ati agbara Rẹ, ati anfaani ti sisọkalẹ awọn aayah ati awọn ẹri ati awọn ojisẹ yoo se ni ara ijọ ti ko ni imura silẹ lati gbagbọ; nitori titako lori keferi.
فَهَلۡ يَنتَظِرُونَ إِلَّا مِثۡلَ أَيَّامِ ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ قُلۡ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ 102
Se awọn opurọ yii nreti nkankan ju ohun ti Ọlọhun Ọba Allah ni ko sẹlẹ lori awọn ijọ opurọ ti o kọja lọ?! Sọ -ire ojise- fun wọn: ẹ maa reti iya Allah, ẹmi naa wa pẹlu yin ni ẹniti nreti adehun Ọlọhun Ọba mi.
ثُمَّ نُنَجِّي رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ حَقًّا عَلَيۡنَا نُنجِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 103
Lẹyin yii a o sọ iya kalẹ fun wọn, a o si la awọn ojisẹ wa, bẹẹ ni a o tun la awọn ti o ni igbagbọ si wọn, ko nii sẹlẹ si wọn ohun ti o sẹlẹ si awọn ijọ wọn, gẹgẹ bi a se la awọn ojisẹ naa ati awọn olugbagbọ ododo pẹlu wọn, a o la ojisẹ Allah ati awọn olugbagbọ ododo naa mọ wọn ni lila ti ododo, ifẹsẹrinlẹ lati ọdọ Wa.
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي شَكّٖ مِّن دِينِي فَلَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِنۡ أَعۡبُدُ ٱللَّهَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُمۡۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 104
Sọ - ire ojise - ẹyin eniyan, ti ẹ ba nwa ninu iyemeji nibi ẹsin wa eyiti a npe yin sibẹ ohun ni ẹsin rẹ kan soso Ọlọhun Ọba, emi wa lori amọdaju wipe jijẹ ibajẹ ẹsin yin, emi ko si nii tẹle, emi ko nii sin ohun ti ẹ nsin yatọ si Allah sugbọn emi yoo maa sin ẹniti yoo pa yin, ti o si pa mi lasẹ ki njẹ ọkan ninu awọn olugbagbọ ododo, oluse afọmọ ẹsin fun Un.
وَأَنۡ أَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفٗا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ 105
O tun pa mi lasẹ bakanna wipe ki nduro lori ẹsin ododo, ki nsi rinlẹ lori rẹ ni ẹniti yoo fi kuro nibi ẹsin miran, o si kọ fun mi ki nwa ninu awọn ẹlẹbọ si I.
وَلَا تَدۡعُ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَۖ فَإِن فَعَلۡتَ فَإِنَّكَ إِذٗا مِّنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 106
Mase pe - ire ojise - oosa, ẹbọ ati ohun ti o yatọ si dipo Allah, nkan ti ko le se anfaani debi yoo se ọ ni anfaani, bẹẹ ni ko nikapa inira debi yoo ni ọ lara, ti o ba jọsin fun, o ti wa ninu awọn alabosi ni yi, awọn olukọja ẹnu aala ẹtọ Ọlọhun Ọba Allah ati ẹtọ ara wọn.
Igbagbọ ni okunfa agbega ẹniti o ba ni i de awọn ipo ti o ga ati igbadun ninu isẹmin aye.
Ko si ninu ikapa ẹnikẹni lati gbe ẹnikankan de ibi igbagbọ; toripe eleyi jẹ ohun ti yoo sẹri si ibib fifẹ Ọlọhun Ọba nikan soso.
Awọn aayah ati ikilọ ko le se anfaani fun ẹniti o ba taku lori keferi, ti o si ntẹsiwaju lori rẹ.
Jijẹ dandan iduro sinsin lori ẹsin ododo ati jijinna ni gbogbo jijinna kuro nibi ẹbọ ati awọn ẹsin ibajẹ.