أُحِلَّ لَكُمۡ صَيۡدُ ٱلۡبَحۡرِ وَطَعَامُهُۥ مَتَٰعٗا لَّكُمۡ وَلِلسَّيَّارَةِۖ وَحُرِّمَ عَلَيۡكُمۡ صَيۡدُ ٱلۡبَرِّ مَا دُمۡتُمۡ حُرُمٗاۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ 96
Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ fun yin idẹdẹ awọn ẹran inu omin, ati ohun ti omin pọ fun yin, laaye ni tabi ni oku, ki o le jẹ anfaani fun ẹniti o ngbele ninu yin tabi onirin ajo ni esenpa fun un, O si se didẹdẹ nkan ti nbẹ ni ori ilẹ ni eewọ fun yin nigba kiigba ti ẹ ba jẹ ẹniti o gbe urumu hajj tabi umrah, ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle asẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti o kọ, toripe Oun nkan ẹ yoo sẹri si ni ọjọ igbende, yoo si san yin lẹsan lori awọn isẹ yin.
۞جَعَلَ ٱللَّهُ ٱلۡكَعۡبَةَ ٱلۡبَيۡتَ ٱلۡحَرَامَ قِيَٰمٗا لِّلنَّاسِ وَٱلشَّهۡرَ ٱلۡحَرَامَ وَٱلۡهَدۡيَ وَٱلۡقَلَٰٓئِدَۚ ذَٰلِكَ لِتَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَأَنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ 97
Ọlọhun Ọba Allah se kaaba, tii se ilke ewọ ni aaye idurosi fun awọn eniyan, lati ara rẹ ni isẹmin ẹsin wọn yoo fi dara, bii irun kiki ati hajj ati umrah, bẹẹ ni alamọri aye wọn yoo si tun dara pẹlu ifẹkan balẹ ni aaye ọwọ naa ati sisẹri gbogbo nkan eleso pata lọ si ibẹ, O si se awọn osu ọwọ ni: (Dhul Qọadah, Dhul Hijjah, Muharram ati Rajab) , ibuduro si fun ifọkanbọlẹ wọn, ki ẹlomkiran mọ baa pa wọn, bẹẹ ni ẹran itanran ati amin ti a fi ndaamọ jẹ ohun ti a o dari si aye ọwọ naa, ki o le jẹ ibuduro si fun wọn lati le fi wọn lọkan balẹ ni ọdọ awọn ti wọn le se wọn ni suta, eleyi ni idẹkun ti Ọlọhun Ọba Allah se le yin lori, ki ẹ le mọ wipe Ọlọhun Ọba Allah mọ ohun ti nbẹ ninu sanmọ mejeeji ati ilẹ, ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nimọ nipa gbogbo nkan, dajudaju eleyi ni ofin - lati le fa oore fun yin, ati kọ aburu fun yin siwaju ki o to sẹlẹ - o jẹ ẹri lori imọ Ọlọhun Ọba Allah si ohun ti o le wulo fun awọn ẹru Rẹ.
ٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ وَأَنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 98
Ki ẹ lọ mọ - ẹyin eniyan - dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ ẹniti iya rẹ le koko fun ẹniti o ba sẹ Ẹ, o si jẹ oluforijinni fun oluronu piwada, bẹẹ ni Yoo kẹ.
مَّا عَلَى ٱلرَّسُولِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُبۡدُونَ وَمَا تَكۡتُمُونَ 99
Ko si ohun ti o jẹ ọranyan fun ojisẹ naa ju ki o mu asẹ Ọlọhun Ọba Allah de ogongo lọ, kii se dandan fun ki o fi awọn eniyan se ọnọọmọ, eleyi wa ni ọwọ Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, Ọlọhun Ọba Allah mọ ohun ti ẹ se afihan rẹ ati eyi ti ẹ se afipamọ rẹ ninu imọna ati isina. Yoo si san yin lẹsan le lori.
قُل لَّا يَسۡتَوِي ٱلۡخَبِيثُ وَٱلطَّيِّبُ وَلَوۡ أَعۡجَبَكَ كَثۡرَةُ ٱلۡخَبِيثِۚ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 100
Sọ wipe - ire ojise - ohun ti ko dara nibi gbogbo nkan, ko le se deede ohun ti o da nibi gbogbo nkan, koda ki pipọ rẹ jọ ọ loju, tori wipe pipọ rẹ ko tọka si ọla ti o wa fun un, ki ẹ paya Allah - ẹyin onilaakaye - pẹlu gbigbe ohun ti ko dara ju silẹ, ki ẹ si maa se ohun ti o dara ki ẹ le ba jere Alujannah.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَسَۡٔلُواْ عَنۡ أَشۡيَآءَ إِن تُبۡدَ لَكُمۡ تَسُؤۡكُمۡ وَإِن تَسَۡٔلُواْ عَنۡهَا حِينَ يُنَزَّلُ ٱلۡقُرۡءَانُ تُبۡدَ لَكُمۡ عَفَا ٱللَّهُ عَنۡهَاۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٞ 101
Ẹyin onigbagbọ ododo, ẹ ma beere ọpọ nkan ni ọdọ ojisẹ yin, ti ẹ ko si ni bukaata sii, ti kii sii se ohun ti o le ran yin lọwọ lori ẹsin yin, ti o ba han si yin, yoo ko inira ba yin nitori idaamu ti o wa nibẹ, ti ẹ ba nbeere nipa awọn nkan wọnyi, eyi ti wọn ti kọ fun yin pe ki ẹ ma beere rẹ ni igbati imisi ti waa ba ojisẹ yin, ti o se alaye fun yin, eleyi rọrun fun Ọlọhun Ọba Allah, paapa o si ti se amoju kuro nibi awọn nkan ti Alukuraani dakẹ nipa rẹ, ẹ mase beere nipa rẹ, tori wipe ti ẹ ba beere nipa rẹ, nkan ti ẹ ko lagbara ni yoo sọkalẹ le yin lori nipa rẹ, Olohun Oba Allah je alaforijin fun awon ẹsẹ ẹrusin rẹ nigbati won ba ronu piwada, Onisuuru ni lati fi iya jẹ wọn.
قَدۡ سَأَلَهَا قَوۡمٞ مِّن قَبۡلِكُمۡ ثُمَّ أَصۡبَحُواْ بِهَا كَٰفِرِينَ 102
Awọn ijọ kan ti beere nipa iru rẹ siwaju yin, nigbati wọn la bọ wọn lọrun nipa rẹ, wọn ko lee se e, wọn di keferi latara rẹ.
مَا جَعَلَ ٱللَّهُ مِنۢ بَحِيرَةٖ وَلَا سَآئِبَةٖ وَلَا وَصِيلَةٖ وَلَا حَامٖ وَلَٰكِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۖ وَأَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ 103
Ọlọhun Ọba Allah se awọn ẹran ni ẹtọ fun yin, ko si se leewọ le yin lori, eyiti awọn ọlọsẹbọ se leewọ lori ara wọn, lati ọdọ oosa wọn, bii bahiiraọ tii se rakunmi eyiti eti rẹ ti ge nigbati o ba bi ọmọ onka ọmọ kan pato, ati saahiba eyi tii se rakunmi nigbati o ba di ọmọ ọdun kan pato, ti wọn fi silẹ fun awọn oosa wọn, ati wasiilah eyi tiii se rakunmi ti o ti fẹ maa bi abo, ti abi rẹ ti fẹ maa bi abo, tahi haamii ohun ni rakunmi eyi ti ọpọ rakunmi miran ti jade ni ara rẹ, sugbọn awọn keferi lero wipe irọ ni, bẹẹ ni Ọlọhun Ọba Allah ko se awọn nkan ti a darukọ yii ni eewọ, ọpọ ninu awọn keferi ko si lee se adayanri laarin ootọ ati irọ, ati adayanri laarin ẹtọ ati eewọ.
Ipilẹ nibi awọn ofin Ọlọhun Ọba Allah ni wipe, o wa lati le fi iwulo ẹru ni aye ati ni ọrun rinlẹ, ati titi awọn inira kuro fun wọn.
Aitọ sise eemọ pẹlu pipọ nkan nitori wipe pipọ nkan ko jẹ ẹtọ lori titọọ rẹ ati didara rẹ bikose wipe ẹri sapamọ si inu idajọ ofin ẹsin.
Ninu ẹkọ ẹniti o nse isiti: ki o fi aala si ibeere niti aala ti o yanju, ko gbọdọ fi aaye gba ibeere ti ko si bukaata fun ọmọ ẹda eniyan nibẹ, tabi ti ko ni idi kankan fun tabi anfaani fun un.
Sise afihan aleebu oju ọna awọn ẹlẹbọ pẹlu dida adadaalẹ ati pipinnu sise awọn ẹran kan ni eewọ gẹgẹ bi: Bahiirọ, saahiba, wasiilah ati haamii.