فَلَمَّآ أَن جَآءَ ٱلۡبَشِيرُ أَلۡقَىٰهُ عَلَىٰ وَجۡهِهِۦ فَٱرۡتَدَّ بَصِيرٗاۖ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 96
Nigbati olufunni niro ohun ti o dun Ya'quub ninu de, o ju asọ Yuusuf si oju baba rẹ, o si di oluriran, nigbati yii ni o wa sọ fun awọn ọmọ rẹ: se emi ko sọ fun yin wipe mo mọ lati ibi aanu Ọlọhun ati daadaa rẹ ohun ti ẹyin ko mọ?
قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا ٱسۡتَغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَآ إِنَّا كُنَّا خَٰطِِٔينَ 97
Awọn ọmọ rẹ sọ ni ẹniti nwi awijare fun baba wọn Ya'quub ti ọla nbẹ fun nipa nkan ti wọn se fun Yuusuf ati ọmọ iya rẹ: irẹ baba wa, wa aforijin ni ọdọ Ọlọhun Allah fun ẹsẹ wa ti a sẹ siwaju dajudaju a jẹ ẹlẹsẹ alaida nibi nkan ti a se fun Yuusuf ati ọmọ iya rẹ.
قَالَ سَوۡفَ أَسۡتَغۡفِرُ لَكُمۡ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ 98
Baba wọbn sọ fun wọn wipe: maa pada wa aforijin fun yin ni ọdọ Ọlọhun Ọba mi, dajudaju O jẹ alaforijin fun ẹsẹ awọn oluronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, onikẹ pẹlu wọn.
فَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيۡهِ أَبَوَيۡهِ وَقَالَ ٱدۡخُلُواْ مِصۡرَ إِن شَآءَ ٱللَّهُ ءَامِنِينَ 99
Ya'quub ati awọn eniyan si jade ni ilu wọn ni ẹniti o gbero ọdọ Yuusuf ni ilu miisira, nigbati wọn wọle si ọdọ rẹ, o si fa baba rẹ ati mama rẹ mọra, o si sọ fun awọn ọmọ baba rẹ ati awọn ara ile wọn: ẹ wọ ilu misira pẹlu fifẹ Ọlọhun ni ẹni ifọkanbalẹ, suta kankan ko le kan yin nibẹ.
وَرَفَعَ أَبَوَيۡهِ عَلَى ٱلۡعَرۡشِ وَخَرُّواْ لَهُۥ سُجَّدٗاۖ وَقَالَ يَٰٓأَبَتِ هَٰذَا تَأۡوِيلُ رُءۡيَٰيَ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَعَلَهَا رَبِّي حَقّٗاۖ وَقَدۡ أَحۡسَنَ بِيٓ إِذۡ أَخۡرَجَنِي مِنَ ٱلسِّجۡنِ وَجَآءَ بِكُم مِّنَ ٱلۡبَدۡوِ مِنۢ بَعۡدِ أَن نَّزَغَ ٱلشَّيۡطَٰنُ بَيۡنِي وَبَيۡنَ إِخۡوَتِيٓۚ إِنَّ رَبِّي لَطِيفٞ لِّمَا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ 100
O mu awọn obi rẹ joko lori ibusun eyiti o joko le lori, awọn obi rẹ mejeeji ati awọn ọmọ baba rẹ mọkanla si ki i ni iforikanlẹ, iforikanlẹ yi jẹ ti ifunni niyi ti kii se ti ijọsin, ti o npe asẹ Ọlọhun Ọba lododo gẹgẹ bi o se ri ni inu ala, tori eleyi ni Yuusuf ẹniti ọla nbẹ fun fi sọ fun baba rẹ: ikini yii ni iforikanlẹ fun mi lati ọdọ yin ni itumọ ala mi eyiti mo ri siwaju, ti mo si sọ ọ fun ọ, paapaa Ọlọhun Ọba mi ti sọ di ododo sisẹlẹ, bẹẹ ni paapaa Ọlọhun Ọba mi se daadaa fun mi nigbati O mu mi jade kuro lẹwọn ati igbati o mu yin jade kuro ni oko lẹyin igbati esu ti ba aarin emi ati awọn ọmọ baba mi jẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba mi jẹ alaanu nibi eto idari Rẹ si oun ti o ba wu U, Ohun si ni onimimọ nipa isesi awọn ẹru Rẹ, Ọjọgbọn nibi idari eto Rẹ.
۞رَبِّ قَدۡ ءَاتَيۡتَنِي مِنَ ٱلۡمُلۡكِ وَعَلَّمۡتَنِي مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِۚ فَاطِرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ أَنتَ وَلِيِّۦ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ تَوَفَّنِي مُسۡلِمٗا وَأَلۡحِقۡنِي بِٱلصَّٰلِحِينَ 101
Lẹyin igba yii ni Yuusuf pe Ọlọhun Ọba rẹ, o si sọ wipe: irẹ Ọlọhun mi, paapaa o ti fun mi ni ọla ilu misirọ, O si fi imọ itumọ ala mọ mi, Iwọ ni adẹda gbogbo sanmọ ati ilẹ ati akọda mejeeji ni ojupọnna ti ko si apejuwe saaju, iwọ ni ko gbogbo ọrọ mi le lọwọ ni isẹmin aye, Iwọ naa si ni olowo gbogbo rẹ ni ọrun.
ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهِ إِلَيۡكَۖ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ أَجۡمَعُوٓاْ أَمۡرَهُمۡ وَهُمۡ يَمۡكُرُونَ 102
Eyiti a sọ ninu itan Yuusuf ati awọn ọmọ baba rẹ yii, a nsọ fun ọ - ire ojise - ko si imọ rẹ fun ọ siwaju toripe o ko si ni ọdọ awọn ọmọ baba Yuusuf nigbati wọn pinnu lati ju sinu ọgbun kanga, ti wọn pete pero ninu ete sugbọn a fi imisi ransẹ si ọ lori eyi.
وَمَآ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ وَلَوۡ حَرَصۡتَ بِمُؤۡمِنِينَ 103
Ọpọ ninu awọn eniyan ko le gbagbọ koda bi o na - ire ojise - gbogbo igbiyanju ki wọn le gbagbọ, mase mu ẹmin rẹ lofo nitori wọn.
Sise daadaa si awọn obi mejeeji ati gbititobi fun wọn ati sise apọnle wọn jẹ dandan, ninu rẹ naa ni gbigbawaju lati fun wọn niro idunnu nibi ohun ti yoo ba mu idunnu ba wọn.
Sise ikilọ kuro nibi roiroi esu ati ẹnikẹni ti o ba nlọ, ti o nbọ lati fi ibajẹ si aarin awọn ololufẹ; lati se onpinya laarin wọn.
Bi oti wulẹ ki ẹru dagba soke nibi ẹsin rẹ to tabi aye rẹ, dajudaju gbogbo eleyi yoo sẹri sibi sise ọla Ọlọhun Allah ti O ga ati sise idẹkun Rẹ le lori.
Bibi Ọlọhun Ọba leere igbẹyin daadaa ati ọla ati erenjẹ ni ọjọ igbende ati wiwa pẹlu awọn ẹniire ninu alujannah.
Ninu ola Ọlọhun Ọba Allah ti ola Re ga, ni bi O se ma nfi han awọn anabi re apakan awọn ounti o pamọ nitori awọn erongba kan ati awọn idi pataki.