يَعۡتَذِرُونَ إِلَيۡكُمۡ إِذَا رَجَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡۚ قُل لَّا تَعۡتَذِرُواْ لَن نُّؤۡمِنَ لَكُمۡ قَدۡ نَبَّأَنَا ٱللَّهُ مِنۡ أَخۡبَارِكُمۡۚ وَسَيَرَى ٱللَّهُ عَمَلَكُمۡ وَرَسُولُهُۥ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 94
Awọn sọbẹselu ti wọn ko jagun ti awon awijare yẹpẹre siwaju fun awọn musulumi nigbati wọn sẹri pada lati ibi oju-ogun, Ọlọhun Ọba Allah si ndoju ko anọbi Rẹ ati awọn olugbagbọ ododo pelu dida esi pada fun wọn: ẹ mase wi awijare irọ, awa ko le gba yin lododo nibi ohun ti ẹ fun wa niro rẹ, paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti fi diẹ ninu oun ti nbẹ ninu ọkan yin mọ wa, bẹẹ ni Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ yoo si maa woye: boya ẹyin yoo ronu piwada ki Allah le gba ironu piwada yin, tabi ẹyin yoo tẹsiwaju lori sọbẹselu yin? Lẹyin naa ti ẹ o wa sẹri lọ si ọdọ Allah ẹniti o mọ gbogbo nkan, yoo si fun yin niro nkan ti ẹ se, bẹẹ ni yoo si san yin lẹsan le lori, ki ẹ ya yara lọ si ibi ironu piwada ati isẹ rere.
سَيَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ لَكُمۡ إِذَا ٱنقَلَبۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡ لِتُعۡرِضُواْ عَنۡهُمۡۖ فَأَعۡرِضُواْ عَنۡهُمۡۖ إِنَّهُمۡ رِجۡسٞۖ وَمَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 95
Awọn oluyapa yii yoo maa fi Allah bura nigbati ẹ ba sẹri tan - ẹyin olugbagbọ ododo - ni ikanpamọ awijare wọn ti ibajẹ; ki ẹ le ba jawọ kuro nibi eebu wọn ati ipẹgan wọn, ẹ ya fi wọn silẹ ni ifisilẹ ibinusini, ki ẹ dagunla si wọn, wọn jẹ iran aida, olubalẹjẹ, ibiti wọn yoo si sinmi si ina jahanamọ; ni ẹsan lori nkan ti wọn nse lori sọbẹ selu ati ẹsẹ.
يَحۡلِفُونَ لَكُمۡ لِتَرۡضَوۡاْ عَنۡهُمۡۖ فَإِن تَرۡضَوۡاْ عَنۡهُمۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يَرۡضَىٰ عَنِ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡفَٰسِقِينَ 96
Awọn oluyapa yii yoo maa bura fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - ki ẹ le ba yonu si wọn, ati ki ẹ le gba awọn awijare wọle, ẹ mase yọnu si wọn, ti ẹ ba yọnu si wọn, ẹ ti yapa Ọlọhun Ọba yin, nitori wipe dajadaju Oun ko nii yọnu si ijọ ti o jade kuro nibi itẹle asẹ Rẹ niti sise keferi ati sọbẹ selu; ki ẹ yaa sọra -ẹyin olugbafa- ki ẹ maa ba yọnu si ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ko yọnu si.
ٱلۡأَعۡرَابُ أَشَدُّ كُفۡرٗا وَنِفَاقٗا وَأَجۡدَرُ أَلَّا يَعۡلَمُواْ حُدُودَ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 97
Awọn ara oko ti wọn ba se keferi tabi sọbẹ selu, keferi wọn yoo le ju keferi ẹlomiran ti o yatọ si wọn lọ ninu awọn ara ile, bẹẹ ni sọbẹ selu wọn yoo lagbara ju ti awọn eniyan naa lọ, awọn ni wọn lẹtọ si aimọkan ẹsin, awọn ni wọn si tọ lati mọ mọ awọn nkan ọranyan ati ikọse anọbi, ati awọn onde idajọ eyiti Ọlọhun Ọba sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ; nitori ifọnu ati ilekoko ti wọn wa lori rẹ, ati airopọ mọ awọn eniyan, bẹẹ ni Ọlọhun Ọba Allah nimọ nipa gbogbo isesi wọn, nkankan ko pamọ fun ninu rẹ, ọjọgbọn nibi idari ati ofin Rẹ.
وَمِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ مَن يَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ مَغۡرَمٗا وَيَتَرَبَّصُ بِكُمُ ٱلدَّوَآئِرَۚ عَلَيۡهِمۡ دَآئِرَةُ ٱلسَّوۡءِۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٞ 98
O wa ninu awọn ti wọn ngbe oko ti wọn si jẹ sọbẹselu, ẹniti o di adisọkan wipe oun ti o nna ninu dukia si oju ọna Allah jẹ ofo ati gbese nitori roiroi ti nbẹ fun wipe oun ko nii gba ẹsan ohun ti ba na an, bẹẹ ni Allah ko nii fi iya jẹ ohun ti ohun ba dii mọ ọwọ, sugbon pẹlu eleyi naa, o ma nna ni awọn asiko miran niti sekarimi ati idaabobo, o wa nreti ki o sọkalẹ fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - aburu ki o le ja wọ ninu ọrọ yin, bikose wipe Ọlọhun Ọba Allah sọ oun ti wọn ngbero wipe ki o sẹlẹ si awọn olugbagbọ ododo laburu ni tabi iyipada igba ni oun ti ẹyin rẹ ko lee dara, di oun ti yoo sẹlẹ le wọn lori, ti ko si nii jẹ ti awọn olugbagbọ ododo, Ọlọhun Ọba Allah jẹ olugbọ ohun ti wọn nsọ, ati onimimọ si oun ti wọn ndi si ọkan.
وَمِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ مَن يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ قُرُبَٰتٍ عِندَ ٱللَّهِ وَصَلَوَٰتِ ٱلرَّسُولِۚ أَلَآ إِنَّهَا قُرۡبَةٞ لَّهُمۡۚ سَيُدۡخِلُهُمُ ٱللَّهُ فِي رَحۡمَتِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 99
Ẹniti o nigbagbọ ninu Allah ati ọjọ ikẹyin wa ninu awọn ara oko, ti yoo si sọ ohun ti o na si oju ọna Allah di isunman si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ati ojupọnna lati ri ere latara adua ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati iwa aforijin Ọlọhun Ọba fun, tẹti dajudaju inawo rẹ si oju ọna Allah, o jẹ isunman si ọdọ Allah, yoo ri ẹsan rẹ ni ọdọ Rẹ pẹlu ki o ki bọnu ikẹ rẹ ti o gbaaye, eyiti o ko aforijin ati alujannah Rẹ sinu, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluforijinni fun ẹniti o ba ronu piwada ninu ẹru Rẹ, olukẹ si wọn.
Ori papa isẹ ati ilabọrun jẹ ẹri ti o loore ju lori afihan irọ sọbẹ selu si ootọ wọn.
Awọn ara oko ti wọn ba se keferi, keferi wọn ma nnipọn ati sọbẹ selu wọn ju ara ile lọ; nitori ayika ti yoo lapa.
Iseni loju kokoro lori mima na ohun ti a ni si oju ọna Allah pẹlu sise afọmọ adisọkan ati titobi ẹsan ẹniti o ba se eleyi.
Ọla imọ ati wipe ẹniti o ba padanu rẹ sun mọ asise.