قُلۡ إِن كَانَتۡ لَكُمُ ٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ ٱللَّهِ خَالِصَةٗ مِّن دُونِ ٱلنَّاسِ فَتَمَنَّوُاْ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 94
Sọpe - irẹ Anọbi - ti o ba jẹ wipe nbẹ fun yin ni, - ẹyin Yahuudi - ọgba idẹra ni ile ikẹyin, ni ẹyin nikan, ti ẹlomiran ti o yatọ si yin ko nii wọ, ẹ maa rankan lati ku, ki ẹ si maa waa; ki ọwọ yin le ba tẹ ipo yii ni kiakia, ti ẹ o si waa si min ninu awọn wahala isẹmi aye ati ibanujẹ ibẹ, ti o ba jẹ wipe ẹ jẹ ẹniti nsọ ododo pẹlu ohun ti ẹ npe mọ ara yin yii.
وَلَن يَتَمَنَّوۡهُ أَبَدَۢا بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّٰلِمِينَ 95
Wọn ko lee rankan iku lailai; nitori ohun ti wọn ti ti siwaju ninu isẹmi wọn nibi sise aimoore pẹlu Ọlọhun Ọba ati pipe awọn ojisẹ Rẹ ni irọ, ati yiyi awọn tira Rẹ pada, Ọlọhun Ọba ni O mọ awọn alabosi ninu wọn ati ninu awọn miran, Yoo si san onikaluku ni ẹsan pẹlu isẹ rẹ.
وَلَتَجِدَنَّهُمۡ أَحۡرَصَ ٱلنَّاسِ عَلَىٰ حَيَوٰةٖ وَمِنَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْۚ يَوَدُّ أَحَدُهُمۡ لَوۡ يُعَمَّرُ أَلۡفَ سَنَةٖ وَمَا هُوَ بِمُزَحۡزِحِهِۦ مِنَ ٱلۡعَذَابِ أَن يُعَمَّرَۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ 96
Iwọ yoo maa ri - Irẹ Anọbi - awọn Yahuudi ni eniyan ti o ni oju kokoro ti o lagbara lori isẹmi bi o ti wulẹ ki o jẹ wipe o jẹ ohun ti o yẹpẹrẹ, ti ko si ni asunsi, bikose wipe wọn tun ni oju kokoro ju awọn ọsẹbọ lọ, awọn ti wọn ko ni igbagbọ pẹlu igbende ati isesiro isẹ, pẹlu wipe wọn jẹ ẹni ti A fun ni tira ti wọn ni igbagbọ pẹlu igbende ati isesiro isẹ; dajudaju ọkan ninu wọn, yoo maa fẹ ki ọjọ ori rẹ ko de ẹgbẹrun ọdun, ko si le gbe jina si iya Ọlọhun Ọba, gigun ẹmi rẹ bi o ti wulẹ ki o gun to, Ọlọhun Ọba nwo gbogbo isẹ wọn, O si riran rii pẹlu, nkankan ninu rẹ ko pamọ fun Un, Yoo si san wọn lẹsan pẹlu rẹ.
قُلۡ مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّـجِبۡرِيلَ فَإِنَّهُۥ نَزَّلَهُۥ عَلَىٰ قَلۡبِكَ بِإِذۡنِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ 97
Sọ - irẹ Anọbi - fun ẹni ti o ba sọ ninu awọn Yahuudi wipe: “dajudaju Jibreel, ọta wa ni ninu awọ malaika”: ẹni ti o ba nba ba Jibreel se ọta, dajudaju oun ni ẹniti o sọ Alukuraani si ọkan rẹ pẹlu iyọnda lati ọdọ Ọlọhun Ọba, to nsọ jijẹ ododo awọn ti wọn siwaju rẹ ninu awọn tira tii se ti Ọlọhun Ọba; gẹgẹ bi Taoreeta ati Injiila, ti o si tun ntọka si oore, ti o si tun nfun awọn Muumini ni iro idunnu pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba pese fun wọn ninu idẹra, ẹniti o ba nba ẹni ti iroyin rẹ ati isẹ rẹ se ọta, o jẹ wipe iru ẹni bẹẹ wa ninu anu.
مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّلَّهِ وَمَلَٰٓئِكَتِهِۦ وَرُسُلِهِۦ وَجِبۡرِيلَ وَمِيكَىٰلَ فَإِنَّ ٱللَّهَ عَدُوّٞ لِّلۡكَٰفِرِينَ 98
Ẹniti o ba nba Ọlọhun Ọba, awọn Malaika Rẹ ati awọn ojisẹ Rẹ se ọta, ti o si tun nba Malaika alasunmọ mejeeji: Jibreel ati Mikaail se ọta; dajudaju Ọlọhun Ọba jẹ ọta awọn alaigbagbọ ninu yin ati awọn ti wọn yatọ si yin, ẹniti Ọlọhun Ọba ba jẹ ọta fun, paapa iru ẹni bẹẹ ti sẹri pẹlu ofo ti o fi oju han.
وَلَقَدۡ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ءَايَٰتِۢ بَيِّنَٰتٖۖ وَمَا يَكۡفُرُ بِهَآ إِلَّا ٱلۡفَٰسِقُونَ 99
Paapa, A ti sọkalẹ fun ọ, - irẹ Anọbi - awọn arisami ti o fi oju han lori isododo rẹ ninu nkan ti o mu wa, ninu jijẹ Anọbi ati fifi isẹ ran ni, ko si nii se aigbagbọ pẹlu rẹ pẹlu bi o se han yii, ti o si ye yekeyeke ayaafi awọn ti wọn ti jade kuro ninu ẹsin Ọlọhun Ọba.
أَوَ كُلَّمَا عَٰهَدُواْ عَهۡدٗا نَّبَذَهُۥ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ 100
Ninu aburu isesi awọn Yahuudi ni wipe gbogbo igbati wọn ba gba adehun kan lori wọn - ninu apapọ rẹ naa ni nini igbagbọ pẹlu ohun ti Taoreeta ntọkasi ninu jijẹ ti Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) , apakan ninu wọn yoo tu adehun naa ka, bikose wipe ọpọlọpọ awọn Yahuudi yii, wọn ko ni igbagbọ pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ ni paapaa; toripe nini igbagbọ, yoo gbe eniyan lọ si ibi mima pe adehun.
وَلَمَّا جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٞ لِّمَا مَعَهُمۡ نَبَذَ فَرِيقٞ مِّنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ كِتَٰبَ ٱللَّهِ وَرَآءَ ظُهُورِهِمۡ كَأَنَّهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 101
Nigbati Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) wa ba wọn, ni ojisẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba, ti o si se deede ohun ti nbẹ ninu Taoreeta ninu iroyin rẹ, awọn apakan ninu wọn gunri kuro nibi ohun ti ntọka si, wọn si juu si ẹyin wọn lai bikita pẹlu rẹ, ni ẹni ti o jọ isesi alaimọkan ẹniti o jẹ wipe ko nii se anfaani pẹlu ohun ti nbẹ nibẹ ninu ododo ati imọna, ti ko si nii bikita pẹlu rẹ.
Olugbagbọ lododo yoo maa rankan ohun ti nbẹ lọdọ Ọlọhun Ọba ninu idẹra eyiti yoo ma lọ gbere, nitori idi eleyi yoo ma dunnu lati pade Ọlọhun Ọba, ko si nii bẹru iku.
Nini oju kokoro awọn Yahuudi lori isẹmi aye titi ti o jẹ wipe ko baa jẹ isẹmi ti o yẹpẹrẹ, ti ko ni asunsi, ti kii sii se alapọnle.
Dajudaju ẹniti ba nba awọn ọrẹ Ọlọhun Ọba ti o jẹ alasunmọ se ọta, paapaa iru ẹni bẹẹ ti nba Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) se ọta.
Gigunri ti awọn Yahuudi gunri kuro nibi ijẹ anabi ti Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) lẹyin igbati wọn ti mọ jijẹ ododo rẹ nitori oun ti nbẹ ni ọwọ wọn ninu Taoraat.
Dajudaju ẹniti ko ba se anfaani pẹlu imọ ti o ni, o daa ki a se iroyin rẹ pẹlu aimọkan; toripe o jọ alaimọkan ninu aimọkan rẹ.