وَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنٍ أَن يَقۡتُلَ مُؤۡمِنًا إِلَّا خَطَٔٗاۚ وَمَن قَتَلَ مُؤۡمِنًا خَطَٔٗا فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖ وَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَصَّدَّقُواْۚ فَإِن كَانَ مِن قَوۡمٍ عَدُوّٖ لَّكُمۡ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ وَإِن كَانَ مِن قَوۡمِۢ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞ فَدِيَةٞ مُّسَلَّمَةٌ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ وَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مُّؤۡمِنَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ شَهۡرَيۡنِ مُتَتَابِعَيۡنِ تَوۡبَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا 92
Ko tọ fun olugbagbọ ododo kan ki o pa olugbagbọ ododo miran ayaafi ti o ba sẹlẹ lati ọdọ rẹ niti asise, ẹniti o pa olugbagbọ ododo kan ni ojupọnna asise, o di dandan ki o bọ okun lọrun ẹru ti a nikapa kan, ni iparẹ si isẹ rẹ, o di dandan fun olusunmọ ẹniti o pa eniyan, awọn ti yoo jẹ ogun rẹ ki o san owo itanran fun awọn ti yoo jẹ ogun ẹniti o pa, ayaafi ti wọn ba se amojukuro nipa owo itanran, igba naa ni ko jẹ dandan, ti ẹniti a pa ba jẹ ninu ijọ ti o ba yin ja ogun, ti o si jẹ olugbagbọ, o di dandan fun ẹniti o pa eniyan ki o bọ okun lọrun ẹru ti a nikapa, ko si itanran fun un, nigbati ẹniti a pa ko ba jẹ olugbagbọ ododo, sugbọn o jẹ ninu ijọ ti adehun wa laarin ẹyin ati wọn gẹgẹ bi awọn oniwọlọrun “Ahalu Dhimmah”, o di dandan fun alasunmọ ẹniti o pa eniyan, awọn ti wọn yoo jẹ ogun rẹ, ki wọn o san owo itanran fun awọn ẹniti a pa, o di dandan fun ẹniti o pa eniyan, ibọkun lọrun ẹrubinrin ti a nikapa, iparẹ fun isẹ rẹ, ti ko ba ri ẹniti yoo bọ okun lọrun rẹ, tabi ko ni agbara lati san owo rẹ, dandan ni ki o gba aawẹ osu meji ti yoo tẹle ara wọn, ti ko nii ja, ti ko si nii siẹnu ninu rẹ, ki Ọlọhun Ọba Allah le gba aforijin rẹ nibi nkan ti o se, Ọlọhun Ọba Allah jẹ onimimọ si isẹ ti awọn ẹru Rẹ nse ati adisọkan wọn, Ọjọgbọn nibi awọn ofin Rẹ ati idari Rẹ.
وَمَن يَقۡتُلۡ مُؤۡمِنٗا مُّتَعَمِّدٗا فَجَزَآؤُهُۥ جَهَنَّمُ خَٰلِدٗا فِيهَا وَغَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ وَلَعَنَهُۥ وَأَعَدَّ لَهُۥ عَذَابًا عَظِيمٗا 93
Ẹniti o ba pa olugbagbọ ododo kan ni ojupọnna igbero ni ọna ti ko tọ; ẹsan rẹ ni ki o wọ ina Jahannamọ ni gbere si inu rẹ, ti o ba sodi eto tabi ko ronu piwada, Ọlọhun Ọba Allah yoo binu si, yoo si le jinna kuro nibi ikẹ Rẹ, yoo si pese iya ti o tobi fun nitori ẹsẹ ti o tobi ti o da yii.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا ضَرَبۡتُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَتَبَيَّنُواْ وَلَا تَقُولُواْ لِمَنۡ أَلۡقَىٰٓ إِلَيۡكُمُ ٱلسَّلَٰمَ لَسۡتَ مُؤۡمِنٗا تَبۡتَغُونَ عَرَضَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا فَعِندَ ٱللَّهِ مَغَانِمُ كَثِيرَةٞۚ كَذَٰلِكَ كُنتُم مِّن قَبۡلُ فَمَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ فَتَبَيَّنُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا 94
A pe ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ, ti ẹ ba jade fun igbiyanju si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah, ki ẹ duro sinsin nibi asẹ ẹniti ẹ nba ja ogun, ẹ ko gbọdọ sọ fun ẹniti o se afihan si yin ohun ti o tọka si Islam rẹ: o kii se olugbagbọ ododo, ipaya lori ẹjẹ rẹ ati dukia rẹ ohun ni o gbe ọ lọ si ibi sise afihan Islam, ki ẹ waa lọ pa ni ẹniti nfi pipa rẹ wa ọrọ ile aye eyiti a gbọdọ ri sa gẹgẹ bi ikọrọ lati ọdọ rẹ, bikose wipe ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni ọrọ ti o pọ wa, ohun si ni o loore, ti o si tobi ju eleyi lọ, gẹgẹ bẹẹ naa ni ẹyin naa se wa siwaju gẹgẹ bi ẹniti o nse afipamọ igbagbọ rẹ fun awọn ijọ rẹ, Ọlọhun Ọba Allah waa se idẹkun le yin lori pẹlu Islam, O daabobo ẹjẹ yin, ki ẹ ya duro sinsin, nkankan ko pamọ fun Ọlọhun Ọba Allah niinu isẹ yin koda ki o wẹ, Yoo si san yin lẹsan pẹlu rẹ.
Alukuraani Alapọnle wa lati gbe titobi fun iwọ ti o wa fun ẹmin olugbagbọ ododo, o si nkọ fun pipaa run, o si fi awọn ijiya ti o pọ tẹlee.
Ninu adisọkan awọn Ahalusunna waljamaa’ah ni wipe ko nii ra si inu ina, olugbagbọ ododo ti o pa eniyan, bikose wipe wọn yoo fi iya jẹẹ nibẹ fun igba pipẹ, lẹyin naa ni yoo jade nibẹ pẹlu ikẹ Ọlọhun Ọba Allah ti o ga.
Jijẹ dandan iduro sinsin ati mimọ amodaju nibi ijagun ati aiikanju nibi idajọ lori awọn eniyan, ti wọn ko fi nii maa kọ kọja ẹnu aala si alailẹsẹ.