وَمَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦٓ إِذۡ قَالُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَىٰ بَشَرٖ مِّن شَيۡءٖۗ قُلۡ مَنۡ أَنزَلَ ٱلۡكِتَٰبَ ٱلَّذِي جَآءَ بِهِۦ مُوسَىٰ نُورٗا وَهُدٗى لِّلنَّاسِۖ تَجۡعَلُونَهُۥ قَرَاطِيسَ تُبۡدُونَهَا وَتُخۡفُونَ كَثِيرٗاۖ وَعُلِّمۡتُم مَّا لَمۡ تَعۡلَمُوٓاْ أَنتُمۡ وَلَآ ءَابَآؤُكُمۡۖ قُلِ ٱللَّهُۖ ثُمَّ ذَرۡهُمۡ فِي خَوۡضِهِمۡ يَلۡعَبُونَ 91
Awọn ọlusẹbọ ko pataki Ọlọhun Ọba Allah ni bi O se tọ nigbati wọn sọ fun Anọbi Rẹ Muhammad (ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun) : Ọlọhun Ọba Allah ko sọ imisi kankan kalẹ fun abara kankan, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ - taani o sọ taoreeta kalẹ fun Musa niti imọlẹ, imọna ati itọsọna fun awọn ijọ rẹ? Awọn Yahuudi fi sinu iwe, wọn si se afihan eyi ti o ba ifẹ inu wọn mu ninu rẹ, wọn si nfi pamọ eyiti o yapa sii, bi iroyin Muhammad (ti ikẹ ati ọla nbẹ fun) , wọn si fi mọ yin - ẹyin larubawa - nkan ti ẹ ko mọ ninu Alukuraani ati eyiti awọn ẹni isaaju yin ko mọ, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ - Ọlọhun Ọba Allah ni O sọọ kalẹ, fi wọn silẹ sinu aimọkan wọn ati anu wọn titi ti amọdaju yoo fi waa ba wọn.
وَهَٰذَا كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ مُبَارَكٞ مُّصَدِّقُ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَلِتُنذِرَ أُمَّ ٱلۡقُرَىٰ وَمَنۡ حَوۡلَهَاۚ وَٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۖ وَهُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ 92
Alukuraani yii jẹ iwe ta sọkalẹ fun ọ - irẹ Anọbi - o si jẹ iwe onibukun, ti o si npe awọn iwe sanmọ ti o ti kọja siwaju rẹ lootọ, ki o le maa fi se ikilọ fun awọn ara Mekkah, ati gbogbo awọn eniyan ti nbẹ ni ori ilẹ lati ibuyọ titi de ibuwọ, ki wọn o le mọ ọna, awọn ti wọn nigbagbọ si isẹmi ọrun, ti wọn si tun ni igbagbọ si Alukuraani yii, ti won si mo oun ti o wa ninu rẹ, ti wọn nmoju to irun wọn pẹlu sise awọn origun rẹ ati awọn ọranyan rẹ, ati awọn ikọse awọn Anọbi ni asiko rẹ ti a se lẹsa fun un gẹgẹ bi ofin.
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ قَالَ أُوحِيَ إِلَيَّ وَلَمۡ يُوحَ إِلَيۡهِ شَيۡءٞ وَمَن قَالَ سَأُنزِلُ مِثۡلَ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُۗ وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلظَّٰلِمُونَ فِي غَمَرَٰتِ ٱلۡمَوۡتِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ بَاسِطُوٓاْ أَيۡدِيهِمۡ أَخۡرِجُوٓاْ أَنفُسَكُمُۖ ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ عَذَابَ ٱلۡهُونِ بِمَا كُنتُمۡ تَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ غَيۡرَ ٱلۡحَقِّ وَكُنتُمۡ عَنۡ ءَايَٰتِهِۦ تَسۡتَكۡبِرُونَ 93
Ko si ẹniti abosi rẹ gboopọn to ẹniti o da adapa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu wipe o sọ wipe: Ọlọhun Ọba Allah ko sọ nkankan kalẹ fun abara kankan, tabi ki o sọọ niti irọ wipe: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ransẹ si oun, ti Ọlọhun Ọba Allah ko si ransẹ sii, tabi ki o sọ wipe: wọn yoo sọ iru ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ ninu Alukuraani kalẹ, ti o ba ri - ire ojise - nigbati ihunrira iku ba nsẹlẹ si awọn alabosi wọnyi, ti awọn Malaika si bẹrẹ si ni fi iya ọwọ wọn jẹ wọn pẹlu lilu, wọn yoo maa sọ ni ojupọnnna ifulẹ mọ wọn, ẹ mu ara yin jade, awa ni a gbaa, oni ẹ yoo maa jẹ iya ti yoo yẹpẹrẹ yin nitori nkan ti ẹ nsọ mọ Ọlọhun Ọba Allah ninu irọ ati pipe apemọra jijẹ Anọbi ati imisi ati sisọ iro ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ, ati nitori igberaga yin kuro nibi igbagbọ si awọn amin Rẹ, ti o ba ri eleyi, iwọ yoo ri alamọri ti o buru juu lọ.
وَلَقَدۡ جِئۡتُمُونَا فُرَٰدَىٰ كَمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَتَرَكۡتُم مَّا خَوَّلۡنَٰكُمۡ وَرَآءَ ظُهُورِكُمۡۖ وَمَا نَرَىٰ مَعَكُمۡ شُفَعَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُمۡ أَنَّهُمۡ فِيكُمۡ شُرَكَٰٓؤُاْۚ لَقَد تَّقَطَّعَ بَيۡنَكُمۡ وَضَلَّ عَنكُم مَّا كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ 94
Wọn yoo maa sọ fun ni ọjọ igbende: paapaa ẹ ti waa ba wa ni oni ni ẹyọ-ẹyọ tabi ni aaso-aaso, ko si dukia pẹlu yin bẹẹni ko si idari gẹgẹ bi a se da yin ni akọkọ laini bata ni ihoho pẹlu adọdọ, ẹ si gbe ohun ti a fun yin ju silẹ nibi si se yin ni arole ni ile aye laise lati ọdọ yin, a ko ri awọn ọlọhun ọba yin pẹlu yin ni oni, awọn ti ẹ pinu wipe wọn yoo jẹ alatẹgun yin, ẹ si nlero wipe awọn ni orogun Ọlọhun Ọba Allah, ti awọn naa ni ẹtọ si ijọsin, okun ti o so yin pọ ti ja bayi, isipẹ ti ẹ nlero wipe yoo ti ọdọ wọn wa ti kuro fun yin, bẹẹ ni ijẹ orogun Ọlọhun Ọba Allah naa ti kuro.
Sisọ iwe kalẹ fun awọn Anọbi Ọlọhun, o jẹ isesi Ọlọhun Ọba Allah fun awọn ojisẹ Rẹ, Anọbi ki ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ ọkan ninu wọn.
Eniyan ti irọ rẹ tobi ju ati adapa irọ rẹ ni ẹniti o ba pa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ti o wa nse afiti, tabi mu kuro, tabi fi rinlẹ fun Ọlọhun, alamọri kan ti ko si ẹri ti o ni alaafia fun un.
Gbogbo ẹni kọọkan ni wọn yoo gbedide ni ọjọ igbende ni yoro-yoro, yoo bọpa-bọsẹ kuro nibi awọn ipo ati awọn alajẹ ni olosi, yoo si da se isiro isẹ ni oun nikan.