وَٱلَّتِيٓ أَحۡصَنَتۡ فَرۡجَهَا فَنَفَخۡنَا فِيهَا مِن رُّوحِنَا وَجَعَلۡنَٰهَا وَٱبۡنَهَآ ءَايَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ 91
Tun ranti - irẹ ojisẹ - itan Maryam ẹniti ọla nbẹ fun eyiti o sọ abẹ rẹ kuro nibi agbere, Ọlọhun Allah si ran Malaika Jibril si ẹniti ọla nbẹ fun, o si fẹ atẹgun si, bayi ni o loyun Isa ẹniti ọla nbẹ fun, oun ati ọmọ rẹ si jẹ amin fun awọn eniyan lori agbara Ọlọhun Allah, ati wipe dajudaju nkankan ko le ko agbara ba A nitoripe o da a laini baba.
إِنَّ هَٰذِهِۦٓ أُمَّتُكُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَأَنَا۠ رَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُونِ 92
Eleyi ni oju ọna yin - ẹyin eniyan - oju ọna kan soso, ohun ni imu Ọlọhun Ọba lọkan soso eyiti tii se ẹsin Islam, bẹẹni Emi ni Ọlọhun yin, ki ẹ se afọmọ ijọsin fun Mi le Mi nikan soso.
وَتَقَطَّعُوٓاْ أَمۡرَهُم بَيۡنَهُمۡۖ كُلٌّ إِلَيۡنَا رَٰجِعُونَ 93
Awọn eniyan pin yẹlẹyẹlẹ, olumu Ọlọhun Ọba lọkan, ẹlẹbọ ati keferi ati olugbagbọ ododo wa ninu wọn, gbogbo awọn ti wọn npin yẹlẹyẹlẹ yii ọdọ Wa nikan ni gbogbo wọn yoo sẹri si ni ọjọ igbende, a o si san wọn lẹsan lori isẹ wọn.
فَمَن يَعۡمَلۡ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَا كُفۡرَانَ لِسَعۡيِهِۦ وَإِنَّا لَهُۥ كَٰتِبُونَ 94
Ẹniti o ba sisẹ re ninu wọn, ti o nigbagbọ ninu Allah ati awọn ojisẹ Rẹ ati ọjọ ikẹyin, ko si iyan fun isẹ rere rẹ bikosepe Allah yoo dupẹ fun un, yoo si san lẹsan adipele, yoo si ri ninu iwe isẹẹ rẹ ni ọjọ igbende, ti inu rẹ yoo si dun si.
وَحَرَٰمٌ عَلَىٰ قَرۡيَةٍ أَهۡلَكۡنَٰهَآ أَنَّهُمۡ لَا يَرۡجِعُونَ 95
O soro fun awọn ara abule ti a pa run nitori kefei wọn, ki wọn o sẹri pada si aye; lati ronu piwada ki wọn si gba ironu piwada wọn.
حَتَّىٰٓ إِذَا فُتِحَتۡ يَأۡجُوجُ وَمَأۡجُوجُ وَهُم مِّن كُلِّ حَدَبٖ يَنسِلُونَ 96
Wọn ko le sẹri lailai titi ti wọn yoo fi si gaga yajuuja ati maajuuja, ni ọjọ naa gegele oriilẹ ni wọn yoo ti maa jade niti ikanju.
وَٱقۡتَرَبَ ٱلۡوَعۡدُ ٱلۡحَقُّ فَإِذَا هِيَ شَٰخِصَةٌ أَبۡصَٰرُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يَٰوَيۡلَنَا قَدۡ كُنَّا فِي غَفۡلَةٖ مِّنۡ هَٰذَا بَلۡ كُنَّا ظَٰلِمِينَ 97
Ọjọ igbende sun mọ ti wọn yoo jade, ipaya rẹ si ti han ati ilekoko rẹ, ni ojiji ni oju awọn keferi yoo la silẹ nibi lilekoko ipaya rẹ, wọn yoo si maa sọpe: iparun wa o, paapa a ti nwa ninu ere gele ati ikoroju lati mura silẹ fun ọjọj ti o tobi naa ni ile aye, bẹẹ ni a jẹ alabosi nibi sise keferi ati gigunle awọn ẹsẹ.
إِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ حَصَبُ جَهَنَّمَ أَنتُمۡ لَهَا وَٰرِدُونَ 98
Dajudaju ẹyin - ẹyin ẹlẹbọ - ati ohun ti a njọsin fun yatọ si Allah ninu awọn oosa ati awọn ti o yọnu si ijọsin yin bi eniyan tabi alujannu fun wọn ni yoo jẹ ikona jahanamọ, ẹyin ati ẹniti ẹ njọsin fun ni yoo si wọ inu rẹ.
لَوۡ كَانَ هَٰٓؤُلَآءِ ءَالِهَةٗ مَّا وَرَدُوهَاۖ وَكُلّٞ فِيهَا خَٰلِدُونَ 99
Ti o ba jẹsi wipe awọn ti ẹ njọsin fun jẹ ọlọhun ti o tọ lati jọsin fun ni wọn ko ba ti wọ ina pẹlu ẹniti o nsin wọn, ati awọn olujọsin ati ẹniti wọn njọsin fun yoo wa ninu ina, wọn yoo si maa gbe ibẹ gbere ti wọn ko nii jade nibẹ.
لَهُمۡ فِيهَا زَفِيرٞ وَهُمۡ فِيهَا لَا يَسۡمَعُونَ 100
Mimi ifupinpin yoo ma bẹ fun wọn nibẹ - nitori lile koko ohun ti wọn ba pade ninu inira - ninu ina wọn ko ni gbọ ohun nitori lile koko ipaya ati ijaya ti yoo kan wọn nibẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ سَبَقَتۡ لَهُم مِّنَّا ٱلۡحُسۡنَىٰٓ أُوْلَٰٓئِكَ عَنۡهَا مُبۡعَدُونَ 101
Nigbati awọn ẹlẹbọ sọpe: (dajudaju Isa ati awọn Mailaka ti wọn nsin yoo wọn ina), Ọlọhun Allah sọpe: awọn ẹniti imọ Allah ti gbawaju nipa wọn ni wọn jẹ ninu oloriire gẹgẹ bi Isa ẹniti ọla nbẹ fun, wọn si ta kete si ina.
Itọnisi amumọra ati sise alaye ọla ti nbẹ fun.
Pipapọ awọn iwe iransẹ sanmọ nibi ijọkan soso ati ipilẹ awọn ijọsin.
Sisi gaga yajuuja ati majuuja wa ninu awọn amin ọjọ igbende ni nla.
Fifọnu nipa imusilẹ fun ọjọ igbende jẹ okunfa lati fi ara kin ipaya bẹ.