بَلۡ أَتَيۡنَٰهُم بِٱلۡحَقِّ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ 90
Ọrọ ko ri bi wọn ti npe e, bikosepe A mu ododo wa ba wọn ti ko si iyemeji nibẹ, dajudaju wọn jẹ olupurọ pẹlu ohun ti wọn npe apemọra rẹ fun Allah gẹgẹ bi akẹgbẹ ati ọmọ, giga Allah kuro nibi ọrọ wọn ni giga ti o tobi.
مَا ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ مِن وَلَدٖ وَمَا كَانَ مَعَهُۥ مِنۡ إِلَٰهٍۚ إِذٗا لَّذَهَبَ كُلُّ إِلَٰهِۢ بِمَا خَلَقَ وَلَعَلَا بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ 91
Allah ko ni ọmọ gẹgẹ bi awọn keferi se nro, ko si ẹni ijọsin fun tootọ pẹlu Rẹ, ti o ba ti lẹ jasi wipe ẹni ijọsin fun tootọ wa pẹlu rẹ, gbogbo ẹni ijọsin fun yii ko ba mu ipin rẹ ninu ẹda ti o da, bẹẹni apakan wọn ko ba bori apakan, wọn ko ba si ba eto aye jẹ, ohun ti o sẹlẹ ni pe ikankan ninu eleyi ko sẹlẹ, ti o wa tọka si wipe olujọsin fun tootọ jẹ ọkan soso, Oun si ni Allah ọkan soso, mimọ Rẹ ati fifọ Ọ mọ kuro nibi iroyin ti awọn ẹlẹbọ nfi nroyin Rẹ ninu ohun ti ko tọ ọ si I gẹgẹ bi ọmọ ati akẹgbẹ.
عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 92
Onimimọ nipa ounti o pamọ fun awọn ẹda Rẹ, onimimọ si ni nipa ohun ti a le fi oju ri ati ohun ti a le fi ọwọ kan, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi, giga Rẹ ati mimọ Rẹ kọja ki O ni akẹgbẹ.
قُل رَّبِّ إِمَّا تُرِيَنِّي مَا يُوعَدُونَ 93
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: iwọ Ọlọhun mi ninu ki o fi han mi ni ara awọn ẹlẹbọ yii ohun ti O se ni adehun fun wọn ninu iya.
رَبِّ فَلَا تَجۡعَلۡنِي فِي ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ 94
Ọlọhun mi, ti O ba fi iya jẹ wọn, ti mo si nri eleyi, mase fi mi si inu wọn, ki iya ti o sẹlẹ si wọn maba sẹlẹ si mi.
وَإِنَّا عَلَىٰٓ أَن نُّرِيَكَ مَا نَعِدُهُمۡ لَقَٰدِرُونَ 95
Bẹẹ ni dajudaju Awa jẹ Ẹniti O lagbara lati jẹki o jẹri si, ki o si ri ohun ti a fi jẹ wọn niya, a ko kagara nibi eleyi tabi nkan miran.
ٱدۡفَعۡ بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ ٱلسَّيِّئَةَۚ نَحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَصِفُونَ 96
Na - irẹ ojisẹ - iwa ti o dara fun ẹniti o se aburu si ọ; pẹlu ki o se amojukuro fun un, ki o si se suuru lori suta rẹ, Awa ni a nimọ ju nipa iroyin ẹbọ ati irọ pipa ti wọn nse ati iroyin idan ati iroyin ti wọn fi nroyin rẹ ninu ohun ti ko tọ si ọ.
وَقُل رَّبِّ أَعُوذُ بِكَ مِنۡ هَمَزَٰتِ ٱلشَّيَٰطِينِ 97
Ki o si sọpe: mo nfi Ọ wa isọ iwọ Ọlọhun Ọba mi nibi idari esu ati royiroyi rẹ.
وَأَعُوذُ بِكَ رَبِّ أَن يَحۡضُرُونِ 98
Mo si tun fi Ọ wasọ iwọ Ọlọun Ọba mi kuro nibi ki wọn maa bẹ nibi alamọri ọrọ mi.
حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَ أَحَدَهُمُ ٱلۡمَوۡتُ قَالَ رَبِّ ٱرۡجِعُونِ 99
Titi ti iku yoo fi de waa ba ikọọkan ninu awọn ẹlẹbọ wọnyi, ti yoo si fi oju ri ohun ti yoo sọkalẹ fun un, yoo wa sọpe niti kikabamọ lori ohun ti o ba mọ lọwọ ninu ọjọ ori ati ohun ti o ti se aseeto rẹ nipa Allah: iwọ Ọlọhun Ọba mi, dami pada si isẹmin aye.
لَعَلِّيٓ أَعۡمَلُ صَٰلِحٗا فِيمَا تَرَكۡتُۚ كَلَّآۚ إِنَّهَا كَلِمَةٌ هُوَ قَآئِلُهَاۖ وَمِن وَرَآئِهِم بَرۡزَخٌ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ 100
O seese ki nse isẹẹre nigbati mo ba sẹri sibẹ, ko le ri bẹẹ, ọrọ ko le ri bi o se beere fun un, o kan jẹ gbolohun la san, ohun ni o si sọ ọ, ti wọn ba da wa pada si isẹmin aye, ko le pe adehun nkan ti o sọ, bẹẹni awọn ti a pa si agbegbemeji aye ati ọrun yii yoo maa sẹku titi di ọjọ igbende ati akojọ, wọn ko nii le sẹri lọ si ile aye lati le pa ba ounti o ti bọ mọ wọn lọwọ, ki wọn si se atunse ounti wọn ti ba jẹ.
فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَلَآ أَنسَابَ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ وَلَا يَتَسَآءَلُونَ 101
Ti Malaika ti a gbe fifan fere fun ba fan fere si inu iwo ni ifanfere ẹlẹẹkeji, ti igbende yoo fi to, ko si mọlẹbi kankan laarin wọn ti wọn le fi yangan nitori awọn ipaya ọjọ ikẹyin naa, ẹnikankan ko si nii le beere lọwọ ẹnikẹni nitori kiko airoju pẹlu ohun ti o kan wọn gbangban.
فَمَن ثَقُلَتۡ مَوَٰزِينُهُۥ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ 102
Ẹniti osunwọn isẹẹre rẹ ba tẹ wọn lori awọn aburu rẹ, awọn wọnyi ni olujere pẹlu ohun ti ọwọ wọn tẹ ninu ohun ti wọn nfẹ, ati eyiti wọn jinna si ninu ohun ti wọn bẹru.
وَمَنۡ خَفَّتۡ مَوَٰزِينُهُۥ فَأُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فِي جَهَنَّمَ خَٰلِدُونَ 103
Ẹniti osunwọn isẹẹre rẹ ba si fun yẹ nitori titẹwọn aida rẹ lori daadaa, awọn wọnyi ni wọn ra ẹmin wọn lare nibi sise ohun ti yoo ko inira ba wọn ati gbigbe ju silẹ ohun ti yoo se wọn ni anfaani ninu igbagbọ ati isẹẹre, wọn yoo wa ninu ina jahannamọ lọ lailai, wọn ko si nii jade nibẹ.
تَلۡفَحُ وُجُوهَهُمُ ٱلنَّارُ وَهُمۡ فِيهَا كَٰلِحُونَ 104
Oju wọn yoo jo ina, wọn yoo wa nibẹ ni ẹniti ete oke wọn yoo ti bo ti isalẹ ati awọn eyin wọn nitori lile koko ifajuro.
Mimu ẹri wa lori ijọkan soso Allah wa nibi ririnlẹ eto aye.
Rirọkirika imọ Allah lori gbogbo nkan.
Fifi daadaa ba oluse aida lo jẹ ẹkọ ẹsin Islam ti o ga, o si mọ oripa ti o de ogongo nibi ija.
Jijẹ dandan fifi Allah wa isọ kuro nibi royiroyi esu ati isọninu rẹ.