وَجَآءَ فِرۡعَوۡنُ وَمَن قَبۡلَهُۥ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتُ بِٱلۡخَاطِئَةِ 9
Fir'aona ati awọn ti o siwaju rẹ ninu awọn ijọ de ati awọn abule eyiti wọn fi iya jẹ pẹlu yiyi ẹni giga rẹ pada si ẹni ilẹ, awọn si ni ijọ Luuth pẹlu awọn isẹ asise gẹgẹ bi ẹbọ ati awọn ẹsẹ.
فَعَصَوۡاْ رَسُولَ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَهُمۡ أَخۡذَةٗ رَّابِيَةً 10
Gbogbo si yapa ojisẹ Rẹ eyiti wọn gbe dide si wọn, wọn si pe e nirọ, Allah si gba wọn mu ni igbamun ti o le kun lori ohun ti yoo mu ki iparun wọn di pipe.
إِنَّا لَمَّا طَغَا ٱلۡمَآءُ حَمَلۡنَٰكُمۡ فِي ٱلۡجَارِيَةِ 11
Dajudaju Awa gbe awọn ti ẹ wa ni ibara idi wọn ninu ọkọ omin eyiti o nlọ eyiti Nuha ẹniti ọla nbẹ fun se pẹlu asẹ Wa nigbati omin kọja ẹnu aala rẹ nibi kikun soke, o si jẹ ẹru fun yin.
لِنَجۡعَلَهَا لَكُمۡ تَذۡكِرَةٗ وَتَعِيَهَآ أُذُنٞ وَٰعِيَةٞ 12
Ki a le sọ ọkọ oju omin naa ati itan rẹ di isiti ti wọn yoo maa fi se itọka lori mimu iparun ba ẹni keferi ati lila ẹni igbagbọ, ki eti ti o nde nkan mọlẹ le de e mọlẹ nigbati o ba gbọ ọ.
فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ نَفۡخَةٞ وَٰحِدَةٞ 13
Ti Malaika ti a la fifan fere si inu iwo ba fan fere ni ifanfere ẹẹkan, ohun si ni ifanfere ẹlẹẹkeji.
وَحُمِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةٗ وَٰحِدَةٗ 14
Ti wọn si gbe ilẹ ati oke ga, ti wọn si kan wọn ni kikan ẹẹkan ti o le koko, ti gbogbo agbegbe ilẹ ati agbegbeoke naa si di rirọ.
فَيَوۡمَئِذٖ وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ 15
Ọjọ ti gbogbo eleyi ba sẹlẹ ni igbende yoo to.
وَٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَهِيَ يَوۡمَئِذٖ وَاهِيَةٞ 16
Ti sanmọ si san ni ọjọ naa fun sisọkalẹ awọn Malaaika ninu rẹ, ni ọjọ yii yoo di lilẹ lẹyin igbati o ti jẹ lile ti o di mọ ara wọn.
وَٱلۡمَلَكُ عَلَىٰٓ أَرۡجَآئِهَاۚ وَيَحۡمِلُ عَرۡشَ رَبِّكَ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ ثَمَٰنِيَةٞ 17
Ti awọn Malaaika si wa ni eteeti rẹ ati ẹgbẹgbẹ rẹ, ti awọn Malaika alasunmọ mẹjọ si gbe itẹ Ọlọhun Rẹ ni ọjọ ti o tobi yii.
يَوۡمَئِذٖ تُعۡرَضُونَ لَا تَخۡفَىٰ مِنكُمۡ خَافِيَةٞ 18
Ni ọjọ yii, wọn yoo sẹri wọn ẹyin eniyan- si Allah, ipamọ eyikeyi ko ni pamọ fun Allah lọdọ yin bikosepe Allah nimọ nipa rẹ, yoo si ri.
فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَيَقُولُ هَآؤُمُ ٱقۡرَءُواْ كِتَٰبِيَهۡ 19
Ẹniti wọn ba fun ni iwe awọn isẹ rẹ pẹlu ọwọ ọtun, yoo sọ ni ẹni idunnu ati ayọ wipe: ẹ gba, ki ẹ si ka iwe awọn isẹ mi.
إِنِّي ظَنَنتُ أَنِّي مُلَٰقٍ حِسَابِيَهۡ 20
Dajudaju emi mọ ni ile aye, mo si mọ amdaju wipe dajudaju wọn yoo gbemi dide, emi yoo si pade ẹsan mi.
فَهُوَ فِي عِيشَةٖ رَّاضِيَةٖ 21
Yoo si wa ninu isẹmin iyọnu; nitori idẹkun gbere ti o ri.
فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٖ 22
Ninu ọgba idẹra kan ti aaye rẹ ga ati ipo.
قُطُوفُهَا دَانِيَةٞ 23
Awọn eso rẹ sun mọ ẹniti o fẹ ẹ mu.
كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيَٓٔۢا بِمَآ أَسۡلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡأَيَّامِ ٱلۡخَالِيَةِ 24
Wọn yoo sọ niti sise apọnle fun wọn: ẹ maa jẹ, ẹ maa mu niti jijẹ ati mimu ti ko si suta nibẹ nitori ohun ti ẹ ti siwaju ninu awọn isẹ rere niawọn ọjọ ti o re kọja ni ile aye.
وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِشِمَالِهِۦ فَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُوتَ كِتَٰبِيَهۡ 25
Sugbọn ẹniti wọn ba fun ni awọn iwe isẹ rẹ ni ọwọ osi yoo sọ nitori lile koko abamọ: egbe mi, ti wọn ko fun mi ni iwe awọn isẹ mi nitori awọn isẹ aburu ti o nbẹ nibẹ, ti o le sọ jijẹ iya mi di dandan.
وَلَمۡ أَدۡرِ مَا حِسَابِيَهۡ 26
Egbe mi, ti nko mọ bi isiro i yoo se jẹ.
يَٰلَيۡتَهَا كَانَتِ ٱلۡقَاضِيَةَ 27
Oma se o, ti iku ti mo ku ko jẹ iku ti wọn ko nii gbe eeyan dide lẹyin rẹ lailai.
مَآ أَغۡنَىٰ عَنِّي مَالِيَهۡۜ 28
Dukia mi ko kọ iya Allah kankan fun mi.
هَلَكَ عَنِّي سُلۡطَٰنِيَهۡ 29
Awijare mi ti bọ, ati agbara ati iyi ti mo ngbera le.
خُذُوهُ فَغُلُّوهُ 30
Wọn yoo si sọ wipe: ẹ gba a mu - ẹyin Malaaika - ẹ si so ọwọ rẹ mọ ọrun rẹ.
ثُمَّ ٱلۡجَحِيمَ صَلُّوهُ 31
Lẹyin naa ki ẹ ti wọ ina ki o le maa fi ara kin igbona rẹ.
ثُمَّ فِي سِلۡسِلَةٖ ذَرۡعُهَا سَبۡعُونَ ذِرَاعٗا فَٱسۡلُكُوهُ 32
Lẹyin naa ẹ mu wọ inu ẹwọn ti gigun rẹ jẹ aadọrin gbọndọn apa.
إِنَّهُۥ كَانَ لَا يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ ٱلۡعَظِيمِ 33
Dajudaju o jẹ ẹniti ko nigbagbọ ninu Allah ti o tobi ju.
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ 34
Kii si se ẹlomiran loju kokoro fifun alaini lounjẹ.
فَلَيۡسَ لَهُ ٱلۡيَوۡمَ هَٰهُنَا حَمِيمٞ 35
Ko si alasunmọ ti yoo kọdi kuro nibi iya naa ni ọjọ igbende.
Iregun ti o nbẹ fun obi lori ọmọ sọ ọpẹ didu di dandan.
Fifun alaini lounjẹ ati siseni loju kokoro si i wa ninu okunfa idaabobo kuro nibi iya ina.
Lile koko iya ọjọ igbende ni bukaata si wiwa isọ kuro nibẹ pẹlu igbagbọ ati isẹ rere.