وَلَمَّا جَآءَهُمۡ كِتَٰبٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٞ لِّمَا مَعَهُمۡ وَكَانُواْ مِن قَبۡلُ يَسۡتَفۡتِحُونَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَمَّا جَآءَهُم مَّا عَرَفُواْ كَفَرُواْ بِهِۦۚ فَلَعۡنَةُ ٱللَّهِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ 89
Nigbati Alukuraani Alapọnle waa ba wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba, ti o si se deede ohun ti o nbẹ ninu Taoraata ati Injeela ninu awọn ipilẹ lapapọ eyiti o ni alaafia, wọn si jẹ ẹni ti o ma nsọ siwaju ki o too sọkalẹ wipe: Awa yoo ri aranse lori awọn ọsẹbọ, wọn yoo si sina fun wa nigbati wọn ba gbe Anọbi kan dide, ti a o si ni igbagbọ pẹlu rẹ, ti a o si tẹle, nigbati Alukuraani ati Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) lori iroyin eyiti wọn ti mọ, ati ododo eyiti wọn ti mọ; wọn se aimoore pẹlu rẹ, igbejina si ikẹ Ọlọhun ki o maa bẹ fun awọn ti wọn se aimoore pẹlu Ọlọhun Ọba ati ojisẹ Rẹ.
بِئۡسَمَا ٱشۡتَرَوۡاْ بِهِۦٓ أَنفُسَهُمۡ أَن يَكۡفُرُواْ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بَغۡيًا أَن يُنَزِّلَ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۖ فَبَآءُو بِغَضَبٍ عَلَىٰ غَضَبٖۚ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٞ مُّهِينٞ 90
Siọ ohun ti wọn fi paarọ erenjẹ ẹmin wọn nibi nini igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba ati ojisẹ Rẹ; wọn waa se aimoore pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ, ti wọn si pe awọn ojisẹ Rẹ ni irọ niti abosi ati sise keeta, nitori sisọ ijẹ Anọbi kalẹ ati Alukuraani fun Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) , ohun ni wọn fi ni ẹtọ si ibinu to nipọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) pẹlu sise aimoore pẹlu Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) , ati pẹlu okunfa yiyi ti wọn yi Taoraata pada siwaju. O nbẹ fun awọn ti wọn se aimoore pẹlu ijẹ Anọbi ti Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) jẹ, iya ti o ma nyẹpẹrẹ eniyan ni ọjọ igbende.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ ءَامِنُواْ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ قَالُواْ نُؤۡمِنُ بِمَآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا وَيَكۡفُرُونَ بِمَا وَرَآءَهُۥ وَهُوَ ٱلۡحَقُّ مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَهُمۡۗ قُلۡ فَلِمَ تَقۡتُلُونَ أَنۢبِيَآءَ ٱللَّهِ مِن قَبۡلُ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 91
Ti wọn ba sọ fun awọn Yahuudi yii wipe: ẹ ni igbagbọ pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ ninu ododo ati imọna, wọn yoo sọ wipe: A ni igbagbọ pẹlu ohun ti wọn sọkalẹ fun awọn anọbi wa, wọn si nse aimoore pẹlu ohun ti o ba yatọ sii ninu ohun ti wọn sọkalẹ fun Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) , pẹlu wipe dajudaju Alukuraani yii ohun ni ododo eyiti o se deede ohun ti nbẹ pẹlu wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba, ti o ba jẹ wipe wọn jẹ ẹniti o ni igbagbọ pẹlu ohun ti wọn sọkalẹ fun wọn ni tootọ ni, wọn ko ba ni igbagbọ pẹlu Alukuraani. Sọ wipe: - Irẹ Anọbi - niti idawọn lohun: kini idi ti ẹ fi npa awọn Anọbi Ọlọhun Ọba tẹlẹ ti o ba jẹ wipe ẹ jẹ olugbagbọ ododo niti tootọ pẹlu ohun ti wọn mu waa ba yin ninu ododo?!
۞وَلَقَدۡ جَآءَكُم مُّوسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ ثُمَّ ٱتَّخَذۡتُمُ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَنتُمۡ ظَٰلِمُونَ 92
Paapa o ti mu wa ba yin ojisẹ yin tii se Muusa (ki ọla maa ba) awọn amin ti o fi oju han eyiti ntọka si isododo rẹ, lẹyin igba naa; ẹ waa mu ogedengbe maalu ni ọlọhun, ti ẹ wa nsin in, lẹyin igbati Muusa ti lọ fun adehun Ọlọhun Ọba rẹ, ti ẹyin si jẹ alabosi nitori mimu orogun yin pẹlu Ọlọhun Ọba, ti o si jẹ wipe Oun ni o ni ẹtọ si ijọsin lohun nikan laisin ẹlomiran.
وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ وَرَفَعۡنَا فَوۡقَكُمُ ٱلطُّورَ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱسۡمَعُواْۖ قَالُواْ سَمِعۡنَا وَعَصَيۡنَا وَأُشۡرِبُواْ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلۡعِجۡلَ بِكُفۡرِهِمۡۚ قُلۡ بِئۡسَمَا يَأۡمُرُكُم بِهِۦٓ إِيمَٰنُكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 93
Ẹ ranti nigbati A gba adehun ti o ni ikanpamọ lori yin pẹlu titẹle Muusa (ki ọla maa jẹ tirẹ) , ati gbigba ohun ti o mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba, A gbe oke leyin lori niti idẹru ba yin, A wa sọ fun yin wipe: ẹ gba ohun ti A fun yin mu ninu Taoreeta pẹlu igbiyanju ati isapa, ki ẹ si maa tẹti ni titẹti gbigba ati itẹle asẹ Ọlọhun Ọba, ti ẹ ba wa kọ A o ja oke leyin lori, ni ẹ ba sọ wipe: a gbọ pẹlu awọn eti wa, a si yapa pẹlu awọn isẹ wa, sisin ogedengbe maalu waa ri aaye ninu ọkan wọn nitori sise aimoore wọn. Sọ - irẹ Anọbi -: siọ ohun ti igbagbọ yi npayin lasẹ rẹ ninu sise aimoore pẹlu Ọlọhun Ọba ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ododo; toripe dajudaju igbagbọ ododo, aimoore ko nii wa pẹlu rẹ.
Awọn Yahuudi ni ẹniti keete wọn tobi pupọ ninu ọmọniyan; nigbati keeta wọn ti gbe wọn lọ si ibi sise aimoore ati kikọ ohun ti O sọkalẹ, pẹlu idi wipe Ojisẹ (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba) ko wa lati aarin wọn.
Dajudaju ini igbagbọ ododo pẹlu Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) yoo sọ gbigba gbogbo ohun ti o sọkalẹ ninu tira gbọ di dandan ati pẹlu gbogbo awọn ti O ran ninu awọn ojisẹ.
Ninu abosi ti o tobi ju ni gigunri kuro nibi ododo ati imọna lẹyin mimọ ati riri ẹri lori rẹ.
Ninu isesi awọn Yahuudi, ni titu ajọsọpọ ati awọn adehun, eleyi ni adamọ wọn titi ti o fi di oni.