فَأَخۡرَجَ لَهُمۡ عِجۡلٗا جَسَدٗا لَّهُۥ خُوَارٞ فَقَالُواْ هَٰذَآ إِلَٰهُكُمۡ وَإِلَٰهُ مُوسَىٰ فَنَسِيَ 88
Samiriyu si mu jade ninu nkan ọsọ naa fun awọn ọmọ isirẹli odidi ara ogedengbe maalu ti ko ni ẹmin, o ni ohun gẹgẹ bi ohun maalu, ẹniti o kan adanwo ninu wọn pẹlu isẹ samiriyu sọpe: eleyi ni nkan ijọsin yin ati nkan ijọsin Musa, o gbagbe rẹ, o si gbe ju silẹ ni ibi yii.
أَفَلَا يَرَوۡنَ أَلَّا يَرۡجِعُ إِلَيۡهِمۡ قَوۡلٗا وَلَا يَمۡلِكُ لَهُمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا 89
Se awọn ti wọn kan adanwo pẹlu ogedegbe maalu, ti wọn si nsin in ko mọ ni wipe ogedegbe maalu naa ko le ba wọn sọrọ bẹẹni ko le da wọn lohun, ko si lagbara lati mu inira kuro fun wọn, tabi mu kuro lọdọ ẹlomiran ti o yatọ si wọn, ko si le mu anfaani kankan fun un tabi ẹniti o yatọ si i?!
وَلَقَدۡ قَالَ لَهُمۡ هَٰرُونُ مِن قَبۡلُ يَٰقَوۡمِ إِنَّمَا فُتِنتُم بِهِۦۖ وَإِنَّ رَبَّكُمُ ٱلرَّحۡمَٰنُ فَٱتَّبِعُونِي وَأَطِيعُوٓاْ أَمۡرِي 90
Paapaa Haruna ti sọ fun wọn siwaju ki Musa to lọ sẹri ba wọn, ohun ti o nbẹ nibi rirọ ogedegbe maalu lati ibi wura tabi ẹyọ rẹ ko jẹ nkankan ju adanwo fun yin lọ, ki olugbagbọ ododo le han kuro nibi keferi, bẹẹni dajudaju Ọlọhun Ọba yin - ẹyin ijọ - Oun ni ẹniti O nikapa ikẹ, kii sii se ẹniti ko ni agbara lati fi inira tabi anfaani se yin debi ki o wa kẹ yin, ki ẹ yaa tẹle mi nibi ijọsin Rẹ ni Oun nikan soso, ki ẹ si maa tẹle asẹ mi pẹlu gbigbe ijọsin ohun ti o yatọ si ju silẹ.
قَالُواْ لَن نَّبۡرَحَ عَلَيۡهِ عَٰكِفِينَ حَتَّىٰ يَرۡجِعَ إِلَيۡنَا مُوسَىٰ 91
Ẹniti o kan adanwo nibi ogedegbe maalu sọpe: a ko nii yẹ ni ẹniti yoo duro lori ijọsin rẹ titi ti Musa yoo fi sẹri waa ba wa.
قَالَ يَٰهَٰرُونُ مَا مَنَعَكَ إِذۡ رَأَيۡتَهُمۡ ضَلُّوٓاْ 92
Musa sọ fun ọmọ iya rẹ Haruna: kinni o kọ fun ọ nigbati o ri wọn ti wọn sọnu pẹlu sinsin ogedegbe maalu yatọ si Allah.
أَلَّا تَتَّبِعَنِۖ أَفَعَصَيۡتَ أَمۡرِي 93
Lati fi wọn silẹ, ki o si wa pẹlu mi?! Se iwọ yoo yapa asẹ mi ni nigbati mo fi ọ role le wọn lori?!
قَالَ يَبۡنَؤُمَّ لَا تَأۡخُذۡ بِلِحۡيَتِي وَلَا بِرَأۡسِيٓۖ إِنِّي خَشِيتُ أَن تَقُولَ فَرَّقۡتَ بَيۡنَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَلَمۡ تَرۡقُبۡ قَوۡلِي 94
Nigbati Musa gba irugbọn ọmọ iya rẹ mu ati irun ori rẹ, o fa a mọ ọdọ niti kikorira nkan ti o se, haruna si sọ fun niti wiwa aanu lọdọ rẹ: mase gba irugbọn mi tabi irun ori mu dajudaju awijare wa fun mi nibi sisẹku pẹlu wọn, paapaa mo npaya ti mo ba fi wọn silẹ la wọn nikan soso, ki wọn ma baa yapa, ki o ma ba waa sọpe dajudaju emi ni mo pin wọn ati emi ko sọ asọtẹlẹ rẹ nipa wọn.
قَالَ فَمَا خَطۡبُكَ يَٰسَٰمِرِيُّ 95
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun samiriyu: kinni ti ẹ irẹ samiriyu, kinni o si ti ọ lọ si ibi ohun ti o se?
قَالَ بَصُرۡتُ بِمَا لَمۡ يَبۡصُرُواْ بِهِۦ فَقَبَضۡتُ قَبۡضَةٗ مِّنۡ أَثَرِ ٱلرَّسُولِ فَنَبَذۡتُهَا وَكَذَٰلِكَ سَوَّلَتۡ لِي نَفۡسِي 96
Samiriyu sọ fun musa ẹniti ọla nbẹ fun: mo ri nkan ti wọn ko ri, paapaa mo ri Jibrilu lori ẹsin, mo si bu ẹkunwọ iyẹpẹ nibi oripa ẹsin rẹ, mo si daa si ọsọ wura eyiti wọn ti rọ ni aworan maalu, bayi ni ogedegbe maalu ti o ni ara se jẹ jade, bayi ni ẹmin mi se ri oun ti mo se ni nkan ti o dara.
قَالَ فَٱذۡهَبۡ فَإِنَّ لَكَ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ أَن تَقُولَ لَا مِسَاسَۖ وَإِنَّ لَكَ مَوۡعِدٗا لَّن تُخۡلَفَهُۥۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰٓ إِلَٰهِكَ ٱلَّذِي ظَلۡتَ عَلَيۡهِ عَاكِفٗاۖ لَّنُحَرِّقَنَّهُۥ ثُمَّ لَنَنسِفَنَّهُۥ فِي ٱلۡيَمِّ نَسۡفًا 97
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun samiriyu ki o yara maa lọ, ki o si maa sọ nigbati o ba si nsẹmin: emi ko ni fi ọwọ kan, emi ko ni fi ọwọ kan, ki o wa maa sẹmin ni ẹni itakete, bẹẹni adehun nbẹ fun ọ ni ọjọ igbende, ti iwọ yoo se isiro nibẹ, ti wọn yoo si fi iya jẹ ọ, Ọlọhun Allah ko nii yapa adehun Rẹ yii, ki o si woye si ogedegbe rẹ eyiti o mu ni nkan ijọsin, ti o si duro lori ijọsin rẹ yatọ si Allah, awa yoo kona mọ wọn titi ti wọn yoo fi maa yọ, bẹẹni a o fi omin wọ wọn lọ titi ti ko fi nii sẹku oripa rẹ.
إِنَّمَآ إِلَٰهُكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ وَسِعَ كُلَّ شَيۡءٍ عِلۡمٗا 98
Dajudaju Ẹniti O yẹ ki ẹ sin niti tootọ -ẹyin eniyan- Oun ni Allah eyiti ko si ẹni ijọsin fun tootọ yatọ si I, imọ Rẹ rọkirika gbogbo nkan, imọ nkankan ko le bọ mọ lọwọ.
Titan awọn eniyan jẹ pẹlu fifi juuju bo awọn ododo jẹ ọna awọn anu.
Ibinu ti a fẹ ni eyiti o sẹlẹ nigbati wọn ba nfa awọn eewọ Ọlọhun Allah ya.
Ipilẹ lile awọn ẹni adadaalẹ ati awọn ẹsẹ ati yiyan wọn lodi wa ninu awọn aayah naa ati mima darapọ mọ wọn.
Jijẹ dandan ironu nipa mimọ Allah ti O ga lati ara awọn isẹ Rẹ ninu aye wa ninu awọn aayah naa.