رَضُواْ بِأَن يَكُونُواْ مَعَ ٱلۡخَوَالِفِ وَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ فَهُمۡ لَا يَفۡقَهُونَ 87
Awọn sọbẹ selu yii nifẹ si iyẹpẹrẹ ati irẹlẹ fun ẹmin ara wọn nigbati wọn ti le yọnu lati yapa pẹlu awọn alawijare, Ọlọhun Ọba Allah waa fi edidi di ọkan wọn nitori keferi wọn ati sọbẹ selu wọn, wọn ko le mọ ohun ti yoo se wọn ni anfaani.
لَٰكِنِ ٱلرَّسُولُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ جَٰهَدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلۡخَيۡرَٰتُۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ 88
Sugbọn ojisẹ naa ati awọn olugbagbọ ododo ti wọn wa pẹlu rẹ, awọn ko yapa kuro ni ibi igbiyanju si oju ọna Allah gẹgẹ bi awọn eniyan wọnyi, bikkse wipe wọn se igbiyanju si oju ọna ti Allah pẹlu dukia wọn ati ẹmin wọn, ẹsan wọn lọdọ Ọlọhun jẹ awọn anfaani ti ile aye ti yoo sẹlẹ fun wọn gẹgẹbi aranse ati awọn ikogun, ati awọn anfaani ti ọrun ti yoo tun sẹlẹ, ninu rẹ ni wiwọ alujannah ati erenjẹ nkan ti wọn ba nfẹ ti yoo sẹlẹ ati lila kuro nibi nkan ti wọn ko ba nifẹ si.
أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 89
Ọlọhun Ọba Allah pese awọn alujannah eyiti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ fun wọn, wọn yoo si maa gbe ibẹ gbere, titan ko nii sẹlẹ si wọn, ẹsan yi ni erenjẹ ti o tobi ju, ti erenjẹ miran ko lee le ba.
وَجَآءَ ٱلۡمُعَذِّرُونَ مِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ لِيُؤۡذَنَ لَهُمۡ وَقَعَدَ ٱلَّذِينَ كَذَبُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥۚ سَيُصِيبُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 90
Awọn ijọ kan ninu awọn ijọ larubawa madinah de ati awọn ti o nbẹ ni agbegbe rẹ, wọn si nwa awijare ni ọdọ ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ki o le yọnda fun wọn lati yapa ki wọn ma baa se igbiyanju si oju ọna Ọlọhun, bẹẹ ni awọn ijọ miran si tun yapa, ti wọn ko wi awijare rara lati mase jade; nitori aida Anọbi lododo, ati nitori ainigbagbọ si adehun Allah, iya ẹlẹta elero yoo kan awọn eniyan wọnyi nitori sise keferi wọn.
لَّيۡسَ عَلَى ٱلضُّعَفَآءِ وَلَا عَلَى ٱلۡمَرۡضَىٰ وَلَا عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ مَا يُنفِقُونَ حَرَجٌ إِذَا نَصَحُواْ لِلَّهِ وَرَسُولِهِۦۚ مَا عَلَى ٱلۡمُحۡسِنِينَ مِن سَبِيلٖۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 91
Kii se dandan fun awọn obinrin ati awọn ọmọ keekeeke ati awọn alarẹ ati awọn olukagara ati awọn afọju ati awọn alaini, awọn ti wọn ko le ri nkankan ti wọn le na ninu owo, ki wọn le fi esenpa, ko si ẹsẹ fun awọn eniyan wọnyi lapapọ nibi yiyapa wọn lati jade nitori wipe awọn awijare wọn fi ẹsẹ rinlẹ nigbati wọn ba ti se afọmọ fun Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si se ofin Rẹ, ko si oju ọna kankan fun awọn ẹniire ninu awọn alawijare yii lati wọ inu iya Ọlọhun Ọba, Ọlọhun Ọba jẹ alaforijin ẹsẹ awọn oluse daadaa, Yoo si kẹ wọn.
وَلَا عَلَى ٱلَّذِينَ إِذَا مَآ أَتَوۡكَ لِتَحۡمِلَهُمۡ قُلۡتَ لَآ أَجِدُ مَآ أَحۡمِلُكُمۡ عَلَيۡهِ تَوَلَّواْ وَّأَعۡيُنُهُمۡ تَفِيضُ مِنَ ٱلدَّمۡعِ حَزَنًا أَلَّا يَجِدُواْ مَا يُنفِقُونَ 92
Bakanna ko si ẹsẹ fun awọn ti wọn yapa kuro ni ọdọ rẹ, awọn ti o ja si wipe ti wọn ba waa ba ọ - irẹ ojisẹ - wọn yoo maa beere fun nkan igun ti yoo gbe wọn, ti o si sọ fun wọn wipe: nko ri oun ti yoo gbe yin ninu nkan igun; wọn pẹyin da kuro ni ọdọ rẹ, oju wọn si nsomin niti ibọkanjẹ lori wipe wọn ko ri oun ti wọn yoo na lati ọdọ ara wọn tabi lati ọdọ rẹ.
۞إِنَّمَا ٱلسَّبِيلُ عَلَى ٱلَّذِينَ يَسۡتَٔۡذِنُونَكَ وَهُمۡ أَغۡنِيَآءُۚ رَضُواْ بِأَن يَكُونُواْ مَعَ ٱلۡخَوَالِفِ وَطَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ فَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 93
Nigbati Ọlọhun Ọba salaye wipe ko si ọna ijiya fun awọn ti wọn ni awijare, O tun wa salaye ẹniti o lọtẹ si iya ati igbamun, O si sọ wipe: ọna iya ati igbamun wa fun awọn ẹniti wọn nbeere lọdọ rẹ -ire ojise- iyọnda lati yapa kuro nibi igbiyanju, ti wọṣn si lagbara lati ri nkan ti wọn yoo fi pese, wọn nifẹ si iyẹpẹrẹ fun ẹmin ara wọn ati irẹlẹ nitori wipe wọn wa pẹlu awọn oluyapa ninu ile, Ọlọhun Ọba Allah waa fi edidi di ọkan wọn ti ko le lapa pẹlu isiti, lati ara edidi yii, wọn ko le ohun ti o le wulo fun wọn lati saa lẹsa ati ohun ti o le pa wọn lara ti yoo fi jinna si i.
Awọn olugbiyanju yoo ri awọn oore ni ile aye koda bi eleyi fo wọn ru, erenjẹ alujannah nbẹ fun wọn ati ọla kuro nibi iya ọrun.
Ipilẹ ni wipe oluse daadaa si awọn eniyan niti apọnle ko nii ri igbamun koda bi aseeto sẹlẹ lati ọdọ rẹ.
Dajudaju ẹniti o ba gbero rere ti o wa fi si inu ọkan rẹ lati sapa lori ohun ti o lagbara sugbọn ti ko ni ikapa –yoo wa ni ipo ẹniti o se e.
Islam jẹ ẹsin deedee ati ọgbọn toribẹẹ ni o se se iya ni ọranyan ati ẹsẹ lori awọn sọbẹ selu ti wọn gbayọnda, ti wọn si jẹ ọlọrọ ti wọn ni ikapa lati se igbiyanju pẹlu dukia ati ẹmin.