وَمَا لَنَا لَا نُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَمَا جَآءَنَا مِنَ ٱلۡحَقِّ وَنَطۡمَعُ أَن يُدۡخِلَنَا رَبُّنَا مَعَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلصَّٰلِحِينَ 84
okunfa wo ni yoo kọ di wa kuro nibi igbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah ati si ohun ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ ni ododo eyiti Anọbi Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mu wa ba wa? ! Ti a si ngbero wiwọ Alujannah pẹlu awọn Anọbi ati awọn olutẹle wọn, awọn ti wọn ntẹle ti Ọlọhun Ọba Allah niti ipaya kuro nibi iya Rẹ.
فَأَثَٰبَهُمُ ٱللَّهُ بِمَا قَالُواْ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 85
Ọlọhun Ọba Allah waa san wọn lẹsan lori igbagbọ wọn ati ijupajusẹ wọn silẹ fun ododo, O fi Alujannah ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule bẹ ati awọn igi bẹ, ni ẹniti yoo maa gbe ibẹ gbere, eleyi jẹ ẹsan fun awọn oluse daada lori titẹle ododo wọn ati titẹribẹ fun Un laisi idina tabi majẹmu.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَآ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ 86
Awọn ti wọn se aimoore si Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si pe awọn amin Allah ti O sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ ni irọ, awọn wọnyi ni wọn dunni mọ ina eyiti o njo gbere-gbere, wọn ko ni jade nibẹ lailai.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُحَرِّمُواْ طَيِّبَٰتِ مَآ أَحَلَّ ٱللَّهُ لَكُمۡ وَلَا تَعۡتَدُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُعۡتَدِينَ 87
Ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo, ẹ mase awọn nkan aladidun ti o tọ ni eewọ ninu awọn nkan jijẹ, mimu ati fifẹ ara ẹni, ẹ mase ni eewọ niti irayesa ati fifi se ijọsin, ẹ si ma kọja ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah nkan ti O se ni eewọ fun yin, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nifẹ si awọn olukọja ẹnu aala Rẹ, bikose wipe O korira wọn.
وَكُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ حَلَٰلٗا طَيِّبٗاۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ أَنتُم بِهِۦ مُؤۡمِنُونَ 88
Ẹ maa jẹ ninu awọn nkan ti Ọlọhun Ọba Allah dari si ọdọ yin ninu arisiki ni igbati o ba tọ, ti o si dara, kii se nigba ti o ba jẹ eewọ gẹgẹ bi nkan ti a ja gba tabi ti o jẹ ẹlẹgbin, ẹ bẹru Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si nkan ti O kọ, Oun ni ẹniti ẹ nigbagbọ si, bẹẹ ni igbagbọ yin si I gbọdọ sọ bibẹru Rẹ di ọranyan leyin lori.
لَا يُؤَاخِذُكُمُ ٱللَّهُ بِٱللَّغۡوِ فِيٓ أَيۡمَٰنِكُمۡ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا عَقَّدتُّمُ ٱلۡأَيۡمَٰنَۖ فَكَفَّٰرَتُهُۥٓ إِطۡعَامُ عَشَرَةِ مَسَٰكِينَ مِنۡ أَوۡسَطِ مَا تُطۡعِمُونَ أَهۡلِيكُمۡ أَوۡ كِسۡوَتُهُمۡ أَوۡ تَحۡرِيرُ رَقَبَةٖۖ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖۚ ذَٰلِكَ كَفَّٰرَةُ أَيۡمَٰنِكُمۡ إِذَا حَلَفۡتُمۡۚ وَٱحۡفَظُوٓاْ أَيۡمَٰنَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 89
Ọlọhun Ọba Allah ko nii se isiro yin - ẹyin olugbagbọ ododo - lori ohun ti o ti ahọn yin jade ninu ibura ti ẹ ko gbero rẹ, bikose wipe yoo se isiro yin lori ohun ti ẹ ba pinnu le lori, ti ẹ takoko ọkan yin le lori, ti ẹ si sọ di ijọsin, Yoo maa pa ẹsẹ ohun ti ẹ ba pinnu rẹ fun yin, bii ibura eyiti ẹ sọ jade nigbati ẹ nse ijọsin lati ara sise ẹsa nkan mẹta yii: fifun alaini mẹwa ni ounjẹ, bii ounjẹ iwọtu-wọnsi ara ilu yin, alaini kọọkan yoo maa gba ilaji “sọọ’hi” tabi wiwọ wọn ni ẹwu pẹlu ohun ti o jẹ asọ asa tabi bibọkun kuro ni ọrun ẹru olugbagbọ ododo, ti ẹniti o fẹ pa ibura rẹ ko ba ri ọkan ninu awọn nkan mẹta yii, yoo fi aawẹ ọjọ mẹta paarẹ, eyiti a sọ lọ yii ni iparẹ awọn ibura yin - ẹyin olugbagbọ ododo - nigbati ẹ ba bura, ti ẹ si fi se ijọsin, ẹ sọ ibura yin kuro nibi fifi Ọlọhun Ọba Allah bura niti irọ, tabi fifi Ọlọhun Ọba Allah bura ni ọpọ igba, ati sise afẹku pipe adehun pẹlu ibura niwọnba igbati sise afẹku pipe adehun ko ba jẹ daada, ki ẹ yaa maa se daadaa, ki ẹ si maa pa awọn ibura yin rẹ gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba Allah se se alaye pipa ibura rẹ fun yin, Ọlọhun Ọba Allah nsalaye awọn idajọ Rẹ fun yin eyiti o fi oju han, ninu ẹtọ ati eewọ, ki ẹ le ba jẹ eniti yoo dupẹ lori wipe Ọlọhun Ọba Allah fi ohun ti ẹ ko mọ mọ yin.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّمَا ٱلۡخَمۡرُ وَٱلۡمَيۡسِرُ وَٱلۡأَنصَابُ وَٱلۡأَزۡلَٰمُ رِجۡسٞ مِّنۡ عَمَلِ ٱلشَّيۡطَٰنِ فَٱجۡتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 90
Ẹyin olugbagbọ ododo, dajudaju ohun ti nmuni hunrira, ti nmu laakaye lọ ati tẹtẹ eyiti o ma nfi si ọdọ awọn ẹnikan ju ẹnikan lọ, ati okuta eyiti awọn ẹlẹbọ ma ndu ẹran nibẹ niti gbigbe titobi fun Un ati sise ijọsin pẹlu rẹ, ati ife tabi igba eyiti wọn fi ma nwa kọkọ ti Ọlọhun Ọba Allah pin fun wọn, gbogbo eleyi jẹ ẹsẹ ninu sise loju ọyin esu, ki ẹ jinna sii, ki ẹ le ba jere pẹlu isẹmi alapọnle ni aye ati idẹkun Alujannah ni ọrun.
Asẹ lori wiwa arisiki ni ọna ti o tọ ati gbigbe ibajẹ ju silẹ.
Aisi igbamu lori ibura nigbati ko ba jẹ ipinnu lori ọkan, ati igbamun eyiti o wa lori ipinnu ọkan, wipe maa se bayi tabi mi o nii se.
Sise alaye lori pipa awọn ibura rẹ: fifun awọn alaini mẹwa ni ounjẹ tabi wiọ wọn ni asọ tabi bibọkun kuro lọrun olugbagbọ ododo, ti olupa ibura rẹ ko lagbara lati mu ọkan wa ninu awọn nkan ti a ti siwaju yii, ki o ya fi aawẹ ọjọ mẹta pa ibura rẹ rẹ.
Gbolohun Ọlọhun Ọba Allah ti o ga: (...إِنَّمَا ٱلۡخَمۡرُ...) (… dajudaju ọti . . . ) eyi ni aayah ti o sọ kalẹ kanyin nipa ọti, ohun ni o se ni eewọ tan yan-yan.