وَٱجۡعَل لِّي لِسَانَ صِدۡقٖ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ 84
Se iranti ti o rẹwa fun mi ati ẹyin eyiti o dara ninu awọn ti o nbẹ ni ọgọrun ọdun lẹyin mi.
وَٱجۡعَلۡنِي مِن وَرَثَةِ جَنَّةِ ٱلنَّعِيمِ 85
Se mi ninu ẹniti yoo jogun awọn ibugbe Alujannah eyiti awọn ẹru rẹ olugbagbọ ododo yoo maa gbadun nibẹ, ki o si mu mi gbe ninu rẹ.
وَٱغۡفِرۡ لِأَبِيٓ إِنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلضَّآلِّينَ 86
Fi ori ẹsẹ baba mi jin in; dajudaju o wa ninu awọn olusọnu kuro nibi ododo nitori ẹbọ; Ibrahim bẹ Ọlọhun rẹ fun baba rẹ siwaju ki o to han si wipe o wa ninu awọn ẹni ina jahiimu, nigbati eleyi han si, o bọpa bọsẹ kuro nibẹ, ko si se adura fun un.
وَلَا تُخۡزِنِي يَوۡمَ يُبۡعَثُونَ 87
Mase yẹyẹ mi pẹlu iya ni ọjọ ti wọn yoo gbe awọn eniyan dide fun isiro.
يَوۡمَ لَا يَنفَعُ مَالٞ وَلَا بَنُونَ 88
Ọjọ ti dukia ti ọmọniyan ti ko jọ ni ile aye ko nii se anfaani nibẹ, bẹẹni awọn ọmọ ti o ran wọn se.
إِلَّا مَنۡ أَتَى ٱللَّهَ بِقَلۡبٖ سَلِيمٖ 89
Ayaafi ẹniti Allah ba mu wa ọkan mimọ; ti ko si ẹbọ tabi sọbẹ selu tabi sekarimi tabi motomoto nibẹ; dajudaju yoo se anfaani pẹlu dukia rẹ eyiti o na si oju ọna Allah ati awọn ọmọ rẹ eyiti wọn nse adua fun un.
وَأُزۡلِفَتِ ٱلۡجَنَّةُ لِلۡمُتَّقِينَ 90
Bẹẹni wọn sun Alujannah mọ awọn olugbagbọ ododo ninu Ọlọhun Ọba wọn pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijina si awọn nkan ti O kọ.
وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِلۡغَاوِينَ 91
Wọn si fi ina han nibi akojọ fun awọn olusọnu ti wọn ti sọnu kuro nibi ẹsin ododo.
وَقِيلَ لَهُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تَعۡبُدُونَ 92
Wọn si nsọ fun wọn ni ẹniti o ntẹ ẹ mọ wọn leti: nibo ni awọn ohun ti ẹ nsin loosa wa?
مِن دُونِ ٱللَّهِ هَلۡ يَنصُرُونَكُمۡ أَوۡ يَنتَصِرُونَ 93
Ẹ nsin wọn yatọ si Allah? Se wọn yoo ran yin nibi kikọ iya Allah kuro fun yin tabi wọn yoo se aranse fun ẹmin ara wọn bi?
فَكُبۡكِبُواْ فِيهَا هُمۡ وَٱلۡغَاوُۥنَ 94
Wọn yoo wa ju apakan wọn si inu ina jahiimu lori apakan awọn ati ounti o sọ wọn nu.
وَجُنُودُ إِبۡلِيسَ أَجۡمَعُونَ 95
Ati awọn olukunlọwọ ibilisu ninu awọn esu lalapọ, wọn ko nii se adayanri ẹnikankan ninu wọn.
قَالُواْ وَهُمۡ فِيهَا يَخۡتَصِمُونَ 96
Awọn ẹlẹbọ ti o nsin nkan miran yatọ si Allah sọ wipe; ti wọn si mu wọn ni akẹgbẹ yatọ si I, wọn si nba ja ẹniti o nsin wọn yatọ si i:
تَٱللَّهِ إِن كُنَّا لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ 97
A fi Allah bura paapaa a ti wa ni oju ọna anu ti o fi oju han kuro nibi ododo.
إِذۡ نُسَوِّيكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 98
Nigbati a nmuyin gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba ti O da gbogbo ẹda patapata, a si nsin yin gẹgẹ bi a se nsin In.
وَمَآ أَضَلَّنَآ إِلَّا ٱلۡمُجۡرِمُونَ 99
Ko si ẹniti o nu wa kuro ni oju ọna ododo ayaafi awọn ẹlẹsẹ ti o pe wa lọ si ibi mima si wọn yatọ si Allah.
فَمَا لَنَا مِن شَٰفِعِينَ 100
Ko si awọn olusipẹ fun ti yoo sipẹ fun wa ni ọdọ Allah lati la wa kuro nibi iya Rẹ.
وَلَا صَدِيقٍ حَمِيمٖ 101
Ko si si ọrẹ ti o mọ ninu ifẹ, ti yoo kọ fun wa, ti yoo si sipẹ fun wa.
فَلَوۡ أَنَّ لَنَا كَرَّةٗ فَنَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 102
Ti isẹri lọ si isẹmin aye ba wa fun wa ni, a ba wa ninu awọn olugbagbọ ododo si Allah.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 103
Dajudaju eyiti a sọ ninu itan Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun yii, ati ibusẹri si awọn olupurọ naa jẹ ariwoye fun awọn oluwoye, bẹẹni ọpọ wọn kii se olugbagbọ ododo.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 104
Ati wipe dajudaju Ọlọhun ọba rẹ - irẹ ojisẹ - jẹ Alagbara eyiti ngba ẹ si tẹle misan lara awọn ọta Rẹ; onikẹ fun ẹniti o ba ronu piwada ninu wọn.
كَذَّبَتۡ قَوۡمُ نُوحٍ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 105
Ijọ Nuha pe awọn ojisẹ nirọ nigbati wọn pe Nuha ẹniti ọla nbẹ fun nirọ.
إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ نُوحٌ أَلَا تَتَّقُونَ 106
Nigbati ọmọ iyawọn ninu mọlebi Nuha sọ fun wọn: se ẹ ko paya Allah pẹlu gbigbe sinsin ẹlomiran ti o yatọ si I ju silẹ niti ibẹru Rẹ ni?!
إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ 107
Dajudaju emi jẹ ojisẹ fun yin ti Allah ran mi si yin, ẹni ifọkanbalẹ ti nko si le se alekun lori imisi ti Allah fi ran sẹ si mi, bẹẹ ni nko le din in ku.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 108
Ki ẹ ya bẹru Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo ba npayin lasẹ rẹ ati ohun ti mo nkọ fun yin kuro nibẹ.
وَمَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 109
Nko si wa ẹsan lori ohun ti mo fi to yin leti lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ẹsan mi ko jẹ lati ibi kankan ju ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti O ntọju gbogbo ẹda lọ, kii se lọdọ ẹlomiran.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 110
Ki ẹ yaa paya Allah pẹlu mima tẹle awọn asẹ RẸ ati jinna si ohun ti o kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo npayin lasẹ rẹ ati ohun ti mo ba kọ fun yin kuro nibẹ.
۞قَالُوٓاْ أَنُؤۡمِنُ لَكَ وَٱتَّبَعَكَ ٱلۡأَرۡذَلُونَ 111
Awọn ijọ rẹ sọ fun pe: se a o wa gba ọ gbọ - irẹ Nuha - a o wa tẹle ohun ti o mu wa, a o wa maa se e, ti o si jẹ wipe awọn ti wọn ntẹle ọ jẹ ẹniti o yẹpẹrẹ ninu awọn eniyan, ko si adari tabi awọn iyi ninu wọn?!
Pataki lila ọkan kuro nibi awọn aarẹ gẹgẹ bi keeta sekarimi ati motomoto.
Mimu ojuse rẹ kuro nibi anu lori awọn ẹni anu ko le se anfaani fun awọn ẹni anu.
Pipe ojisẹ Allah nirọ jẹ pipe gbogbo awọn ojisẹ nirọ.
Didara bibapa kuro nibi itan Ibrahim jẹ ilenilọsi ibi iranti ọjọ igbende, lẹyin naa ni sisẹri lọ si ibi itan naa.