وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ لَا تَسۡفِكُونَ دِمَآءَكُمۡ وَلَا تُخۡرِجُونَ أَنفُسَكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ ثُمَّ أَقۡرَرۡتُمۡ وَأَنتُمۡ تَشۡهَدُونَ 84
Ẹ ranti adehun ti o ni ikanpamọ eyiti A gba lori yin, ninu Taoraata nibi sise itajẹ apakan yin silẹ ni eewọ ati sise yiyọ apakan yin jade ninu ilee wọn leewọ, lẹyin igbannaa ni ẹ jọwọ ara yin fun ohun ti A gba lori yin ninu adehun pẹlu nkan naa; ti ẹyin si jẹri lori nini alaafia rẹ.
ثُمَّ أَنتُمۡ هَٰٓؤُلَآءِ تَقۡتُلُونَ أَنفُسَكُمۡ وَتُخۡرِجُونَ فَرِيقٗا مِّنكُم مِّن دِيَٰرِهِمۡ تَظَٰهَرُونَ عَلَيۡهِم بِٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِ وَإِن يَأۡتُوكُمۡ أُسَٰرَىٰ تُفَٰدُوهُمۡ وَهُوَ مُحَرَّمٌ عَلَيۡكُمۡ إِخۡرَاجُهُمۡۚ أَفَتُؤۡمِنُونَ بِبَعۡضِ ٱلۡكِتَٰبِ وَتَكۡفُرُونَ بِبَعۡضٖۚ فَمَا جَزَآءُ مَن يَفۡعَلُ ذَٰلِكَ مِنكُمۡ إِلَّا خِزۡيٞ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يُرَدُّونَ إِلَىٰٓ أَشَدِّ ٱلۡعَذَابِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ 85
Lẹyinnaa ni ẹyin nyapa adehun yii; ni apakan yin npa apakan, ti ẹ si nmu awọn ikọ kan jade ninu yin kuro ninu ile wọn ni ẹni ti nwa iranlọwọ le wọn lori pẹlu awọn ọta niti abosi ati ibanisọta, ti wọn ba waa ni ẹni ti o jẹ ẹru lọwọ awọn ọta, ẹ yoo pada san owo irapada ki ẹ le ba lawọn kuro nibi jijẹ ẹru, pẹlu wipe mimu wọn jade kuro ninu ile wọn jẹ eewọ leyin lori, ki lode, ti ẹ nni igbagbọ pẹlu apakan ohun ti o nbẹ ninu Taoraata nibi jijẹ dandan ira ẹru pada, ti ẹ si nse aimoore pẹlu apakan ohun ti nbẹ nibẹ nibi sisọ ẹjẹ ati kikọ bi apakan yin se nmu apakan jade ninu ile wọn?! Ko si fun ẹniti o ba nse iru nkan yii ninu yin, ẹsan kankan ju iyẹpẹrẹ lọ ati ailasunsi ninu isẹmi aye yii sugbọn ni ọjọ ikẹyin, wọn yoo dari wọn si ibi iya ti o le koko, Ọlọhun ko fọnufọra nipa ohun ti ngbeese nisẹ bikose wipe O nwo gbogbo rẹ, Yoo si san yin lẹsan pẹlu rẹ.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا بِٱلۡأٓخِرَةِۖ فَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ 86
Awọn wọnyi ni awọn ti wọnpaarọ isẹmi aye pẹlu ọrun, ni gbigbe ọla fun ohun ti yoo tan lori ohun ti yoo sẹku, wọn ko nii gbe iya ni fifuyẹ fun wọ ni ọjọ ikẹyin, ko si nii si alaranse fun wọn, ti yoo ran wọn se ni ọjọ naa.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَقَفَّيۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِۦ بِٱلرُّسُلِۖ وَءَاتَيۡنَا عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَيَّدۡنَٰهُ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِۗ أَفَكُلَّمَا جَآءَكُمۡ رَسُولُۢ بِمَا لَا تَهۡوَىٰٓ أَنفُسُكُمُ ٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡ فَفَرِيقٗا كَذَّبۡتُمۡ وَفَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ 87
Paapaa A ti fun Musa ni Taoraata, A si mu awọn ojisẹ kan wa lẹyin rẹ lori oripa rẹ, A si fun Isa ọmọ Maryam ni awọn amin ti o fi oju han, ti o si nsalaye jijẹ ododo rẹ; gẹgẹ bi jiji oku dide, ati wiwo eniti won bi ni afọju san, ati wiwo adẹtẹ san, A si ro ni agbara pẹlu Malaika Jubril (ki ọla maa bẹ fun un) , kee wa se pe gbogbo igbati o ba ti waa ba yin - ẹyin ọmọ Isirẹli - ojisẹ kan lati ọdọ Ọlọhun Ọba pẹlu ounti ko se deede awọn ifẹ inu yin, e ma gbẹru gbọnri lori ododo, ẹ o si gapa lori awọn ojisẹ Allah; awọn apakan ninu wọn npe wọn ni irọ, awọn apakan si npa wọn?!
وَقَالُواْ قُلُوبُنَا غُلۡفُۢۚ بَل لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفۡرِهِمۡ فَقَلِيلٗا مَّا يُؤۡمِنُونَ 88
Paapa, o jẹ awijare awọn Yahuudi nibi aitẹle Muhammad (ki Ọlọhun ko se ikẹ ati igẹ fun un) gbolohun wọn: dajudaju ọkan wa ti ti pa, nkankan ko le sọkalẹ sibẹ ninu nkan ti o nsọ, oo si le gbọye, isesi ko ri bi wọn se lero, bikose wipe Ọlọhun Ọba le wọn jinna kuro nibi ikẹ Rẹ pẹlu sise aimoore wọn, wọn ko si le gbagbọ ayaafi diẹ ninu ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ.
Ninu sise aimoore ti o tobi nii nini igbagbọ pẹlu apakan ohun ti Allah sọkalẹ ati sise aimoore pẹlu apakan rẹ; toripe ẹni ti o nse iru nkan naa, o ti sọ ifẹ inu rẹ di Ọlọhun Ọba rẹ.
Titobi ibi ti awọn Yahuudi de ninu igbẹrugbọnri, ati titẹle ifẹ-inu, ati sise ere pẹlu ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ.
Ọla Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) ati ikẹẹ Rẹ pẹlu awọn ẹda Rẹ, ni aaye ti o ti nmu wa ni tẹlentẹle nipa riran ojisẹ si wọn ati mima sọ awọn tira kalẹ lati le baa fi wọn mọna lọ si ibi onaamọ.
Dajudaju Ọlọhun Ọba Yoo fiya jẹ awọn ti wọn gunri kuro nibi onaamọ, ti wọn si ntako awọn asẹẹ Rẹ pẹlu fifi edidi di ọkan wọn ati gbigbe wọn jinna kuro nibi ikẹ Rẹ, wọn ko nii mọ ọna lọ si ibi ododo, wọn ko si nii fi sisẹ se.