إِنَّا مَكَّنَّا لَهُۥ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَءَاتَيۡنَٰهُ مِن كُلِّ شَيۡءٖ سَبَبٗا 84
A gba a laaye lori ilẹ, a si fun ni gbogbo nkan ti o le so papọ mọ ohun ti nwa ki o le jẹ ọna lati debi erongba rẹ.
فَأَتۡبَعَ سَبَبًا 85
O wa mu ohun ti a fun ninu awọn itẹgun ati awọn oju ọna ki o le debi nkan ti o nwa, o si kọju si ibuwọ oorun.
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ مَغۡرِبَ ٱلشَّمۡسِ وَجَدَهَا تَغۡرُبُ فِي عَيۡنٍ حَمِئَةٖ وَوَجَدَ عِندَهَا قَوۡمٗاۖ قُلۡنَا يَٰذَا ٱلۡقَرۡنَيۡنِ إِمَّآ أَن تُعَذِّبَ وَإِمَّآ أَن تَتَّخِذَ فِيهِمۡ حُسۡنٗا 86
O rin lori ilẹ titi ti o fi de opin rẹ ni abala ibuwọ oorun, - ni riri oju - o ri gẹgẹbi wipe o wọ si omin kan ti o gbona, ti o si ni abata dudu, o wa ri awọn ijọ kan ti wọn jẹ keferi nibi ibuwọ oorun naa, a wa sọ fun ni ojupọnna ki o le sẹsa: irẹ dhul kọrnayn, ninu ki o fi iya jẹ awọn eniyan yii pẹlu pipa tabi nkan miran, tabi ki o si se daadaa si wọn.
قَالَ أَمَّا مَن ظَلَمَ فَسَوۡفَ نُعَذِّبُهُۥ ثُمَّ يُرَدُّ إِلَىٰ رَبِّهِۦ فَيُعَذِّبُهُۥ عَذَابٗا نُّكۡرٗا 87
Dhul-Qarnayn sọpe: ẹniti o ba wo mọ ẹsẹ lẹyin igbati a ti pe e sibi ijọsin Allah, a o pada fi iya pipa jẹ ẹ ni ile aye, lẹyin igba naa yoo sẹri pada lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ni ọjọ igbende, ti yoo fi iya ti o gbona jẹ ẹ.
وَأَمَّا مَنۡ ءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَهُۥ جَزَآءً ٱلۡحُسۡنَىٰۖ وَسَنَقُولُ لَهُۥ مِنۡ أَمۡرِنَا يُسۡرٗا 88
Sugbọn ẹniti o ba nigbagbọ ninu wọn si Allah, ti o si sisẹẹre, Alujannah nbẹ fun un; ni ẹsan lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ lori igbagbọ rẹ ati isẹẹre ti o se, a o wa sọ fun ninu asẹ wa eyiti pẹlẹpẹlẹ ati irọrun nbẹ nibẹ.
ثُمَّ أَتۡبَعَ سَبَبًا 89
Lẹyin igba naa tẹle oju ọna kan, ti o yatọ si oju ọna rẹ alakọkọ ni ẹniti o da oju kọ abala ibuyọ oorun.
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ مَطۡلِعَ ٱلشَّمۡسِ وَجَدَهَا تَطۡلُعُ عَلَىٰ قَوۡمٖ لَّمۡ نَجۡعَل لَّهُم مِّن دُونِهَا سِتۡرٗا 90
O wa nlọ titi ti o fi de ibiti oorun ti nyọ, - ni riri oju - o ri oorun ni ounti nyọ fun awọn ijọ kan, a ko fi ounti o le daabobo wọn kuro nibi oorun naa nibi awọn ile fun wọn ati boji awọn igi.
كَذَٰلِكَۖ وَقَدۡ أَحَطۡنَا بِمَا لَدَيۡهِ خُبۡرٗا 91
Bayi ni alamọri Dhul-Qarnayn paapaa imọ Wa rọkirika alaye agbara ati ọla ti o ni.
ثُمَّ أَتۡبَعَ سَبَبًا 92
Lẹyin naa o tẹle oju ọna kan eyiti o yatọ si oju ọna akọkọ, ti o gunri kuro nibi ibuyọ ati ibuwọ.
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ بَيۡنَ ٱلسَّدَّيۡنِ وَجَدَ مِن دُونِهِمَا قَوۡمٗا لَّا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ قَوۡلٗا 93
O nlọ titi ti o fi de iho kan nibi oke meji, o wa ri ni abala mejeeji awọn ijọ kan ti wọn ko fẹẹ le gbọ ọrọ ara wọn ye.
قَالُواْ يَٰذَا ٱلۡقَرۡنَيۡنِ إِنَّ يَأۡجُوجَ وَمَأۡجُوجَ مُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَهَلۡ نَجۡعَلُ لَكَ خَرۡجًا عَلَىٰٓ أَن تَجۡعَلَ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَهُمۡ سَدّٗا 94
Wọn sọ wipe: irẹ Dul qọrnayn dajudaju yajuuja ati maajuuja (ẹniti wọn gba lero ni ijọ meji ti o tobi ninu awọn ọmọ Aadamọ), wọn jẹ olubilẹjẹ lori ilẹ pẹlu ohun ti wọn nse ni ipaniyan ati ohun ti o yatọ si i, se ki a fun ọ ni owo lori ki o se gaga laarin wa ati awọn naa?
قَالَ مَا مَكَّنِّي فِيهِ رَبِّي خَيۡرٞ فَأَعِينُونِي بِقُوَّةٍ أَجۡعَلۡ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُمۡ رَدۡمًا 95
Dhul-Qarnayn sọpe: ohun ti Ọlọhun mi ran mi se ninu ọla ati agbara loore ju ohun ti ẹyin yoo fun mi ni owo lọ, ki ẹ kun mi lọwọ pẹlu awọn ọkunrin ati awọn irinsẹ, maa se gaga laarin ẹyin ati wọn.
ءَاتُونِي زُبَرَ ٱلۡحَدِيدِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا سَاوَىٰ بَيۡنَ ٱلصَّدَفَيۡنِ قَالَ ٱنفُخُواْۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَعَلَهُۥ نَارٗا قَالَ ءَاتُونِيٓ أُفۡرِغۡ عَلَيۡهِ قِطۡرٗا 96
Ẹ mu egige irin wa, wọn mu wa, wọn waa bẹrẹ sini mọ nkan laarin oke mejeeji titi ti o fi se dọgbandọgba laarin meeji pẹlu ohun ti o mọ, wọn wa sọ fun awọn osisẹ: ẹ da ina si egige irin yii titi irin naa yoo fi pọn, o wa sọ wipe: ẹ oje wa ki nyọ le lori.
فَمَا ٱسۡطَٰعُوٓاْ أَن يَظۡهَرُوهُ وَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ لَهُۥ نَقۡبٗا 97
Yaajuuja ati Maajuuja ko si lagbara nitori giga rẹ, wọn ko si tun nikapa lati da iho lu si isalẹ rẹ nitori lile rẹ.
Dajudaju Dhul-Qarnayn jẹ ikan lara awọn ọlọla olugbagbọ ododo, ti wọn lọla laye, ti wọn si jẹ gaba lori awọn eniyan ibẹ, paapaa julọ Ọlọhun Allah fun ni ọla ti o gbaaye, O si ta lọrẹ ọgbọn ati ọwọ ati imọ ti o se anfaani.
Ninu ojuse ọba tabi adajọ ni ki o mojuto aabo ẹda nibi sisọ awọn ile wọn ati sise atunse ibi ti o ba lu iho nibi dukia wọn.
Awọn ẹniire ti wọn si ni afọmọ ma nse akiyesi lori isaseyọri isẹ nitori wiwa ojuure Ọlọhun Allah.