وَمَا كَانَ جَوَابَ قَوۡمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُوٓاْ أَخۡرِجُوهُم مِّن قَرۡيَتِكُمۡۖ إِنَّهُمۡ أُنَاسٞ يَتَطَهَّرُونَ 82
Ifesi pada awọn ijọ rẹ ti wọn nse ibajẹ lori ohun ti wọn kọ fun wọn ko jẹ nkankan ju wipe wọn nsọrọ ni ẹniti o gunri nibi ododo: ẹ le Luutu ati awọn eniyan rẹ kuro nibi abule yin, wọn jẹ ẹniti om bọpa-bọsẹ kuro nibi isẹ wa yii, ko tọ ki wọn o maa sọ ku ni aarin wa.
فَأَنجَيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ كَانَتۡ مِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ 83
A laa oun ati awọn ara ile rẹ pẹlu wipe a pa wọn lasẹ wipe ki wọn jade ni oru kuro ninu abule ti iya wa ti gbawaju fun, ayaafi iyawo rẹ, o wa ninu ẹniti o sẹku pẹlu awọn ijọ rẹ, ohun ti o sẹlẹ si sẹlẹ sii.
وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِم مَّطَرٗاۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 84
A sọ ojo ti tobi kalẹ le wọn lori, a si tun ju okuta lati inu ẹrọfọ mọ wọn, a wa yi abule naa pada, a sọ oke rẹ di ilẹ, woye - ire ojise - si bi igbẹyin ijọ Luutu ẹlẹsẹ se ri? Igbẹyin wọn jẹ iparun ati idojuti lailai.
وَإِلَىٰ مَدۡيَنَ أَخَاهُمۡ شُعَيۡبٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ قَدۡ جَآءَتۡكُم بَيِّنَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡۖ فَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ وَٱلۡمِيزَانَ وَلَا تَبۡخَسُواْ ٱلنَّاسَ أَشۡيَآءَهُمۡ وَلَا تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ بَعۡدَ إِصۡلَٰحِهَاۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 85
A ran ọmọ iya wọn Suaebu si ijọ Madiyana, o si sọ fun wọn wipe: ẹyin ijọ mi, ẹ sin Ọlọhun Ọba nikan, ko si olujọsin fun yin ti o lẹtọ yatọ siI, awijare ti wa ba yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin ti o fi oju han, ati awijare ti o gbọngbọn lori jijẹ ododo ohun ti mo mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ẹ fun awọn eniyan ni ẹtọ wọn pẹlu pipe osunwọn, ati odiwọn, ẹ ma din ọja awọn eniyan ku lati ara aleebu nini, ati riri aye sa nibẹ, tabi ẹtanjẹ fun awọn eniyan rẹ, ẹ mase ba ilẹ jẹ pẹlu mima se keferi ati dida ẹsẹ lẹyin titun ilẹ se pẹlu gbigbe awọn anọbi dide siwaju, eyiti a sọ yii loore fun yin, o si se anfaani fun yin ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ododo; nitori gbigbe ẹsẹ ju silẹ ati jijinna si ohun ti Ọlọhun Ọba kọ ti o wa nibẹ, ati sisunmọ Ọlọhun Ọba pẹlu sise ohun ti O palasẹ ti o wa nibẹ.
وَلَا تَقۡعُدُواْ بِكُلِّ صِرَٰطٖ تُوعِدُونَ وَتَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ مَنۡ ءَامَنَ بِهِۦ وَتَبۡغُونَهَا عِوَجٗاۚ وَٱذۡكُرُوٓاْ إِذۡ كُنتُمۡ قَلِيلٗا فَكَثَّرَكُمۡۖ وَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُفۡسِدِينَ 86
Ẹ mase wa nibi didẹruba awọn eniyan lati tọ oju ọna naa, ki ẹ le ba ja dukia wọn gba tabi sẹri awọn ti wọn ngbero imọna kuro nibi ẹsin Ọlọhun Ọba ni ẹniti nwa ki oju ọna Ọlọhun Ọba Allah wọgun, ki awọn eniyan ma baa tẹle e, ẹ ranti idẹkun Ọlọhun Ọba le yin lori ki ẹ le ba dupẹ fun Un lori rẹ, onka yin ti jẹ kekere tẹlẹ, O si sọ yin di pupọ, ẹ ronu si igbẹyin awọn olubilẹjẹ lori ilẹ siwaju yin se ri, ti maa ba fi iya jẹ wọn, yoo jẹ ti iparun, ati daru-dapọ.
وَإِن كَانَ طَآئِفَةٞ مِّنكُمۡ ءَامَنُواْ بِٱلَّذِيٓ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦ وَطَآئِفَةٞ لَّمۡ يُؤۡمِنُواْ فَٱصۡبِرُواْ حَتَّىٰ يَحۡكُمَ ٱللَّهُ بَيۡنَنَاۚ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡحَٰكِمِينَ 87
Ti awọn ijọ kan ba nigbagbọ ninu si nkan ti mo mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ti awọn ijọ miran ko si ni igbagbọ sii, - ẹyin opurọ - nkan ti Ọlọhun Ọba yoo fi se idajọ laarin yin, Oun ni ẹniti o loore ju nibi idajọ ati deedee.
Ibara ẹni sun ọkunrin meji jẹ ibajẹ ti ntọka si ohun ti o tako adamọ, o si yẹ ki ijiya ti yoo maa bẹ fun wọn jẹ deedee iran isẹẹ wọn, ni Ọlọhun Ọba fi yi aburu le wọn po.
Ipepe awọn Anọbi Ọlọhun Ọba ma nwa lori –ninu wọn Suaebu- ipilẹ meji: gbigbe asẹ Ọlọhun Ọba tobi: ki o ko fifi mimọ Ọlọhun Ọba lọkan rinlẹ ati gbigba anọbi lododo sinu, ati sise aanu awọn ẹda Ọlọhun Ọba Allah: o si ko gbigbe dindin osunwọn ku ati sise ibajẹ, ati gbogbo iran suta ju silẹ.
Ibajẹ lori ilẹ lẹyin atunse rẹ jẹ ẹsẹ awujọ ninu ẹtọ ọmọniyan; tori wipe titun ilẹ se pẹlu adisọkan ti o dara ati iwa rere jẹ oore fun awujọ, ki eniyan waa se ibajẹ lori ilẹ jẹ igbogunti awọn eniyan.
Ninu awon ẹsẹ ti o tobi ju, ti o si le, ti o si buru ni gbigba ounti ko leto lati gba niti biba ofin mu ni awọn ile isẹ owo niti agidi ati ijẹni nipa; nitoripe ijanilowogba, abosi, ihale mo eniyan, ipolongo fun ibaje, isisetoo, idunnumo ati ifirinle ni o je.