ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَمۡ يَلۡبِسُوٓاْ إِيمَٰنَهُم بِظُلۡمٍ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلۡأَمۡنُ وَهُم مُّهۡتَدُونَ 82
Awọn ti won ni igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn ntẹle ofin Rẹ, ti wọn ko si da igbagbọ wọn pọ mọ ẹbọ, ifọkan balẹ wa fun wọn, alaafia si wa fun awọn nikan yatọ si ẹlomiran, awọn ẹniti o se kongẹ, Ọlọhun Ọba wọn fi wọn mọ oju ọna ti o tọ.
وَتِلۡكَ حُجَّتُنَآ ءَاتَيۡنَٰهَآ إِبۡرَٰهِيمَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦۚ نَرۡفَعُ دَرَجَٰتٖ مَّن نَّشَآءُۗ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٞ 83
Ẹri eleyi ohunn ni gbolohun rẹ ti o sọ wipe: ...فَأَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ أَحَقُّ بِٱلۡأَمۡنِۖ (ewo ni ipin ti o lẹtọ si ifọkanbalẹ ninu awọn mejeeji...) , eyiti Ibrahim fi bori awọn ijọ rẹ, titi ti ko fi si awijare kankan mọ, ohun ni awijare wa, a fi se kongẹ ki o fi ba awọn ijọ rẹ jiyan, a si fi fun un, a ma nse agbega fun awọn ti o ba wu Wa ninu awọn ẹru Wa nibi awọn ipo aye ati ti ọrun, dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ, -ire ojise- ọjọgbọn ni nibi dida Rẹ ati idari Rẹ, onimimọ nipa awọn ẹru Rẹ.
وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۚ كُلًّا هَدَيۡنَاۚ وَنُوحًا هَدَيۡنَا مِن قَبۡلُۖ وَمِن ذُرِّيَّتِهِۦ دَاوُۥدَ وَسُلَيۡمَٰنَ وَأَيُّوبَ وَيُوسُفَ وَمُوسَىٰ وَهَٰرُونَۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 84
A ta Ibrahim lọrẹ ọmọ rẹ Ishaq ati arọmọdọmọ rẹ ya'quub, a si gbogbo wọn se kongẹ oju ọna ti o duro tọ, bẹẹ ni a fi Nuha se kongẹ siwaju ti wọn, a tun fi awọn arọmọdọmọ Nuha naa se kongẹ oju ọna ti o tọ, bii Dawud ati ọmọ rẹ Sulayman ati Hayyub ati Yuusuf ati Muusa ati ọmọ iya rẹ Haruuna ki ikẹ Ọlọhun maa bẹ fun gbogbo wọn, iru apejuwe ẹsan ti a se fun awọn Anọbi yii lori daadaa wọn ti wọn se, ohun naa ni a o maa fi san ẹsan fun awọn oluse daadaa ti wọn yatọ si wọn lori daadaa ti awọn naa se.
وَزَكَرِيَّا وَيَحۡيَىٰ وَعِيسَىٰ وَإِلۡيَاسَۖ كُلّٞ مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 85
Bẹẹ naa ni a fi Zakariyyah ati yahya ati Isa ọmọ Maryam ati Iliyasu (ki ikẹ ati ọla maa bẹ fun gbogbo wọn) se kongẹ, gbogbo awọn Anọbi yii ni wọn jẹ ẹniire, Ọlọhun Ọba Allah sa wọn lẹsa gẹgẹ bi ojisẹ.
وَإِسۡمَٰعِيلَ وَٱلۡيَسَعَ وَيُونُسَ وَلُوطٗاۚ وَكُلّٗا فَضَّلۡنَا عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ 86
Bakanna ni a fi Ismaheel ati Al-yasa’u ati yuunus ati Luutu ki ikẹ ati ọla maa bẹ fun gbogbo wọn se kongẹ, gbogbo awọn Anọbi yii titi ti o fi de ọdọ olori wọn tii se Anọbi Muhammad ki ikẹ ati ọla maa bẹ fun, a gbe ọla fun gbogbo wọn lori agbanla aye.
وَمِنۡ ءَابَآئِهِمۡ وَذُرِّيَّٰتِهِمۡ وَإِخۡوَٰنِهِمۡۖ وَٱجۡتَبَيۡنَٰهُمۡ وَهَدَيۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 87
A fi apakan ninu awọn baba wọn ati apakan ninu awọn ọmọ wọn ati apakan ninu awọn ọmọ iya wọn ninu awọn ti o wu Wa se kongẹ, a sa wọn lẹsa, bẹẹ ni a fi wọn se kongẹ oju ọna ti o duro tọ, eyi tii se oju ọna mimu Ọlọhun Ọba Allah ni ọkan soso ati titẹle asẹ Rẹ.
ذَٰلِكَ هُدَى ٱللَّهِ يَهۡدِي بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۚ وَلَوۡ أَشۡرَكُواْ لَحَبِطَ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 88
Kongẹ eyiti o sẹlẹ si wọn yii jẹ kongẹ ti Ọlọhun Ọba Allah, ti O ma nse fun ẹniti o ba wu U ninu ẹru Rẹ, ti wọn ba mu nkan miran mọ Ọlọhun Ọba Allah, isẹ wọn ki ba bajẹ; nitori wipe isẹ ma nba isẹ rere jẹ.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحُكۡمَ وَٱلنُّبُوَّةَۚ فَإِن يَكۡفُرۡ بِهَا هَٰٓؤُلَآءِ فَقَدۡ وَكَّلۡنَا بِهَا قَوۡمٗا لَّيۡسُواْ بِهَا بِكَٰفِرِينَ 89
Awọn Anọbi ti a daru yii ni awọn ti a fun ni tira, a si tun fun wọn ni ọgbọn, bẹẹ ni a fun wọn ni ijanọbi, ti awọn ijọ rẹ ba se aimoore pẹlu nkan ti a fun wọn ninu awọn nkan mẹta wọnyi, paapaa a ti pese silẹ fun wọn, bakanna ni a tọju ijọ miran ti wọn ko nii se keferi sii, awọn ni awọn olugbagbọ ti wọn yoo gbaa mu daradara, awọn si ni oluse irin ajo, ati awọn alaranse, ati awọn ti o tẹle wọn pẹlu daadaa titi di ọjọ ẹsan.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ هَدَى ٱللَّهُۖ فَبِهُدَىٰهُمُ ٱقۡتَدِهۡۗ قُل لَّآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًاۖ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرَىٰ لِلۡعَٰلَمِينَ 90
Awọn ni awọn Anọbi, awọn ti a darukọ pẹlu wọn gẹgẹ bi awọn baba wọn ati awọn ọmọ wọn ati awọn ọmọ iya wọn, awọn ni ẹni imọna tootọ, ẹ tẹle wọn, ki ẹ si kọse wọn, ki o wa sọ fun -ire ojise- awọn ijọ rẹ: emi ko wa ẹsan kankan ni ọdọ yin lori mimu Alukuraani de ogongo, Alukuraani kii se nkankan ju isiti fun gbogbo agbanla aye lọ, ninu awọn eniyan ati alujannu, ki wọn le gba itọsọna lọ si oju ọna ti o duro tọ, ati oju ọna ti o ni alaafia.
Ninu awọn ọla ti nẹb fun mimọ Ọlọhun Ọba Allah lọkan soso ni wipe ifọkan balẹ pamọ sinu rẹ fun ẹru, paapaa julọ ni ọrun nigbati awọn eniyan ba npaya.
Awọn aayah naa nfi rinlẹ wipe gbogbo anọbi ti wọn ti re kọja lọ, ri imude ogongo ipepe se lati ara kongẹ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ti kii se pẹlu agbara wọn.
Awọn Anọbi Ọlọhun papọ nibi ipepe si ijọkan soso Allah, ti wọn si yatọ nibi awon ifosiwewe ofin ijọsin.
Kikọse awọn Anọbi Ọlọhun jẹ ikọse ẹyin paapaa julọ nibi ipilẹ ọkan soso Ọlọhun Ọba Allah.