فَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا جَعَلۡنَا عَٰلِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهَا حِجَارَةٗ مِّن سِجِّيلٖ مَّنضُودٖ 82
Nigbati asẹ wa de lori pipa ijọ Luth run, a sọ oke ilu naa di isalẹ rẹ pẹlu gbigbe soke ati yiyiipo, a si rọ ojo okuta lati inu Tiini le wọn lori, ti o le ni leralera, ti apakan wọn ju apakan lọ ni leralera.
مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَۖ وَمَا هِيَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ بِبَعِيدٖ 83
Okuta yii jẹ ohun ti o ni amin pẹlu amin adayanri, okuta yii ki se ohun ti o jinna si awọn alabosi kuraysi ati ẹniti o yatọ si wọn bikose wipe o jẹ ohun ti o sun mọ nigba kiigba ti Ọlọhun Ọba ba kadara sisọkalẹ rẹ le wọn lori.
۞وَإِلَىٰ مَدۡيَنَ أَخَاهُمۡ شُعَيۡبٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ وَلَا تَنقُصُواْ ٱلۡمِكۡيَالَ وَٱلۡمِيزَانَۖ إِنِّيٓ أَرَىٰكُم بِخَيۡرٖ وَإِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٖ مُّحِيطٖ 84
A si ran ọmọ iya wọn Shu'aibu si ilẹ Madiyanọ, o wa sọ wipe: ẹyin ijọ mi, ẹ ma sin Allah nikan soso, ko si fun yin olujọsin ti o lẹtọ si ijọsin yatọ si I, ki ẹ ma si se din osunwọn ati ondinwọn ku nigbati ẹ ba nwọn fun awọn eniyan, tabi ẹ nse ondinwọn rẹ fun wọn, dajudaju mo ri yin ninu arisiki ti o gbaaye ati idẹkun, ẹ mase jẹ ki idẹkun Allah yi pada latara ẹsẹ, dajudaju emi npaya iya ọjọ ti yoo kari leyin lori, ti yoo si ba ẹnikọọkan yin, ti ẹ ko ni ri ibusalọ tabi ibusẹri si kuro nibẹ.
وَيَٰقَوۡمِ أَوۡفُواْ ٱلۡمِكۡيَالَ وَٱلۡمِيزَانَ بِٱلۡقِسۡطِۖ وَلَا تَبۡخَسُواْ ٱلنَّاسَ أَشۡيَآءَهُمۡ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ 85
Ẹyin ijọ mi, ẹ maa pe osunwọn ati ondinwọn pẹlu deedee nigbati ẹ ba nse ondinwọn tabi se osunwọn fun ẹlomiran, ẹ mase din osunwọn ku fun awọn eniyan nibi ẹtọ wọn kankan pẹlu dindin ku tabi sise abosi tabi dida ete, ẹ mase ba iilẹ jẹ pẹlu pipa eniyan ati nkan miran ti o yatọ si ninu ẹsẹ.
بَقِيَّتُ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَۚ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِحَفِيظٖ 86
Nkan ti Ọlọhun sẹku fun yin ninu ẹtọ lẹyin pipe ẹtọ awọn eniyan niti deedee, o ni anfaani ti o pọ ati ibukun ju alekun ti ẹ ri latara dindin osunwọn ku ati biba ilẹ jẹ lọ, ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ododo tootọ, ki ẹ yaa yọnu si ondinwọn ti o sẹku naa, emi kii se olusọ fun yin ti yoo maa yẹ isẹ yin wo tabi ti yoo maa se isiro yin, ẹniti o jẹ alamojuto eleyi ni ẹniti o mọ kọkọ ati ọrọ kẹlẹkẹlẹ.
قَالُواْ يَٰشُعَيۡبُ أَصَلَوٰتُكَ تَأۡمُرُكَ أَن نَّتۡرُكَ مَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَآ أَوۡ أَن نَّفۡعَلَ فِيٓ أَمۡوَٰلِنَا مَا نَشَٰٓؤُاْۖ إِنَّكَ لَأَنتَ ٱلۡحَلِيمُ ٱلرَّشِيدُ 87
Awọn ijọ Shu'aibu sọ fun Shu'aibu: irẹ Shu'aibu, se irun rẹ ti o nki fun Allah ni o pa ọ lasẹ pe ki a gbe ijọsin ti awọn baba wa ti nse ju silẹ gẹgẹ bi ẹbọ, ti o tun wa pa ọ lasẹ ki a ma le se bi o ti wuwa lori awọn dukia wa ati ki a mu idagbasoke ba bi o ti wu wa?! Dajudaju alatẹmọra, olutọnisọna ni iwọọ se, dajudaju onilaakaye ọlọgbọn gẹgẹ bi a se mọ ọ siwaju ipepe yi ni iwọ se, kinni eyiti o wa sẹlẹ si ọ bayi?!
قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَرَزَقَنِي مِنۡهُ رِزۡقًا حَسَنٗاۚ وَمَآ أُرِيدُ أَنۡ أُخَالِفَكُمۡ إِلَىٰ مَآ أَنۡهَىٰكُمۡ عَنۡهُۚ إِنۡ أُرِيدُ إِلَّا ٱلۡإِصۡلَٰحَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُۚ وَمَا تَوۡفِيقِيٓ إِلَّا بِٱللَّهِۚ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ 88
Shu'aibu sọ fun awọn ijọ rẹ, ẹyin ijọ mi, ẹ fun ni iro nipa isesi yin ti ẹ ba wa lori awijare ti o fi oju han lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ati ẹri lati ọdọ Rẹ, o si ran mki se ni aranse ẹtọ lati ọdọ Rẹ ninu rẹ ni jijẹ anọbi, ẹmi ko gbero lati kọ fun yin kuro nibi ohun kihun ki nsi yapa yin nibi sise e, emi ko gbero nkankan ju atunse yin lọ pẹlu pipe sibi ijọkan soso Ọlọhun Ọba yin ati titẹle ni odiwọn ikapa mi, ko si si ẹniti o le fi mi se kongẹ eleyi ju Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun lọ, Oun nikan ni mo gbarale nibi gbogbo alamọri mi, ọdọ Rẹ ni mo si sẹri si.
Ninu isesi Allah ni mimu iparun ba awọn alabosi pẹlu awọn iya ti o le koko ati eyiti o buru ju.
Sise dindin osunwọn ati ondinwọn ku leewọ ati sise janba ẹtọ awọn eniyan.
Jijẹ dandan yiyọnu si ẹtọ koda bi o kere.
Ọla ti nbẹ fun pipasẹ daadaa ati kikọ kuro nibi ohun ti ko dara ati jijẹ dandan sise ohun ti Ọlọhun Ọba Allah pa lasẹ ati jijawọ kuro nibi nkan ti O kọ.