مَّن يُطِعِ ٱلرَّسُولَ فَقَدۡ أَطَاعَ ٱللَّهَۖ وَمَن تَوَلَّىٰ فَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ حَفِيظٗا 80
Ẹniti o ba tẹle ojisẹ naa pẹlu sise ohun ti o pasẹ rẹ, ati jijina si nkan ti o kọ, o ti jẹpe asẹ Ọlọhun Ọba Allah, ẹniti o ba gunri kuro nibi titẹle ọ - ire ojise - ma banu jẹ le lori, a ko ran ọ ni olusọ le lori, ki o maa sọ isẹ rẹ, dajudaju Awa ni A ansọ isẹrẹ, ti A o si se isiro rẹ.
وَيَقُولُونَ طَاعَةٞ فَإِذَا بَرَزُواْ مِنۡ عِندِكَ بَيَّتَ طَآئِفَةٞ مِّنۡهُمۡ غَيۡرَ ٱلَّذِي تَقُولُۖ وَٱللَّهُ يَكۡتُبُ مَا يُبَيِّتُونَۖ فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلًا 81
Awọn sọbẹselu nsọ fun ọ pẹlu ahọn wọn: a ntẹle asẹ rẹ, a si nsee, ti wọn ba jade kuro ni ọdọ rẹ, awọn ijọ kan ninu wọn, ni kọkọ wọn yoo se ohun ti o yapa si ohun ti wọn se afihan si ọ, Ọlọhun Ọba Allah si mọ nkan ti wọn gba lero, Yoo si san wọn lẹsan lori ete wọn yii, mase gboju wo ọdọ wọn; wọn ko le ko inira kankan ba ọ, fi ọrọ rẹ ti si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ki o si gbe ara leE, Ọlọhun Ọba Allah to ni olugbarale, ti o le gbara le.
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ ٱلۡقُرۡءَانَۚ وَلَوۡ كَانَ مِنۡ عِندِ غَيۡرِ ٱللَّهِ لَوَجَدُواْ فِيهِ ٱخۡتِلَٰفٗا كَثِيرٗا 82
Kinni o de ti awọn wọnyi ko le ronu si Alukuraani, ki wọn si gbe yẹwo daradara, titi yoo fi rinlẹ fun wọn wipe ko si iyapa tabi iforigbari kankan nibẹ? ! Titi wọn yoo fi mọ ododo nkan ti o mu wa, ti o ba ja si wipe o wa lati ọdọ ẹlomiran ti o yatọ si Allah ti ọla Rẹ ga, wọn ko ba ri iforigbari nibi awọn idajọ rẹ, ati iyapa ti o pọ nibi awọn itumọ rẹ.
وَإِذَا جَآءَهُمۡ أَمۡرٞ مِّنَ ٱلۡأَمۡنِ أَوِ ٱلۡخَوۡفِ أَذَاعُواْ بِهِۦۖ وَلَوۡ رَدُّوهُ إِلَى ٱلرَّسُولِ وَإِلَىٰٓ أُوْلِي ٱلۡأَمۡرِ مِنۡهُمۡ لَعَلِمَهُ ٱلَّذِينَ يَسۡتَنۢبِطُونَهُۥ مِنۡهُمۡۗ وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ لَٱتَّبَعۡتُمُ ٱلشَّيۡطَٰنَ إِلَّا قَلِيلٗا 83
Nigbati alamọri kan ba waa ba awọn sọbẹselo yii, ninu oun ti o jẹ ifọkanbalẹ fun awọn olugbagbọ ododo ati idunnu fun wọn, tabi ipaya fun wọn, tabi ibanujẹ fun wọn; wọn yoo da silẹ, wọn yoo si fan ka, ti wọn ba seri ọrọ lọ si ọdọ ojisẹ naa ni, ati si ọdọ awọn ọlọgbọn, ati onimimọ ati alatunse; awọn ọlọgbọn ati imujade ki ba mọ nkan ti o yẹ ki wọn o se isẹ le lori ninu fifanka tabi pipamọ rẹ, ti kii baa se ọla Ọlọhun Ọba Allah le yin lori pẹlu Islam, ati ikẹ Rẹ si yin pẹlu Alukuraani - ẹyin olugbagbọ ododo - ti O fun yin ni alaafia kuro nibi oun ti o fi se adanwo fun awọn sọbẹselo; ẹ ko ba tẹle roiroi esu ayaafi diẹ ninu yin.
فَقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا تُكَلَّفُ إِلَّا نَفۡسَكَۚ وَحَرِّضِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَكُفَّ بَأۡسَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ وَٱللَّهُ أَشَدُّ بَأۡسٗا وَأَشَدُّ تَنكِيلٗا 84
Maa jagun - ire ojise - si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah nitori gbigbe gbolohun Rẹ ga, mase beere nipa ẹniti o yatọ si ọ, mase ni dandan fun un, toripe ohun ti a la bọ ọ lọrun, ko ju nkan ti ẹmin rẹ le fi jagun lọ, maa se awọn olugbagbọ ododo loju kokoro lọ si ibi ijagun, ki o si ta wọn ji sii, o sun mọ ki Ọlọhun Ọba Allah da aabo bo yin kuro nibi agbara awọn keferi pẹlu jijagun yin, Ọlọhun Ọba Allah ni o lagbara ju, Oun ni iya Rẹ si le ju.
مَّن يَشۡفَعۡ شَفَٰعَةً حَسَنَةٗ يَكُن لَّهُۥ نَصِيبٞ مِّنۡهَاۖ وَمَن يَشۡفَعۡ شَفَٰعَةٗ سَيِّئَةٗ يَكُن لَّهُۥ كِفۡلٞ مِّنۡهَاۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ مُّقِيتٗا 85
Ẹniti o ba nsapa lati fa daradara fun ẹnikeji; yoo ni ipin ninu ẹsan naa, bẹẹni ẹniti o ba fa aburu fun ẹnikeji; yoo ni ipin ninu ẹsẹ naa, Ọlọhun Ọba Allah jẹ olujẹri lori gbogbo ohun ti ọmọ ẹda eniyan nse, yoo si san wọn ni ẹsan le lori. ẹniti o ba jẹ okunfa ninu si ibi daradara, ipin o nbẹ fun un, ẹniti o ba jẹ okunfa nibi sise aburu, nkankan yoo bẹ fun ninu rẹ.
وَإِذَا حُيِّيتُم بِتَحِيَّةٖ فَحَيُّواْ بِأَحۡسَنَ مِنۡهَآ أَوۡ رُدُّوهَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَسِيبًا 86
Ti ẹnikan ba salamọ si yin, ki ẹ yara da salamọ pada pẹlu eyiti o lọla ju salamọ ti o se fun yin lọ, tabi ki o da pada ni deede ohun ti o sọ, ki o daa pada pẹlu eyiti o dara julọ, ohun ni o lọla, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ olusọ lori gbogbo nkan ti ẹ nse, yoo si san ẹnikọọkan pẹlu isẹ rẹ.
Ironu nipa Alukuraanu Alapọnle yoo jogun amọdaju wipe isọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni o jẹ; nitori lila rẹ kuro nibi iforigbari, yoo si se afihan titobi awọn idajọ ti o ko sinu.
Ko tọ fifan awọn iro eyiti yoo da ipaya si ifọkanbalẹ awọn olugbagbọ ododo, tabi yoo fan ipaya si awujọ wọn.
Sisọrọ nipa awọn alamọri ọrọ awọn olugbagbọ ododo ati awọn alamọri ti o ka ri eyiti o so pọ mọ wọn, dandan ni ki o jẹ wipe ọdọ awọn onimimọ ati alasẹ wọn ni yoo ti maa jade.
Sise lofin ipẹ ti o dara, eyiti ko si ẹsẹ nibẹ, ti ko si kọja ẹnu aala ẹtọ ọmọniyan, ati sise leewọ gbogbo ipẹ eyiti ẹsẹ wa nibẹ tabi ikọja ẹnu aala.