وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۢ بُيُوتِكُمۡ سَكَنٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ بُيُوتٗا تَسۡتَخِفُّونَهَا يَوۡمَ ظَعۡنِكُمۡ وَيَوۡمَ إِقَامَتِكُمۡ وَمِنۡ أَصۡوَافِهَا وَأَوۡبَارِهَا وَأَشۡعَارِهَآ أَثَٰثٗا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ 80
Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun se yin ninu ile yin eyiti nkọ lati ibi okuta ati nkan miran eyiti o rinlẹ, ti o si jẹ isimin, O si tun se atibaba ati orule ninu oko gẹgẹ bi ile ọlaju lati ibi awọ rakunmi, maalu, agutan, ti gbigbe rẹ rọrun fun yin nibi irin ajo yin lati aaye kan si aaye miran, ti o si rọrun titẹ ẹ silẹ ni aaye ti ẹ ba sọkalẹ si, O si se awọn ọsọ ile ati awọn asọ ati awọn nkan idabora, ti ẹyin yoo maa fi se anfaani di awọn asiko kan pato fun yin lati ara awọn irun agutan ati irun rakunmi ati awọn irun agbo.
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّمَّا خَلَقَ ظِلَٰلٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡجِبَالِ أَكۡنَٰنٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ سَرَٰبِيلَ تَقِيكُمُ ٱلۡحَرَّ وَسَرَٰبِيلَ تَقِيكُم بَأۡسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُسۡلِمُونَ 81
Ọlọhun Ọba Allah tun se ohun ti ẹ o maa fi se idaabobo ara ni igba ooru fun yin lati ibi igi ati awọn ile, O si tun se anpeena ati awọn ọgbun ati awọn iho ti ẹ nbo asiri ara yin nibi otutu ati oorun ati ọta fun yin nibi oke, O si tun se ẹwu ati asọ lati inu owu ati nkan miran fun yin ti ẹ ndabobo ara yin kuro nibi ooru ati otutu, O si tun se ẹwu irin ti o ndaabobo yin kuro nibi apakan yin nibi ogun fun yin, ti nkan ija ogun ko fi le de ara yin, gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba Allah se se idẹkun fun yin ninu awọn idẹkun ti o siwaju, O npe idẹkun rẹ le yin lori ni ireti ki ẹ le ba tẹriba fun Un ni Oun nikan soso, ki ẹ si ma mu nkan miran pẹlu Rẹ.
فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا عَلَيۡكَ ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ 82
Ti wọn ba gunri nibi igbagbọ ati gbigba ohun ti o mu wa lododo, ko jẹ dandan fun ọ - irẹ ojisẹ - ju ki o mu de ogongo nkan ti wọn pa ọ lasẹ ki o mu dopin rẹ lọ ni imudopin ti o fi oju han, kii se dandan fun ọ ki o gbe wọn lọ si ibi imọna.
يَعۡرِفُونَ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُنكِرُونَهَا وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ 83
Awọn ẹlẹbọ mọ idẹkun Allah eyiti O se le wọn lori ninu rẹ si ni riran Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun si wọn, wọn ko jiyan idẹkun Rẹ pẹlu aidupẹ naa ati pipe ojisẹ naa nirọ sugbọn ọpọlọpọ wọn jẹ oluja idẹkun Rẹ ti mimọ nbẹ fun niyan.
وَيَوۡمَ نَبۡعَثُ مِن كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدٗا ثُمَّ لَا يُؤۡذَنُ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ 84
Ranti - irẹ ojisẹ - ọjọ ti Allah yoo gbe ojisẹ dide ninu ijọ eyiti o ransẹ si, ti yoo maa jẹri lori olugbagbọ ododo ninu wọn ati oluse keferi, lẹyin igba naa, ko nii yọnda fun keferi wiwi awijare lori keferi rẹ, wọn ko si nii le sẹri lọsi ile aye lati le se nkan ti yoo yọ Ọlọhun Ọba wọn ninu, ọrun jẹ ile isiro kii se ile isẹ.
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلۡعَذَابَ فَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ 85
Nigbati awọn alabosi, ẹlẹbọ ba fi oju kan iya, wọn koo nii se ni fifuyẹ fun wọn, wọn ko si nii dẹ wọn lẹkẹ ki wọn le lọ lara fun wọn, bikosepe wọn yoo wọ ibẹ ni wiwa gbere nibẹ.
وَإِذَا رَءَا ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ شُرَكَآءَهُمۡ قَالُواْ رَبَّنَا هَٰٓؤُلَآءِ شُرَكَآؤُنَا ٱلَّذِينَ كُنَّا نَدۡعُواْ مِن دُونِكَۖ فَأَلۡقَوۡاْ إِلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلَ إِنَّكُمۡ لَكَٰذِبُونَ 86
Nigbati awọn ẹlẹbọ ba fi oju kan ẹniti wọn nsin ni ọrun eyiti wọn nsin yatọ si Allah, wọn yoo sọpe: Ọlọhun wa, awọn wọnyi ni akẹgbẹ wa eyiti a nsin yatọ si Ọ, wọn yoo sọ eleyi ki wọn le gbe ẹsẹ wọn le wọn lori, Ọlọhun Allah yoo waa fun awọn ti wọn nsin ni ọrọ sọ, ti wọn yoo si fọ esi pada fun wọn: dajudaju ẹyin - ẹyin ẹlẹbọ - jẹ olupurọ nibi sinsin nkan miran mọ Allah, ko si orogun fun Un ti o yẹ ki wọn sin.
وَأَلۡقَوۡاْ إِلَى ٱللَّهِ يَوۡمَئِذٍ ٱلسَّلَمَۖ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ 87
Awọn ẹlẹbọ yoo jupa jusẹ silẹ, wọn yoo si tẹriba fun Allah nikan soso, adapa irọ lori wipe awọn oosa yoo sipẹ fun wọn ni ọdọ Allah, yoo poora fun wọn.
Awọn aayah naa tọka lori titọ sise anfaani pẹlu irun maalu ati irun rakunmi ati irun agutan ni gbogbo ọna, ninu rẹ si ni lilo o fun ile ati nkan elo inu ile.
Pipọ idẹkun wa ninu awọn okunfa ti o ma nmu ki alekun ọpẹ wa fun ẹru ati sise ẹyin lati ara rẹ fun Allah ti O ga.
Olujẹri eyiti yoo jẹri lori gbogbo ijọ, Ohun ni ẹlẹri ti o mọ ju, ti o si ni deede ju, awọn ni awọn ojisẹ ti o ja si wipe ti wọn ba jẹri, idajọ ti pe le wọn lori.
Nibi gbolohun Rẹ ti O ga julọ: (وَسَرَٰبِيلَ تَقِيكُم بَأۡسَكُمۡۚ) (ati asọ owu rakunmi, ti o ndaabobo yin nibi suta yin) jẹ ẹri lori ki ẹru mu esenpa igbiyanju; ki wọn le fi se ikunlọwọ lori biba ọta ja.