يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ تُوبُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ تَوۡبَةٗ نَّصُوحًا عَسَىٰ رَبُّكُمۡ أَن يُكَفِّرَ عَنكُمۡ سَئَِّاتِكُمۡ وَيُدۡخِلَكُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ يَوۡمَ لَا يُخۡزِي ٱللَّهُ ٱلنَّبِيَّ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥۖ نُورُهُمۡ يَسۡعَىٰ بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَبِأَيۡمَٰنِهِمۡ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَتۡمِمۡ لَنَا نُورَنَا وَٱغۡفِرۡ لَنَآۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 8
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se se ohun ti wọn se lofin fun wọn, ẹ ronu piwada lọsi ọdọ Allah kuro nibi awọn ẹsẹ yin ni ironu piwada tootọ, o seese ki Ọlọhun yin pa awọn asise yin rẹ fun yin, ki o si fi yin wọ awọn ọgba idẹra, ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ni ọjọ igbende, ni ọjọ ti Allah ko nii mu iyẹpẹrẹ ba anọbi, ko si nii yẹpẹrẹ awọn ti o nigbagbọ pẹlu Rẹ nipa fifi wọn wọ si ina, imọlẹ wọn yoo maa bẹ ni iwaju wọn ati ni ẹgbẹ ọtun wọn ni ori afara naa, wọn yoo maa sọpe: irẹ Ọlọhun wa, pe imọlẹ wa fun wa, ti a o fi wọ ọgba idẹra naa, ti a ko fi nii da gẹgẹ bi awọn sọbẹ selu, awọn ti imọlẹ wọn yoo ku ni ori afara naa, ki o si fi ori awọn ẹsẹ wa jin wa, dajudaju iwọ jẹ alagbara lori gbogbo nkan, ki o mọ se kagara nipa pipe imọlẹ wa ati sise amojukuro awọn ẹsẹ wa naa.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ جَٰهِدِ ٱلۡكُفَّارَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱغۡلُظۡ عَلَيۡهِمۡۚ وَمَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ 9
ire ojise, ja awọn keferi niyan pẹlu ida ati awọn sọbẹ selu pẹlu ahọn ati fifi aala lelẹ, ki o si le mọ wọn titi wọn yoo fi maa bẹru rẹ, ibudarisi wọn eyiti wọn yoo sẹri si ni ọjọ igbende ni ina jahannamọ, ibusẹri wọn eyiti wọn yoo sẹri si si buru ni ibusẹri si.
ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱمۡرَأَتَ نُوحٖ وَٱمۡرَأَتَ لُوطٖۖ كَانَتَا تَحۡتَ عَبۡدَيۡنِ مِنۡ عِبَادِنَا صَٰلِحَيۡنِ فَخَانَتَاهُمَا فَلَمۡ يُغۡنِيَا عَنۡهُمَا مِنَ ٱللَّهِ شَيۡٔٗا وَقِيلَ ٱدۡخُلَا ٱلنَّارَ مَعَ ٱلدَّٰخِلِينَ 10
Allah fi apejuwe lile fun awọn ti wọn se keferi si Allah ati si ojisẹ Rẹ - wipe dajudaju asopọ wọn pẹlu awọn olugbagbọ ododo ko le se anfaani ni ọna kankan - awọn obinrin meji anọbi meji kan ninu awọn anọbi Allah: Nuhu ati Luuth ki ọla Allah maa bẹ fun awọn mejeeji, paapaa awọn mejeeji jẹ iyawo meji fun ẹru rere meji kan, awọn mejeeji si jamba ọkọ wọn; nipa ikọdi kuro ni oju ọna Allah ati ise aranse fun awọn ẹni keferi ninu ijọ wọn ti wọn wa lori rẹ, jijẹ iyawo meji fun awọn ẹru rere meji naa ko se wọn ni anfaani, wọn si sọ fun awọn mejeeji: ẹyin mejeeji ẹ wọ ina naa ni awujọ awọn ti o nwọ ọ ninu awọn keferi ati awọn pokii.
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱمۡرَأَتَ فِرۡعَوۡنَ إِذۡ قَالَتۡ رَبِّ ٱبۡنِ لِي عِندَكَ بَيۡتٗا فِي ٱلۡجَنَّةِ وَنَجِّنِي مِن فِرۡعَوۡنَ وَعَمَلِهِۦ وَنَجِّنِي مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ 11
Allah si tun fi apejuwe lelẹ fun awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ati si awọn ojisẹ Rẹ wipe dajudaju asopọ wọn pẹlu awọn keferi ko le ko inira ba wọn, ko si le lapa lara wọn niwọnba igba ti wọn ba duro deedee lori ododo nipa obinrin fir'aona nigbati o sọ wipe: irẹ Ọlọhun mi, mọ ile kan fun mi ni ọdọ Rẹ ni ọgba idẹra, ki o si la mi kuro nibi agbara fir'aona ati ijọba rẹ ati kuro nibi awọn isẹ aburu rẹ, ki O si tun la mi kuro lọdọ awọn ijọ alabosi fun ẹmin ara wọn nipa titẹle wọn fun un nibi ikọja ẹnu aala rẹ ati abosi rẹ.
وَمَرۡيَمَ ٱبۡنَتَ عِمۡرَٰنَ ٱلَّتِيٓ أَحۡصَنَتۡ فَرۡجَهَا فَنَفَخۡنَا فِيهِ مِن رُّوحِنَا وَصَدَّقَتۡ بِكَلِمَٰتِ رَبِّهَا وَكُتُبِهِۦ وَكَانَتۡ مِنَ ٱلۡقَٰنِتِينَ 12
Allah si tun fi apejuwe lelẹ fun awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ati awọn ojisẹ Rẹ nipa isesi Maryam ọmọbinrin Imran eyiti o sọ abẹ rẹ kuro nibi agbere, Allah si pa Jibril lasẹ ki o fẹ atẹgun si i, o si loyun Isa ọmọ Maryam ni aini baba pẹlu agbara Allah, o si gba awọn ofin Allah lododo ati awọn iwe Rẹ ti o sọkalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, o si wa ninu awọn olutẹle ti Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati kikuraro kuro nibi awọn ohun ti O kọ.
Ironu piwada ti o mọ jẹ okunfa gbogbo rere.
Nibi dida igbiyanju imọ ati awijare pọ mọ igbiyanju ida jẹ itọka lori pipataki mejeeji atipe dajudaju ko si irọrọ kuro nibi ikan ninu wọn.
Isunmọ nitori idi tabi iran ko le se anfaani fun ẹni rẹ ni ọjọ igbende nigbati ẹsin ba pin ya laarin awọn mejeeji.
Ikoraro ati ijina si iye meji wa ninu awọn iroyin awọn olugbagbọ ododo rere.