رَبَّنَا وَأَدۡخِلۡهُمۡ جَنَّٰتِ عَدۡنٍ ٱلَّتِي وَعَدتَّهُمۡ وَمَن صَلَحَ مِنۡ ءَابَآئِهِمۡ وَأَزۡوَٰجِهِمۡ وَذُرِّيَّٰتِهِمۡۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 8
Awọn Malaaika yoo sọ wipe: Ọlọhun wa, fi awọn olugbagbọ ododo wọ inu ọgba idẹra gbere eyiti o se ni adehun fun wọn wipe iwọ yoo ki wọn wọ, si mu wọ ibẹ pẹlu wọn ẹniti isẹ rẹ ba dara ninu awọn baba wọn ati awọn iyawo wọn ati awọn ọmọ wọn, dajudaju iwọ ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi ipebubu Rẹ ati idari Rẹ.
وَقِهِمُ ٱلسَّئَِّاتِۚ وَمَن تَقِ ٱلسَّئَِّاتِ يَوۡمَئِذٖ فَقَدۡ رَحِمۡتَهُۥۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 9
Ki o si sọ wọn nibi aburu isẹ wọn, mase fi iya jẹ wọn le lori, ẹniti O ba daabobo ni ọjọọ igbende nibi iya naa lori awọn aburu isẹẹrẹ, paapaa O ti kẹ ẹ, idaabobo kuro nibi iya yii ati ikẹ wiwọ ọgba idẹra; jẹ erenjẹ ti o tobi, ti erenjẹ kankan ko sun mọ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُنَادَوۡنَ لَمَقۡتُ ٱللَّهِ أَكۡبَرُ مِن مَّقۡتِكُمۡ أَنفُسَكُمۡ إِذۡ تُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلۡإِيمَٰنِ فَتَكۡفُرُونَ 10
Dajudaju awọn ti o se aimoore si Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, wọn yoo pe wọn ni ọjọ igbende nigbati wọn ba nwọ inu ina, ti wọn si nbinu si ara wọn, wọn yoo si maa sẹbi le wọn: paapaa lilekoko ikorira Allah si yin tobiju biburu ikorira apakan yin si apakan lọ nigbati wọn pe yin ni ile aye sibi inigbagbọ ninu Allah sugbọn ẹ se aimoore si I, ẹ si tun mu Ọlọhun miran pẹlu Rẹ.
قَالُواْ رَبَّنَآ أَمَتَّنَا ٱثۡنَتَيۡنِ وَأَحۡيَيۡتَنَا ٱثۡنَتَيۡنِ فَٱعۡتَرَفۡنَا بِذُنُوبِنَا فَهَلۡ إِلَىٰ خُرُوجٖ مِّن سَبِيلٖ 11
Awọn keferi sọrọ ni ẹniti o nfi awọn ẹsẹ wọn rinlẹ nigbati ifirinlẹ wọn tabi ironu piwada wọn ko le se anfaani: Ọlọhun wa, o pa wa ni igba meji ni igbati a wa ni aisi, o si mu wa jade sugbọn O tun pa wa lẹyin imujade yii, O si ta wa ji ni igba meji pẹlu mimu wa jade lati ibi aisi ati jiji wa fun igbende, a si jẹwọ awọn ẹsẹ wa eyiti a da, njẹ ọna kan wa ti a le tọ lati jade kuro ni inu ina ki a le pada si isẹmin aye lati se atunse awọn isẹ wa, ki O le yọnu si wa?!
ذَٰلِكُم بِأَنَّهُۥٓ إِذَا دُعِيَ ٱللَّهُ وَحۡدَهُۥ كَفَرۡتُمۡ وَإِن يُشۡرَكۡ بِهِۦ تُؤۡمِنُواْۚ فَٱلۡحُكۡمُ لِلَّهِ ٱلۡعَلِيِّ ٱلۡكَبِيرِ 12
Iya eyiti wọn fi jẹ yin yiijẹ okunfa wipe ti wọn ba pe Allah nikan soso, ti wọn ko si se ẹbọ kankan pẹlu Rẹ, ẹyin yoo se aimoore si I, ẹ o si tun wa akẹgbẹ pẹlu Rẹ, ti wọn si sin akẹgbẹ pẹlu Allah, ẹ o nigbagbọ si i, idajọ jẹ ti Allah nikan soso, ẹniti O ga pẹlu bibẹ Rẹ ati akọsilẹ Rẹ ati ibori Rẹ, olutobi ti gbogbio nkan wa ni abẹ Rẹ.
هُوَ ٱلَّذِي يُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُنَزِّلُ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ رِزۡقٗاۚ وَمَا يَتَذَكَّرُ إِلَّا مَن يُنِيبُ 13
Allah ni ẹniti o nfi awọn amin Rẹ han yin ni oferefe ati ni abara ati ni ara; lati tọka fun yin lori agbara Rẹ ati ijẹ aaso Rẹ, O si rọ omin ojo kalẹ fun yin lati sanmọ, ki o le jẹ okunfa ti ẹ o maa fi se arisiki gẹgẹ bi awọn nkan ti o nwu ninu ilẹ ati awọn nkan ti a ngbin ati ohun ti o yatọ si wọn, ẹnikan ko nii gba isiti pẹlu awọn amin Allah ayaafi ẹniti o sẹri si ọdọ Rẹ ni ironu piwada ati sise afọmọ.
فَٱدۡعُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡكَٰفِرُونَ 14
Ki ẹ ya pe Allah - ẹyin olugbagbọ ododo - ni ẹniti nse afọmọ fun Un nibi itẹle asẹ ati adura ni aiko ni se ẹbọ pẹlu Rẹ koda bi awọn keferi tako eleyi, ti o si tun bi wọn ninu.
رَفِيعُ ٱلدَّرَجَٰتِ ذُو ٱلۡعَرۡشِ يُلۡقِي ٱلرُّوحَ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ لِيُنذِرَ يَوۡمَ ٱلتَّلَاقِ 15
Oun si ni ara ile fun ni ti nse afọmọ adura ati itẹle asẹ fun Un, Oun si ni oluse agbega awọn ipo ti o hande fun gbogbo ẹda Rẹ, Oun si tun ni onitẹ ti o tobi ju, O nsọ imisi kalẹ fun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ ki wọn le maa sẹmin ati ki wọn le maa ta ẹniti o yatọ si wọn ji ati ti wọn le maa da ẹru ba awọn eniyan nipa ọjọ igbende eyiti awọn ẹni akọkọ ati awọn ẹni ikẹyin yoo pade nibẹ.
يَوۡمَ هُم بَٰرِزُونَۖ لَا يَخۡفَىٰ عَلَى ٱللَّهِ مِنۡهُمۡ شَيۡءٞۚ لِّمَنِ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَۖ لِلَّهِ ٱلۡوَٰحِدِ ٱلۡقَهَّارِ 16
Ọjọ ti wọn yoo hande ni ẹniti o kojọ si ori yerupẹ kan soso, nkankan ko si nii pamọ fun Allah nibi bibẹ wọn, bẹẹni awọn isẹ wọn, bẹẹni awọn ẹsan wọn ko nii pamọ, yoo beere: titaani ọla oni?! Kii se isinsin yii ayaafi esi kan soso; ọla jẹ ti Allah, aaso nibi bibẹ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn isẹ Rẹ, olubori eyiti o bori gbogbo nkan, ti gbogbo nkan si tẹriba fun Un.
Aaye gbigba ironu piwada ni isẹmin aye.
Anfaani isiti wa fun awọn olusẹri si ọdọ Ọlọhun Ọba wọn nikan.
Iduro sinsin olugbagbọ ododo jẹ ohun ti awọn iduro keferi olugunri fun ẹsin rẹ ko le lapa nibẹ.
Itẹriba awọn alagbara ati okunkun ninu awọn ọlọla jẹ ti Allah ni ọjọ igbende.