أَفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَم بِهِۦ جِنَّةُۢۗ بَلِ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ فِي ٱلۡعَذَابِ وَٱلضَّلَٰلِ ٱلۡبَعِيدِ 8
Wọn waa sọpe: se arakunrin yii wa hun irọ ma Allah ni, ni o fi nlero wipe igbende wa nbẹ lẹyin iku wa tabi were ni ti o nsọ ohun ti ko si ododo nibẹ? Kii se bi awọn wọnyi se nlero bikosepe dajudaju awọn ti ko nigbagbọ ninu ọjọ ikẹyin yoo wa ninu iya lile ni ọjọ igbende ati ọna anu ti o jinna si ododo ni ile aye.
أَفَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِن نَّشَأۡ نَخۡسِفۡ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضَ أَوۡ نُسۡقِطۡ عَلَيۡهِمۡ كِسَفٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّكُلِّ عَبۡدٖ مُّنِيبٖ 9
Se awọn olupe igbende nirọ yii ko wa ri ohun ti nbẹ ni iwaju wọn ni ilẹ ni ati ohun ti o nbẹ lẹyin wọn ni sanmọ? Ti a ba fẹ lati min ilẹ mọ wọn ni ẹsẹ, a ko ba min mọ wọn labẹ, ti a ba si fẹ lati ja egigan kan ni sanmọ le wọn lori, a ko ba ja a le wọn lori, dajudaju amin ti o daju nbẹ ninu eleyi fun gbogbo ẹru ti o ba ma nyara lati sẹri pada si ibi itẹle ti Ọlọhun Ọba rẹ, ti o ma nfi nse ẹri lori agbara Allah, ẹniti O lagbar lori eleyi jẹ ẹniti o lagbara lati jiyin dide lẹyin iku yin ati yiya yẹlẹyẹlẹ ara yin.
۞وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ مِنَّا فَضۡلٗاۖ يَٰجِبَالُ أَوِّبِي مَعَهُۥ وَٱلطَّيۡرَۖ وَأَلَنَّا لَهُ ٱلۡحَدِيدَ 10
Paapaa a ti fun Dawud - ẹniti ọla nbẹ fun - ni ijẹ anọbi ati ọla lati ọdọ Wa, a si sọ fun oke wipe: irẹ oke, paara pẹlu Dawud nibi afọmọ, bayi naa ni a se sọ fun ẹyẹ, a si sọ irin di ohun ti o lẹ fun un, ki o le maa se ninu rẹ ohun ti o ba wu u ninu awọn irin isẹ.
أَنِ ٱعۡمَلۡ سَٰبِغَٰتٖ وَقَدِّرۡ فِي ٱلسَّرۡدِۖ وَٱعۡمَلُواْ صَٰلِحًاۖ إِنِّي بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ 11
Ki o se - irẹ Dawud - idaabobo onirin ti o gbaaye, ti yoo maa daabobo ọ kuro lọdọ ẹniti o nba ọ ja nibi agbara ọta awọn, ki o si se awọn eso ti yoo ba awọn aye mu, mase se ni ohun ti yoo wẹ, ti ko nii le duro nibẹ, ki o si ma yi ti ko fi nii le wọ inu rẹ, ki ẹ wa maa se isẹ rere, dajudaju oluri ohun ti ẹ nse ni mo jẹ, nkankan ko pamọ fun Mi ninu awọn isẹ yin, Emi yoo si san yin lẹsan le lori.
وَلِسُلَيۡمَٰنَ ٱلرِّيحَ غُدُوُّهَا شَهۡرٞ وَرَوَاحُهَا شَهۡرٞۖ وَأَسَلۡنَا لَهُۥ عَيۡنَ ٱلۡقِطۡرِۖ وَمِنَ ٱلۡجِنِّ مَن يَعۡمَلُ بَيۡنَ يَدَيۡهِ بِإِذۡنِ رَبِّهِۦۖ وَمَن يَزِغۡ مِنۡهُمۡ عَنۡ أَمۡرِنَا نُذِقۡهُ مِنۡ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ 12
A tun rọ atẹgun fun Sulayman ọmọ Dawud ẹniti ọla nbẹ fun ti o nrin ni aarọ ni iin ajo osu kan, bẹẹni o nrin ni irọlẹ ni irin ajo osu kan, a si tun rọ ojulowo oje fun un, ki o le maa se ohun ti o ba wu u ninu oje naa, a tun rọ alujannu fun un, awọn ti o nsisẹ niwaju rẹ pẹlu asẹ Ọlọhun Ọba rẹ, eyiti o ba kuro nibi ohun ti a pa lasẹ ninu alujannu ninu isẹ, a o fi iya ina ti o njo belebele tọ ọ wo.
يَعۡمَلُونَ لَهُۥ مَا يَشَآءُ مِن مَّحَٰرِيبَ وَتَمَٰثِيلَ وَجِفَانٖ كَٱلۡجَوَابِ وَقُدُورٖ رَّاسِيَٰتٍۚ ٱعۡمَلُوٓاْ ءَالَ دَاوُۥدَ شُكۡرٗاۚ وَقَلِيلٞ مِّنۡ عِبَادِيَ ٱلشَّكُورُ 13
Awọn alujannu yii nsisẹ fun sulayman ni ohun ti o ba fẹ gẹgẹ bi masalaasi fun iran tabi awọn ile gogoro ati ohun ti o fẹ ninu aworan ati eyiti o fẹ ninu awọn apo gẹgẹ bi korondodo omin ti o tobi ati ikoko idana ti o loorin, ti ko le min nitori titobi wọn, a wa sọ fun wọn pe: - ẹyin ara Dawud - ọpẹ fun Allah lori ikdẹkun ti O se leyin lori, kekere ninu awọn ẹru Mi ni o jẹ dupẹ dupẹ fun Mi lori idẹkun ti Mo se fun wọn.
فَلَمَّا قَضَيۡنَا عَلَيۡهِ ٱلۡمَوۡتَ مَا دَلَّهُمۡ عَلَىٰ مَوۡتِهِۦٓ إِلَّا دَآبَّةُ ٱلۡأَرۡضِ تَأۡكُلُ مِنسَأَتَهُۥۖ فَلَمَّا خَرَّ تَبَيَّنَتِ ٱلۡجِنُّ أَن لَّوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ ٱلۡغَيۡبَ مَا لَبِثُواْ فِي ٱلۡعَذَابِ ٱلۡمُهِينِ 14
Nigbati a da ọjọ iku fun sulayman, nkankan ko tọka fun alujannu wipe o ti ku ayaafi kokoro ikan ti o jẹ ọpa rẹ eyiti o rọgbọku le lori, nigbati o jabọ, awọn alujannu mọ wipe awọn ko mọ kọkọ nitoripe ti jọ wipe wọn mọ ọ ni, wọn ko ti wa nibi iya ti o yẹpẹrẹ wọn yii, ohun si ni isẹ wahala eyiti wọn wa lori rẹ eyiti wọn nse fun sulayman ẹniti ọla nbẹ fun ni erongba lọdọ wọn wipe o jẹ alaaye ti o nsọ wọn.
Apọnle Allah fun anọbi Rẹ dawud nipa jijẹ anọbi ati ọla ati rirọ oke ati ẹyẹ ti o nse afọmọ iru afọmọ rẹ ati rirọ irin fun un.
Apọnle Allah fun anọbi sulayman ẹniti ọla nbẹ fun pẹlu jijẹ anọbi ati ọla.
jijẹwọ idẹkun naa nitori ọpẹ fun Allah le lori.
Dida Allah yanri nibi imọ ikọkọ, ko si ipilẹ fun ohun ti awọn eniyan nsọ lori wipe alujannu tabi eniti o yatọ si wọn nboju wo kọkọ.