وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ ٱئۡتُونِي بِكُلِّ سَٰحِرٍ عَلِيمٖ 79
Fir'aona tun sọ fun ijọ rẹ: ẹ mu gbogbo pidanpidan to dantọ nibi idan, ti o mọọ yanju wa fun mi.
فَلَمَّا جَآءَ ٱلسَّحَرَةُ قَالَ لَهُم مُّوسَىٰٓ أَلۡقُواْ مَآ أَنتُم مُّلۡقُونَ 80
Nigbati wọn mu awọn onidan wa fun fir'aona, musa ti ikọ ati ọla nbẹ fun sọ fun wọn niti igbarale aranse Rẹ le wọn lori, ẹ ju -ẹyin pidan pidan - ohun ti ẹ fẹ ju silẹ.
فَلَمَّآ أَلۡقَوۡاْ قَالَ مُوسَىٰ مَا جِئۡتُم بِهِ ٱلسِّحۡرُۖ إِنَّ ٱللَّهَ سَيُبۡطِلُهُۥٓ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُصۡلِحُ عَمَلَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ 81
Nigbati wọn ju idan ti nbẹ ni ọdọ wọn, musa sọ fun wọn ẹniti ikẹ nbẹ fun: ẹyiti ẹ nse afihan rẹ yi ni idan, dajudaju Ọlọhun Ọba yoo sọ ohun ti ẹ se yii di ibajẹ ti ko si ni si oripa fun un, dajudaju idan yin yii ẹ fi njẹ olubilẹjẹ ni, Ọlọhun Ọba Allah ko si nii tun isẹ ẹniti o jẹ olubilẹjẹ se.
وَيُحِقُّ ٱللَّهُ ٱلۡحَقَّ بِكَلِمَٰتِهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُجۡرِمُونَ 82
Ọlọhun Ọba Allah yoo fi ododo rinlẹ, Yoo si fi gbolohun akọsilẹ Rẹ rinlẹ ati awọn ofin ti o wa ninu gbolohun Rẹ bii awọn ẹri ati awọn awijare, koda bi awọn keferi bi awọn ara ile fir'aona kọ.
فَمَآ ءَامَنَ لِمُوسَىٰٓ إِلَّا ذُرِّيَّةٞ مِّن قَوۡمِهِۦ عَلَىٰ خَوۡفٖ مِّن فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِمۡ أَن يَفۡتِنَهُمۡۚ وَإِنَّ فِرۡعَوۡنَ لَعَالٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلۡمُسۡرِفِينَ 83
Awọn ijọ naa pinnu lati gunri, wọn ko gba Musa ẹni ikẹ nbẹ fun lododo pẹlu awọn amin ti o fi oju han ati awọn ẹri ti o yanju ti o mu wa ayaafi awọn ọdọ ninu ijọ rẹ ninu ọrọmọdọmọ Isirẹli, Fir'aona ati awọn onigberaga ninu ijọ rẹ nyi igbagbọ wọn pada lati fi iya jẹ wọn niti ipaya ki asiri wọn maa ba tu, ati wipe dajudaju fir'aona jẹ olugberaga, olujẹgaba lori ilu misira ati awọn eniyan bẹ, dajudaju o jẹ ọkan ninu awọn olukọja ẹnu aala nibi sise keferi ati ipaniyan ati fifi kiya jẹ arọmọdọmọ isirẹli.
وَقَالَ مُوسَىٰ يَٰقَوۡمِ إِن كُنتُمۡ ءَامَنتُم بِٱللَّهِ فَعَلَيۡهِ تَوَكَّلُوٓاْ إِن كُنتُم مُّسۡلِمِينَ 84
Musa ti ọla anbẹ fun tun sọ fun awọn ijọ rẹ: ẹyin ijọ mi, ti ẹ ba nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ni igbagbọ ododo, Ọlọhun Ọba Allah nikan ni ki ẹ ya gbarale ti ẹ ba jẹ olugbafa, igbarale Ọlọhun Ọba Allah yoo ti aburu kuro fun yin, yoo si mu rere wa fun yin.
فَقَالُواْ عَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلۡنَا رَبَّنَا لَا تَجۡعَلۡنَا فِتۡنَةٗ لِّلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ 85
Wọn jẹpe musa ẹniti ọla nbẹ fun wọn si sọ wipe: Ọlọhun Ọba Allah nikan ni a gbarale, Ọlọhun wa, mase fi alabosi jẹ gaba le wa lori ki wọn mase maa daamun wa nibi ẹsin wa latara ifiyajẹni, ipaniyan ati idanilaamun.
وَنَجِّنَا بِرَحۡمَتِكَ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ 86
Ki o si lawa lati ibi ikẹ Rẹ - Ọlọhun wa - kuro lọwọ ijọ fir'aona ti ojẹ keferi, wọn ti muwa lẹru, wọn fi suta se wa pẹlu ifiyajẹni ati ipani.
وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰ وَأَخِيهِ أَن تَبَوَّءَا لِقَوۡمِكُمَا بِمِصۡرَ بُيُوتٗا وَٱجۡعَلُواْ بُيُوتَكُمۡ قِبۡلَةٗ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 87
A ransẹ si Musa ati ọmọ iya rẹ Haruna ki ọla Ọlọhun maa bẹ fun wọn wipe ki wọn o se ẹsa, ki wọn o si wa ile ijọsin fun Allah nikan soso fun awọn ijọ wọn, ki ẹ si sọ awọn ile yin di idojukọ abala kibula (ile kudus), ki ẹ maa kirun ni pipe, ki o si fun niro - irẹ Musa - awọn olugbagbọ ododo nkan ti yoo dun wọn ninu, ninu aranse Ọlọhun Ọba ati ikunlọwọ wọn ati pipa awọn ọta wọn ati fifi wọn role lori ilẹ.
وَقَالَ مُوسَىٰ رَبَّنَآ إِنَّكَ ءَاتَيۡتَ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَأَهُۥ زِينَةٗ وَأَمۡوَٰلٗا فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا رَبَّنَا لِيُضِلُّواْ عَن سَبِيلِكَۖ رَبَّنَا ٱطۡمِسۡ عَلَىٰٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ وَٱشۡدُدۡ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُواْ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ 88
Musa sọ - ẹniti ọla nbẹ fun -: Ọlọhun Ọba wa dajudaju Iwọ lo fun firaona ati awọn ẹni iyi ninu ijọ rẹ ni yodoyindin aye ati ọsọ miran ni ẹgbẹgbẹẹ rẹ, O si fun wọn ni awọn dukia ni isẹmin aye yii, wọn ko dupẹ fun Ọ lori awọn oun ti o fun wọn bikose wipe wọn tun nfi se ikunlọwọ lati sọ awọn eniyan nu kuro ni oju ọna Rẹ, iwọ Ọlọhun Ọba, pa gbogbo dukia wọn rẹ, ki O si pa run, jẹ ki ọkan wọn le, wọn ko nii gbagbọ ayaafi ti wọn ba ri iya inira nigbati igbagbọ wọn ko nii se wọn ni anfaani mọ.
Igbẹkẹle Allah ati aranse Rẹ ati igbarale jẹ ohun ti o di dandan ki o jẹ iroyin olugbagbọ ododo ti o lagbara.
Sise alaye pataki adua, dajudaju o wa ninu iroyin awọn olugbarale Ọlọhun Ọba.
Kikanpamọ pataki irun ati jijẹ ọranyan gbigbeeduro nibi gbogbo isẹ to wa lati oke, ati nibi gbogbo isesi.
Sise adua lofin lori alabosi.