لُعِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۢ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ عَلَىٰ لِسَانِ دَاوُۥدَ وَعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ 78
Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun mu iro wa wipe lile awọn keferi inu arọmọdọmọ Israheel kuro nibi ikẹ rẹ, ninu tira eyiti o sọkalẹ fun Dawud tii se Sabuur, ati ninu tira eyiti o sọkalẹ fun Isa ọmọ Maryam tii se Injiila wipe igbejinna si ikẹ Ọlọhun Ọba Allah nii se nitori awọn ẹsẹ ti wọn da, ati kikọja awọn ẹnu aala iwọ Ọlọhun Ọba Allah.
كَانُواْ لَا يَتَنَاهَوۡنَ عَن مُّنكَرٖ فَعَلُوهُۚ لَبِئۡسَ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ 79
Wọn jẹ ẹniti apakan wọn kii kọ fun apakan wọn lati ma se ẹsẹ bikose wipe awọn ẹlẹsẹ ma nse afihan rẹ ninu wọn; nitori wipe nkan aida kii se aida ni ọdọ wọn nigbati aida ti di nkan ti wọn ma nse.
تَرَىٰ كَثِيرٗا مِّنۡهُمۡ يَتَوَلَّوۡنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ لَبِئۡسَ مَا قَدَّمَتۡ لَهُمۡ أَنفُسُهُمۡ أَن سَخِطَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ وَفِي ٱلۡعَذَابِ هُمۡ خَٰلِدُونَ 80
Jẹri si - ire ojise - ọpọ ninu awọn keferi ninu yahuudi wipe wọn nifẹ si awọn keferi, wọn si ma nfi si ọdọ wọn, wọn ma nba ọ sọta, bẹẹ si ni wọn ma nba gbogbo ẹniti o ba mu Ọlọhun Ọba Allah ni ọkan soso sọta, mimu awọn keferi ni aayo buru ni nkan itisiwaju wọn toripe o jẹ okunfa ibinu Ọlọhun Ọba Allah le wọn lori, ati nkan ti yoo mu wọn wọ ina ti yoo maa mu wọn gbe bẹ lọ gbere, wọn ko nii le jade kuro nibẹ lailai.
وَلَوۡ كَانُواْ يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلنَّبِيِّ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِ مَا ٱتَّخَذُوهُمۡ أَوۡلِيَآءَ وَلَٰكِنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ 81
Ti o ba ja si wipe awọn yahuudi yii nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah lododo, ti wọn si nigbagbọ ninu Anọbi Rẹ, wọn ko ba ti mu alaayo ninu awọn ẹlẹbọ, ti wọn yoo fẹran wọn, ti wọn yoo si maa fi si ọdọ wọn dipo awọn olugbagbọ ododo; toripe wọn kọ fun wọn lati maa mu keferi ni alaayo, sugbọn ọpọ ninu awọn yahuudi yii jade kuro nibi itẹle ti Ọlọhun Ọba Allah, ati mimu U ni alatilẹyin ati mimu awọn olugbagbọ ododo ni aayo.
۞لَتَجِدَنَّ أَشَدَّ ٱلنَّاسِ عَدَٰوَةٗ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱلۡيَهُودَ وَٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْۖ وَلَتَجِدَنَّ أَقۡرَبَهُم مَّوَدَّةٗ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّا نَصَٰرَىٰۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّ مِنۡهُمۡ قِسِّيسِينَ وَرُهۡبَانٗا وَأَنَّهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ 82
Iwọ yoo ri - ire ojise - awọn eniyan ti o pọ ni ijọta si awọn olugbagbọ ododo pẹlu rẹ ati ijẹ ọta si ohun ti o waa ba yahuudi; nitori ikorira, ati keeta ati igberaga ati sisin awọn oosa eyiti wọn wa lori rẹ ati awọn miran ti o yatọ si wọn ninu olusẹbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, iwọ yoo ri ẹniti o sunmọ ju ninu awọn ti o nifẹ si olugbagbọ ododo pẹlu rẹ ati nkan ti o mu wa, awọn ti wọn yoo maa sọ nipa ara wọn wipe: nassara ni wọn, ninifẹ awọn eniyan yii si awọn olugbagbọ ododo sunmọ nitori awọn onimimọ wa ninu wọn ati awọn olujọsin, ati wipe dajudaju wọn jẹ olutẹriba, wọn kii se oluse igberaga nitori wipe oore ko le de inu ọkan onigberaga.
وَإِذَا سَمِعُواْ مَآ أُنزِلَ إِلَى ٱلرَّسُولِ تَرَىٰٓ أَعۡيُنَهُمۡ تَفِيضُ مِنَ ٱلدَّمۡعِ مِمَّا عَرَفُواْ مِنَ ٱلۡحَقِّۖ يَقُولُونَ رَبَّنَآ ءَامَنَّا فَٱكۡتُبۡنَا مَعَ ٱلشَّٰهِدِينَ 83
Awọn eniyan wọnyi - gẹgẹ bi ọba najaasi ati awọn eniyan rẹ - ọkan wọn rọ nitori wipe wọn ma nsunkun niti ipaya nigbati wọn ba gbọ ohun ti o sọkalẹ ninu Alukuraani, ti wọn si gba wipe ododo ni; toripe wọn mọ nkan ti Anọbi Isa mu wa ki ọla maa ba, wọn ma nsọ wipe: iwọ Ọlọhun Ọba wa, a ni igbagbọ si nkan ti O sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ Muhammad ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa jẹ tirẹ, kọ wa mọ - irẹ Ọlọhun Ọba wa - ijọ Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, eyiti yoo jẹ awiijare lori awọn eniyan ni ọjọ igbende.
Gbigbe ipasẹ daadaa ju silẹ ati ikọfunni kuro nibi aida, ma nsọ ibi dandan, ati lileni jinna si ikẹ Ọlọhun Ọba Allah di ọranyan lori ẹni.
Ninu awọn amin igbagbọ : ohun ni ninifẹ nitori Ọlọhun Ọba Allah ati kikorira nitori ti Ọlọhun Ọba Allah.
Mimu awọn ọta Ọlọhun Ọba Allah ni aayo ma nsọ ibinu ỌlọhunỌba Allah di dandan lori ẹniti o see.
Lilekoko ijọta yahuudi ati awọn ọsẹbọ fun awọn ẹni Islam, ni ojupọnna keji, bibẹ apakan ninu awọn nasaara, ti wọn nmu inifẹ si ẹsin Islam ni ẹsin nitori wipe wọn mọ wipe ẹsin ododo ni.