وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلٗا مِّن قَبۡلِكَ مِنۡهُم مَّن قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّن لَّمۡ نَقۡصُصۡ عَلَيۡكَۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأۡتِيَ بَِٔايَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ فَإِذَا جَآءَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قُضِيَ بِٱلۡحَقِّ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ 78
Atipe paapaa A ti gbe ọpọ awọn ojisẹ dide siwaju ti rẹ, - irẹ ojise - si awọn ijọ wọn, wọn pe wọn nirọ, wọn si fi suta se wọn, wọn wa se suuru lori irọ ti wọn pa mọ wọn ati suta ti wọn fi se wọn, o nbẹ ninu awọn ojisẹ yii awọn ti a sọ itan wọn fun ọ, o si wa ninu wọn awọn ti a ko sọ itan wọn fun ọ, ko tọ fun ojisẹ kan ki o mu amin wa fun ijọ rẹ lati ọdọ Ọlọhun rẹ ayaafi fifẹ Rẹ ti mimọ nbẹ fun, mimumọran wa keferi fun awọn ijọ wọn lati mu awọn amin wa jẹ abosi, ti asẹ Allah ba de gẹgẹ bi isipaya tabi ise atunse laarin awọn ojisẹ ati awọn ijọ wọn, yoo se atunse laarin wọn ati deedee, wọn si mu iparun ba awọn keferi, bẹẹni wọn la awọn ojisẹ, awọn onibajẹ padanu - ni aaye yii eyiti wọn ti se atunse laarin awọn ẹrusin - ẹmin ara wọn nitoripe wọn mu lọ sibi iparun pẹlu idi keferi wọn.
ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَنۡعَٰمَ لِتَرۡكَبُواْ مِنۡهَا وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ 79
Allah ni O se rakunmi, maalu ati agunta fun yin; ki ẹ le maa gun apakan, ki ẹ si maa jẹ ekiri apakan.
وَلَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَلِتَبۡلُغُواْ عَلَيۡهَا حَاجَةٗ فِي صُدُورِكُمۡ وَعَلَيۡهَا وَعَلَى ٱلۡفُلۡكِ تُحۡمَلُونَ 80
Awọn anfaani ti ko ni onka ti o jẹ ọtun ọtun ni gbogbo igba wa fun yin nibi awọn ẹda yii, lati ara rẹ awọn nkan ti ẹ nfẹ ninu bukaata fun ara yin nsẹlẹ si yin, eyiti o fi oju han ju nibẹ ni gbigbera ni ori ilẹ ati ori omin.
وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ فَأَيَّ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُنكِرُونَ 81
Oun ti mimọ nbẹ fun nfi awọn amin Rẹ ti ntọka si agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ han yin, ewo ninu awọn amin Allah ni ẹ ko jẹwọ rẹ lẹyin igbati o ti rinlẹ lọdọ yin wipe o jẹ awọn amin Rẹ?!
أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِنۡهُمۡ وَأَشَدَّ قُوَّةٗ وَءَاثَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 82
Se awọn opurọ wọnyi ko rin lorilẹ ni ki wọn si ronu si bi igbẹyin awọn ijọ opurọ se ri siwaju wọn, ki wọn si woye pẹlu rẹ?! Paapaa awọn ijọ naa pọ ju wọn lọ ni dukia, wọn si tobi ni agbara, wọn si ni awọn oripa gidi ni ilẹ, awọn ohun ti wọn kojọ ninu agbara ko rọ wọn lọrọ ni igbati iya Allah apanirun de.
فَلَمَّا جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرِحُواْ بِمَا عِندَهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 83
Ni igbati awọn ojisẹ wọn mu awọn awijare ti o fi oju han wa, wọn pe e nirọ, wọn si yọnu si gbigba imọ ti o wa lọdọ wọn mu eyiti o ntako ohun ti awọn ojisẹ wọn mu wa, iya eyiti wọn fi nse yẹyẹ si sọkalẹ fun wọn, eyiti awọn ojisẹ wọn fi ndẹru ba wọn nibẹ.
فَلَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥ وَكَفَرۡنَا بِمَا كُنَّا بِهِۦ مُشۡرِكِينَ 84
Nigbati wọn ri iya wa, wọn sọrọ ni ẹniti o fi nrinlẹ nigbati ifirinlẹ ko le se anfaani fun wọn: a nigbagbọ si Allah ọkan soso, a si se aimoore si ohun ti a njọsin fun yatọ si I ninu awọn akẹgbẹ ati awọn oosa.
فَلَمۡ يَكُ يَنفَعُهُمۡ إِيمَٰنُهُمۡ لَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَاۖ سُنَّتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي قَدۡ خَلَتۡ فِي عِبَادِهِۦۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡكَٰفِرُونَ 85
Igbagbọ wọn ko se wọn ni anfaani nigbati wọn ti fi oju ri iya Wa ti o sọkalẹ fun wọn, isesi Allah ti o ti fe kọja lori awọn ẹru Rẹ nipe igbagbọ wọn ko nii se wọn lanfaani nigbati wọn ba ti fi oju ri iya, awọn keferi padanu ẹmin wọn nigbati iya sọkalẹ le wọn lori pẹlu mimu lọ si aaye iparun nitori keferi wọn si Allah ati aironu piwada kuro nibẹ siwaju fifi oju ri iya.
Allah ni awọn ojisẹ ti o yatọ si awọn eyiti Allah darukọ ninu Alukuraani alapọnle, a o nigbagbọ si wọn lapapọ.
Ninu awọn idẹkun Allah ni sise alaye Rẹ awọn aayah eyiti ọ tọka si ọkan soso Rẹ.
Ewu ayọpọrọ lori ibajẹ ati aburu igbẹyin rẹ lori ẹni rẹ.
Bibajẹ igbagbọ nigba ifoju ri iya apanirun.