قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلۡمٍ عِندِيٓۚ أَوَ لَمۡ يَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ قَدۡ أَهۡلَكَ مِن قَبۡلِهِۦ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مَنۡ هُوَ أَشَدُّ مِنۡهُ قُوَّةٗ وَأَكۡثَرُ جَمۡعٗاۚ وَلَا يُسَۡٔلُ عَن ذُنُوبِهِمُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ 78
Qọruna sọpe: wọn fun mi ni awọn dukia yii nitori imọ ti nbẹ ni ọdọ mi ati agbara, emi ni mo waa lẹtọ si eleyi, se Qọruna ko wa mọ ni wipe dajudaju Allah ti pa awọn kan run ninu awọn ijọ ti o ti siwaju, awọn ti agbara wọn le, ti o si pọ di dukia?! Agbara wọn ko se wọn lanfaani, bẹẹni dukia wọn, wọn ko si ni beere ẹsẹ ni ọdọ awọn ẹlẹsẹ ni ọjọ igbende nitori imọ Ọlọhun Ọba si i, ibeere wọn yoo jẹ ibeere ipanilẹkun ati eebu.
فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ فِي زِينَتِهِۦۖ قَالَ ٱلَّذِينَ يُرِيدُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا يَٰلَيۡتَ لَنَا مِثۡلَ مَآ أُوتِيَ قَٰرُونُ إِنَّهُۥ لَذُو حَظٍّ عَظِيمٖ 79
Qọruna waa jade ninu ọsọ rẹ ni ẹniti nse afihan igbadun rẹ, awọn ti wọn rankan ọsọ isẹmin ile aye ninu awọn eniyan Qọruna sọpe: o ma se fun wa ti wọn ko fun wa ni ọsọ ile aye iru eyiti wọn fun Qọruna, dajudaju Qọruna jẹ onipin ti o pe, ti o si tobi.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ وَيۡلَكُمۡ ثَوَابُ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لِّمَنۡ ءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗاۚ وَلَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ٱلصَّٰبِرُونَ 80
Bẹẹni awọn ti wọn fun ni imọ sọ nigbati wọn ri Qọruna ninu ọsọ rẹ, ti wọn si gbọ nkan ti awọn eniyan rẹ nrankan: egbe yin ọ! ẹsan Allah ni ọrun ati ohun ti o pese ninu idẹkun fun awọn ti o nigbagbọ si I, ti wọn si sisẹ rere loore ju ohun ti wọn fun Qọruna ju yodoyindin aye lọ, ẹnikan ko nii se kongẹ gbolohun yii ati isẹ ti o se dọgba rẹ ayaafi awọn onisuuru, awọn ti wọn nse ifarada lori gbigbe ọla fun ẹsan ti nbẹ ni ọdọ Allah lọ lori ohun ti o wa laye lori idẹkun ti yoo yẹ.
فَخَسَفۡنَا بِهِۦ وَبِدَارِهِ ٱلۡأَرۡضَ فَمَا كَانَ لَهُۥ مِن فِئَةٖ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُنتَصِرِينَ 81
A fi ilẹ gbemi ati ile rẹ ati awọn ti ohun ti o nbẹ nibẹ niti gbigba ẹsan lori ikọja ẹnu aala rẹ, ko si ijọ kankan fun un ti o le ranse yatọ si Allah, bẹẹni oun naa ko si ninu ẹniti o le ran ara rẹ se.
وَأَصۡبَحَ ٱلَّذِينَ تَمَنَّوۡاْ مَكَانَهُۥ بِٱلۡأَمۡسِ يَقُولُونَ وَيۡكَأَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ وَيَقۡدِرُۖ لَوۡلَآ أَن مَّنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡنَا لَخَسَفَ بِنَاۖ وَيۡكَأَنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡكَٰفِرُونَ 82
Awọn ti wọn nrankan ohun ti o wa ninu rẹ ni owo, lọsọ siwaju ki o to tẹri di ẹniti nsọ wipe niti ẹni ofo ati olugba oye: se a ko mọ wipe dajudaju Allah ma ntẹ arisiki Rẹ fun ẹniti ti O ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ, A si maa fun mọ ẹniti o ba wu U ninu wọn?! Ti kii ba sepe Allah se idẹkun le wa lori, ti ko fi fi iya jẹ wa lori ohun ti a sọ, ki ba tẹ awa naa ri gẹgẹ bi O se tẹ Qọruna ri, dajudaju awọn keferi ko le jere, ni ile aye ni tabi ni ọrun bikosepe dajudaju isẹri wọn ati ibupadasi wọn yoo jẹ ofo ni aaye mejeeji.
تِلۡكَ ٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ نَجۡعَلُهَا لِلَّذِينَ لَا يُرِيدُونَ عُلُوّٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فَسَادٗاۚ وَٱلۡعَٰقِبَةُ لِلۡمُتَّقِينَ 83
Ile ọrun yii, A se ni ile idẹkun ati isepọnle fun awọn ti ko gbero igberaga lorilẹ nipa ini igbagbọ si ododo ati titẹle e, wọn ko si gbero ibajẹ nibẹ, bẹẹni igbẹyin daadaa ni ohun ti nbẹ ninu Alujannah ninu idẹkun ati ohun ti yoo sẹlẹ nibẹ ninu iyọnu Allah fun awọn olubẹru Ọlọhun wọn pẹlu titẹle asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ.
مَن جَآءَ بِٱلۡحَسَنَةِ فَلَهُۥ خَيۡرٞ مِّنۡهَاۖ وَمَن جَآءَ بِٱلسَّيِّئَةِ فَلَا يُجۡزَى ٱلَّذِينَ عَمِلُواْ ٱلسَّئَِّاتِ إِلَّا مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 84
Ẹniti o ba mu daadaa wa ni ọjọ igbende - gẹgẹ bi irun, saka ati aawẹ ati ohun ti o yatọ si i - ẹsan ti o loore ju eleyi nbẹ fun lori daadaa naa nitori wọn yoo se adipele daadaa fun un titi di mẹwa iru rẹ, ẹniti o ba si wa ni ọjọ igbende pẹlu aburu bi keferi, jijẹ riba, agbere ati ohun ti o yatọ si i -, wọn ko nii sẹsan fun awọn ti o se aida ju iru ohun ti wọn se lọ ni ẹsan ti ko si ni lekun.
Gbogbo ohun ti nbẹ ni ọdọ ọmọniyan ni rere ati idẹkun, o wa lati ọdọ Allah ni, didara rẹ ati pipebubu rẹ.
Awọn onimimọ ni awọn ọlọgbọn ati ọla kuro nibi idaamu; nitoripe dajudaju yoo da oju ẹniti o ba ni kọ dọgba.
Igberaga ati moto moto lorilẹ ati fifan ibajẹ ka igbẹyin rẹ jẹ iparun ati ofo.
Gbigbaaye ikẹ Allah ati deedee rẹ nibi sise adipele awọn daadaa fun olugbagbọ ododo ati aise adipele aburu fun keferi.