إِنَّهُۥ لَقُرۡءَانٞ كَرِيمٞ 77
Dajudaju Alukuraani naa ti a nka fun yin -ẹyin eniyan- jẹ Alukuraani alapọnle; nitori awọn anfaani ti o tobi, ti o wa nibẹ.
فِي كِتَٰبٖ مَّكۡنُونٖ 78
Ninu iwe kan ti a daabobo kuro ni oju awọn eniyan, ohun si ni apọn ti a daabobo.
لَّا يَمَسُّهُۥٓ إِلَّا ٱلۡمُطَهَّرُونَ 79
Ẹnikan ko le fi ọwọ kan an ayaafi awọn malaika ẹni mimọ kuro nibi awọn ẹsẹ ati awọn aleebu.
تَنزِيلٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 80
O jẹ ohun ti a sọkalẹ lọdọ Ọlọhun gbogbo ẹda fun anọbi Rẹ Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
أَفَبِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ أَنتُم مُّدۡهِنُونَ 81
Se ọrọ eleyi ni ẹyin jẹ - ẹyin ẹlẹbọ - olupurọ ti kii se olododo?!
وَتَجۡعَلُونَ رِزۡقَكُمۡ أَنَّكُمۡ تُكَذِّبُونَ 82
Ti ẹ se pipe e nirọ ni idupẹ yin fun Allah lori aranse awọn idẹkun ti O se fun yin, ti ẹ wa nse afiti ojo si ọdọ irawọ Naohu, ti ẹ si nsọpe, wọn fun wa lomin lati ibi irawọ naohu bayi bayi?!
Nigbati wọn sọ apakan awọn ẹri ajinde, O gbero lati ta awọn eniyan ji si agbara Rẹ, nipa idawọn pada pẹlu titọka si kikagara wọn lati kọdi iku, ẹniti o pani lagbara lati jinni.
فَلَوۡلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلۡحُلۡقُومَ 83
Bawo ni yoo se ri nigbati ẹmin ba de ibi ọna ọfun.
وَأَنتُمۡ حِينَئِذٖ تَنظُرُونَ 84
Ti ẹyin si nwo ẹniti o npọka iku niwaju yin ni asiko yii.
وَنَحۡنُ أَقۡرَبُ إِلَيۡهِ مِنكُمۡ وَلَٰكِن لَّا تُبۡصِرُونَ 85
Awa pẹlu imọ Wa ati agbara Wa ati awọn Malaika Wa si ni ẹniti o sun mọ oku yin ju yin lọ, sugbọn ẹ ko ri awọn Malaika yii.
فَلَوۡلَآ إِن كُنتُمۡ غَيۡرَ مَدِينِينَ 86
Bawo ni - ti ẹ ba jẹ, gẹgẹ bi ẹ se nlero ẹniti a ko nii gbe dide fun sisan yin lẹsan lori awọn isẹ yin -.
تَرۡجِعُونَهَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 87
Lati da ẹmin naa pada eyiti o jade ni ara oku yin ti ẹ ba jẹ olododo?! ẹ ko lagbara eleyi.
فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ 88
Ti oku naa ba jẹ ninu awọn ẹni isiwaju lọsi ibi awọn rere.
فَرَوۡحٞ وَرَيۡحَانٞ وَجَنَّتُ نَعِيمٖ 89
Isimin nbẹ fun un ti ko nii daamun lẹyin rẹ ati arisiki mimọ ati ikẹ, ọgba idbra si nbẹ fun un ti yoo maa gbadun pẹlu ohun ti o ba wu u nibẹ.
وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ 90
Sugbọn ti oku ba wa ninu awọn ẹni ọtun.
فَسَلَٰمٞ لَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡيَمِينِ 91
Mase ko ọrọ wọn leya, alaafia ati ifọkanbalẹ nbẹ fun wọn.
وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ٱلضَّآلِّينَ 92
Sugbọn ti oku ba jẹ ninu awọn olupe ohun ti ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mu wa nirọ, ti o si jẹ ẹni anu kuro nibi oju ọna ti o duro tọ.
فَنُزُلٞ مِّنۡ حَمِيمٖ 93
Ikona alejo rẹ ti wọn yoo fi ko o loju ni omin gbigbona ti igbona rẹ le koko.
وَتَصۡلِيَةُ جَحِيمٍ 94
Igbona pẹlu ina jahimu si wa fun un.
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ ٱلۡيَقِينِ 95
Dajudaju eyiti a sọ itan rẹ fun ọ yii - irẹ ojisẹ - paapaa o jẹ ododo amọdaju ti ko si iyemeji nibẹ.
فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ 96
Orukọ Ọlọhun Ọba rẹ ti o tobi mọ kanga, ki o si fọ Ọ mọ kuro nibi awọn adinku.
سورة (MADANIYYAH)
Giga ipo pẹlu ẹmi fun igbagbọ ati ninawo si oju ọna Allah.
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 1
Gbogbo ohun ti o wa ni sanmọ ati ilẹ ninu awọn ẹda Rẹ ni o nfọ Allah mọ, ti wọn si nse afọmọ Rẹ, Oun si ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu.
لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ 2
TiRẹ nikan ni ikapani gbogbo sanmọ ati ilẹ, O ma nji ẹniti o ba wu U lati taji, O si ma npa ẹniti o ba wu U lati pa, Oun si ni alagbara lori gbogbo nkan ti nkankan ko ko agara ba A.
هُوَ ٱلۡأَوَّلُ وَٱلۡأٓخِرُ وَٱلظَّٰهِرُ وَٱلۡبَاطِنُۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ 3
Oun ni akọkọ ti nkankan ko siwaju Rẹ, Oun si ni igbẹyin ti nkankan ko si lẹyin Rẹ, Oun ni ohun ti han ju ti nkankan ko si loke Rẹ, Oun ni O pamọ ti nkankan ko pamọ to O, Oun ni onimimọ si gbogbo nkan, nkankan ko bọ mọ lọwọ.
Lilekoko ipọka iku ati kikagara ọmọniyan lati kọ di.
Ipilẹ nipe ọmọniyan ko le ri awọn Malaaika ayaafi ti allah ba gbero nitori ọgbọn kan.
Awọn orukọ Allah tii se (alakọkọ, igbẹyin, ẹniti o han, ẹniti o pamọ) jẹ ohun ti bukaata gbigbe titobi fun Allah ati mimọ sọ nibi awọn isẹ ti o han ati eyiti o pamọ.