وَجَعَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُۥ هُمُ ٱلۡبَاقِينَ 77
A la awọn ara ile rẹ ati awọn olukọse rẹ awọn olugbagbọ ododo nikan, bẹẹni a si ti tẹ ẹniti o yatọ si wọn ri ninu ijọ rẹ ti wọn jẹ keferi.
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ 78
A si sẹku fun un ẹyin ti o dara, ti wọn yoo maa yin le lori ninu awọn ijọ ti o tẹle e.
سَلَٰمٌ عَلَىٰ نُوحٖ فِي ٱلۡعَٰلَمِينَ 79
Ifọkanbalẹ alaafia ki o ma bẹ fun Nuhu ju ki a maa sọ aburu nipa rẹ ninu awọn ijọ ti o tẹle e, bikosepe ẹyin ati iranti ti o dara yoo maa sẹku fun un.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 80
Dajudaju apejuwe ẹsan yii eyiti a san fun Nuha ẹniti ọla nbẹ fun ni a o fi sẹsan fun awọn oluse daadaa ati itẹle asẹ wọn fun Allah nikan soso.
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 81
Dajudaju Nuha wa ninu awọn ẹru Wa ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, ti wọn sisẹ itẹle ti Allah.
ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ 82
Lẹyin naa a tẹ awọn ti o sẹku ri pẹlu okun tufaanu eyiti a ran si wọn, ẹnikankan ko sẹku ninu wọn.
۞وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِۦ لَإِبۡرَٰهِيمَ 83
Dajudaju Ibrahim wa ninu ẹlẹsin rẹ, awọn ti wọn kun un lọwọ nibi ipepe si ijọkan soso Allah.
إِذۡ جَآءَ رَبَّهُۥ بِقَلۡبٖ سَلِيمٍ 84
Ranti nigbati o wa ba Ọlọhun Ọba rẹ pẹlu ọkan ti o mọ kuro nibi ẹbọ, ti o se isiti ti Allah fun ẹda Rẹ.
إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَاذَا تَعۡبُدُونَ 85
Nigbati o sọ fun baba rẹ ati awọn ijọ rẹ ti wọn jẹ ẹlẹbọ ni ẹniti o nbu wọn: kinni eyiti ẹ nsin yatọ si Allah?!
أَئِفۡكًا ءَالِهَةٗ دُونَ ٱللَّهِ تُرِيدُونَ 86
Se awọn Ọlọhun irọ ni ẹ nsin yatọ si Allah bi?
فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 87
Kinni ero yin - ẹyin ijọ mi - si olutọju gbogbo agbanla aye nigbati ẹ ba pade rẹ ti ẹ si wa nsin nkan miran ti o yatọ si I?! Kinni ẹ lero wipe yoo se pẹlu yin?!
فَنَظَرَ نَظۡرَةٗ فِي ٱلنُّجُومِ 88
Ibrahim wo iwoyesi awọn irawọ, o nronu ete lati la jade pẹlu awọn ijọ rẹ.
فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٞ 89
O wa sọ ni ẹniti nwi awijare jijade pẹlu ijọ rẹ lọsi ibi ọdun wọn: dajudaju alaarẹ ni mi.
فَتَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ مُدۡبِرِينَ 90
Wọn gbe ju silẹ, wọn si lọ.
فَرَاغَ إِلَىٰٓ ءَالِهَتِهِمۡ فَقَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ 91
O wa sẹri sibi awọn ọlọhun wọn eyiti wọn nsin yatọ si Allah, o wa sọrọ ni ẹniti o nfi awọn ọlọhun wọn se yẹyẹ: se ẹ ko nii jẹ ninu ounjẹ ti awọn ẹlẹbọ pese fun yin?!
مَا لَكُمۡ لَا تَنطِقُونَ 92
Kilo se yin ti ẹ ko le sọrọ, ẹ ko si le fesi fun ẹniti nbeere ibeere lọwọ yin?! Se iru eyi lo yẹ ki wọn maa sin yatọ si Allah bi?!
فَرَاغَ عَلَيۡهِمۡ ضَرۡبَۢا بِٱلۡيَمِينِ 93
Ibrahim wa sẹri sibi fifi iya jẹ wọn pẹlu ọwọ ọtun rẹ lati kan wọn.
فَأَقۡبَلُوٓاْ إِلَيۡهِ يَزِفُّونَ 94
Bayi ni awọn olusin oosa yii yiju si i ni kiakia.
قَالَ أَتَعۡبُدُونَ مَا تَنۡحِتُونَ 95
Ibrahim si pade wọn niti iduro sinsin, o wa ọs fun wọn ni ẹniti o nbu wọn: se ẹ nsin nkan miran ti o yatọ si Allah ni ọlọhun ni, ẹyin ni ẹ gbẹ wọn pẹlu ọwọ yin?!
وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ وَمَا تَعۡمَلُونَ 96
Allah ti mimọ nbẹ fun ni o si da yin ni ẹyin gan angan, O si tun da isẹ yin, ninu isẹ yin yii ni awọn oosa, Oun ni o wa lẹtọ ki wọn sin ni Oun nikan, ti wọn ko gbọdọ mu nkan miran mọ.
قَالُواْ ٱبۡنُواْ لَهُۥ بُنۡيَٰنٗا فَأَلۡقُوهُ فِي ٱلۡجَحِيمِ 97
Nigbati wọn kagara lati ba fi iga gbaga pẹlu awijare, wọn sẹri sibi agbara, wọn si ji roro laarin ara wọn, kinni ohun ti wọn yoo se nipa Ibrahim yii, wọn sọpe: ẹ mọ ile kan fun un, ki ẹ si ko igi kun inu rẹ, ki ẹ si jo o nina, lẹyin naa ki ẹ ju u sibẹ.
فَأَرَادُواْ بِهِۦ كَيۡدٗا فَجَعَلۡنَٰهُمُ ٱلۡأَسۡفَلِينَ 98
Ijọ Ibrahim gbero aburu ro Ibrahim lati pa a run ki wọn le simin nipa rẹ, awa sọ wọn di ẹni ofo, nigbati a sọ ina naa di tutu ati alaafia.
وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهۡدِينِ 99
Ibrahim sọpe: dajudaju emi nse irin ajo lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba mi ni ẹniti o ngbe ilu ijọ mi ju silẹ ki nle fi ọkan balẹ nibi ijọsin Rẹ, Ọlọhun Ọba mi yoo tọ mi si ohun ti oore nbẹ nibẹ ni aye ati lọrun.
رَبِّ هَبۡ لِي مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 100
Irẹ Ọlọhun ỌBa mi, ran mi se ni ọmọkunrin rere ti yoo jẹ iranlọwọ fun mi ati ipaarọ dipo awọn ijọ mi nibi ajo ojiji.
فَبَشَّرۡنَٰهُ بِغُلَٰمٍ حَلِيمٖ 101
A jẹpe rẹ, a si fun niro ohun ti yoo dun un ninu pẹlu wipe a fun niro idunnu ọmọ ti yoo dagba, ti yoo di onitẹmọra, ọmọ naa ni Ismail ẹniti alaafia nbẹ fun.
فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ ٱلسَّعۡيَ قَالَ يَٰبُنَيَّ إِنِّيٓ أَرَىٰ فِي ٱلۡمَنَامِ أَنِّيٓ أَذۡبَحُكَ فَٱنظُرۡ مَاذَا تَرَىٰۚ قَالَ يَٰٓأَبَتِ ٱفۡعَلۡ مَا تُؤۡمَرُۖ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّٰبِرِينَ 102
Nigbati Ismail dagba, ti igbesẹ rẹ ba igbesẹ baba rẹ, baba rẹ Ibrahim ri lojuran, bẹẹni ala awọn anọbi Ọlọhun jẹ imisi, Ibrahim sọrọ ni ẹniti o nfun ọmọ rẹ niro nipa ohun ti ala naa ko sinu: irẹ ọmọ mi, dajudaju emi ri ni ojuran wipe mo ndu ọ, kinni ohun ti o ri si eleyi, Ismail fọ esi fun baba rẹ ni ẹniti o nsọpe: irẹ baba mi, se ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ pa ọ lasẹ nipa didu mi, iwọ yoo ri mi ninu awọn onisuuru ẹniti yoo yọnu si idajọ Allah.
Ninu ojupọnna idẹkun lori Nuha: ni ọla Nuha ati ti o nigbagbọ pẹlu rẹ, o si se arọmọdọmọ rẹ ni ipilẹ abara ati awọn isan ati iran, ati sisẹ iranti ti o rẹwa ku ati ẹyin ti o dara.
Awọn isẹ ọmọniyan Allah ni o da a, ẹru ni o si nse e pẹlu sisẹsa rẹ.
Ẹniti o fẹ du ni ibamun si awọn aayah yii ati tito o tẹle ara wọn, oun ni Ismail ẹniti ọla nbẹ fun; toripe oun ni ẹniti a fi fun ni niro idunnu ni igba akọkọ sugbọn Ishaaq ẹniti ọla nbẹ fun wọn fi muro idunnu wa lẹyin Ismail ẹniti ọla nbẹ fun ni.
Gbolohun Ismail: (سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّٰبِرِينَ) (iwọ yoo ri mi ti Allah ba fẹ ninu awọn onisuuru) jẹ okunfa kongẹ Allah lori suuru; nitoripe o gbe ọrọ ti fun Allah.