وَإِنَّهُۥ لَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ 77
Dajudaju o jẹ imọna, ikẹ fun awọn olugbagbọ ododo ti wọn nsisẹ pẹlu ohun ti o wa nibẹ.
إِنَّ رَبَّكَ يَقۡضِي بَيۡنَهُم بِحُكۡمِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡعَلِيمُ 78
Dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ -ire ojise- yoo se idajọ laarin awọn eniyan olugbagbọ inu wọn ati keferi inu wọn ni ọjọ igbende pẹli idajọ rẹ deedee, Yoo si jẹ olugbagbọ ododo, bẹẹni Yoo fi iya jẹ keferi, Oun si ni Ọba Alagbara ti O nma gbẹsan lara awọn ọta Rẹ, ẹnikankan ko le bori Rẹ, Onimimọ ti ẹniti o lẹtọ ko le dapọ mọ olubilẹjẹ lọdọ Rẹ.
فَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۖ إِنَّكَ عَلَى ٱلۡحَقِّ ٱلۡمُبِينِ 79
Ki o ya gbarale Allah, ki o si gbọkan le E lori gbogbo alamọri rẹ, dajudaju ori ododo ti o fi oju han ni o wa.
إِنَّكَ لَا تُسۡمِعُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَلَا تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا وَلَّوۡاْ مُدۡبِرِينَ 80
Dajudaju iwọ - irẹ ojisẹ - o ko le mu awọn oku gbọ, awọn ti ọkan wọn ti ku nitori sise keferi wọn si Allah, bẹẹni o ko le mu ẹniti Allah di ni eti igbọran rẹ gbọ ododo ounti o npe wọn si nigbati wọn ba sẹri ni ẹniti o gunri kuro lọdọ rẹ.
وَمَآ أَنتَ بِهَٰدِي ٱلۡعُمۡيِ عَن ضَلَٰلَتِهِمۡۖ إِن تُسۡمِعُ إِلَّا مَن يُؤۡمِنُ بَِٔايَٰتِنَا فَهُم مُّسۡلِمُونَ 81
Bẹẹni o kole fi awọn ti iriran wọn ti fọ kuro nibi ododo mọna, mase banujẹ le wọn lori tabi daamun ẹmin ara rẹ, bẹẹni iwo ko kapa lati fi ododo ye wọn ayaafi ẹniti o nigbagbọ si awọn amin Wa toripe awọn ni yoo tẹriba fun awọn asẹ Allah.
۞وَإِذَا وَقَعَ ٱلۡقَوۡلُ عَلَيۡهِمۡ أَخۡرَجۡنَا لَهُمۡ دَآبَّةٗ مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ تُكَلِّمُهُمۡ أَنَّ ٱلنَّاسَ كَانُواْ بَِٔايَٰتِنَا لَا يُوقِنُونَ 82
Nigbati iya ba di dandan ti o si rinlẹ le wọn lori nitori wiwo mọ keferi wọn ati awọn ẹsẹ wọn, ti o wa sẹku awọn eniyan buruku, a o mu amin ninu awọn amin wa ti o tobi jade fun wọn nigbati igbende ba sun mọ, ohun si ni ẹranko kan lori ilẹ, yoo maa ba wọn sọrọ pẹlu ohun ti wọn gbọ ye wipe dajudaju awọn eniyan wọn ko nii gbọ lododo awọn amin wa ti a sọkalẹ fun anọbi wa.
وَيَوۡمَ نَحۡشُرُ مِن كُلِّ أُمَّةٖ فَوۡجٗا مِّمَّن يُكَذِّبُ بَِٔايَٰتِنَا فَهُمۡ يُوزَعُونَ 83
Si tun ranti - irẹ ojisẹ - ọjọ ti a o ko awọn ijọ onigberaga jọ ninu awọn ijọ kọọkan ninu awọn ti npe awọn amin wa nirọ ti apakan yoo maa da ọrọ pada si apa miran, lẹyin naa wọn yoo da wọn lọ si ibi isiro.
حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُو قَالَ أَكَذَّبۡتُم بَِٔايَٰتِي وَلَمۡ تُحِيطُواْ بِهَا عِلۡمًا أَمَّاذَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 84
Didawọn lọ yoo tẹsiwaju titi wọn yoo fi de aaye isiro wọn, Allah yoo maa sọ fun wọn niti bibu wọn: se ẹ npe awọn amin mi nirọ eyiti ntọka si ijọkan soso mi, ti o si tunn ko awọn ofin mi sinu, ẹ ko wa ni imọ wipe ibajẹ ni ti irọ yin fi se lọsọ tabi kin ni ẹ se pẹlu rẹ ninu gbigba lododo tabi pipe e nirọ?!
وَوَقَعَ ٱلۡقَوۡلُ عَلَيۡهِم بِمَا ظَلَمُواْ فَهُمۡ لَا يَنطِقُونَ 85
Iya yoo si sẹlẹ le wọn lori lati ara abosi wọn pẹlu sise keferi si Allah ati pipe awọn amin rẹ nirọ, wọn ko ni le sọrọ lati daabobo ẹmin ara wọn nitori ailagbara wọn si eleyi ati ibajẹ awijare wọn.
Nigbati o ja si wipe wọn tako igbende, Allah ta wọn ji si ounti o tọka si eleyi ninu isẹmin wọn ohun si ni oorun eyiti o wa ni ipo iku ati itaji wọn eyiti o wa ni ipo igbende, o wa sọpe:
أَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا جَعَلۡنَا ٱلَّيۡلَ لِيَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 86
Se awọn opurọ yii ko wa woye si igbende ni wipe awa ni a se oru ki wọn le maa gbe inu rẹ pẹlu oorun, a si se ọsan ni ohun ti ntan imọlẹ ki wọn le baa maa riran nibẹ, ki wọn si tun le ba maa lọ si ibi awọn isẹ wọn, dajudaju nibi iku gbogboogba ati igbende lẹyin jẹ awọn amin ti o fi oju han fun ijọ ti o nigbagbọ.
وَيَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِ فَفَزِعَ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا مَن شَآءَ ٱللَّهُۚ وَكُلٌّ أَتَوۡهُ دَٰخِرِينَ 87
Tun ranti - irẹ ojisẹ -: ọjọ ti Malaika ti a gbeẹsẹ fun yoo fan fere si inu iwo ni ifanfere ẹlẹẹkeji, ti gbogbo eniti o nbẹ ni sanmọ ati ile yii si jaya ayaafi ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba sa lẹsa ninu wọn kuro nibi ipaya; niti sise ọla ni ọdọ Rẹ, bẹẹni gbogbo ẹda Allah yoo wa ba A ni ọjọ naa ni ẹniti yoo maa tẹle E, ti yoo si maa tẹriba fun Un.
وَتَرَى ٱلۡجِبَالَ تَحۡسَبُهَا جَامِدَةٗ وَهِيَ تَمُرُّ مَرَّ ٱلسَّحَابِۚ صُنۡعَ ٱللَّهِ ٱلَّذِيٓ أَتۡقَنَ كُلَّ شَيۡءٍۚ إِنَّهُۥ خَبِيرُۢ بِمَا تَفۡعَلُونَ 88
Iwọ yoo ri oke ni ọjọ naa ti o ro wipe o fi ẹsẹ rinlẹ ti ko nii yira pada sugbọn ni tootọ yoo maa rin niti yarayara ni rinrin ẹsu ojo, isẹ ti Allah ni, Oun ni O si nyi pada, dajudaju olufunni niro idunnu ohun ti ẹ ba se nii se, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori.
Pataki igbarale Allah.
Fifọ anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mọ wipe ori ododo ti o fi oju han ni o wa.
Imọna ise kongẹ wa ni ọwọ Allah, kii se ọwọ ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Titọka oorun si iku ati itaji si igbende.