وَلَقَدۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَسۡرِ بِعِبَادِي فَٱضۡرِبۡ لَهُمۡ طَرِيقٗا فِي ٱلۡبَحۡرِ يَبَسٗا لَّا تَخَٰفُ دَرَكٗا وَلَا تَخۡشَىٰ 77
Paapaa a ti ransẹ imisi si Musa: wipe ki o rinrin oru pẹlu ẹru Mi lati misirọ ti ẹnikankan ko nii fura si wọn, ki o si se oju ọna fun wọn ninu odo ti yoo gbẹ lẹyin igbati o ba fi ọpa na odo ni ẹni ifọkanbalẹ, ki o mase paya wipe fir'aona ati awọn ọmọ ogun rẹ yoo ba ọ, ki o si tun ma paya lati tẹri si inu odo naa.
فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ بِجُنُودِهِۦ فَغَشِيَهُم مِّنَ ٱلۡيَمِّ مَا غَشِيَهُمۡ 78
Bayi ni fir'aona ati awọn ọmọ ogun rẹ ntọpa wọn, bayi ni odo tẹ ẹ ri ati awọn ọmọ ogun rẹ ni itẹri naa ni ẹnikankan ko le mọ paapaa rẹ ayaafi Allah, wọn tẹri lapapọ, wọn si parun, Musa ati awọn ti o wa pẹlu rẹ si la.
وَأَضَلَّ فِرۡعَوۡنُ قَوۡمَهُۥ وَمَا هَدَىٰ 79
Fir'aona sọ awọn ijọ rẹ nu lati ibi keferi ti o se lọsọ fun wọn, o si tan wọn jẹ pẹlu rẹ lati ibi ibajẹ, ko si tọ wọn si oju ọna imọna.
يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ قَدۡ أَنجَيۡنَٰكُم مِّنۡ عَدُوِّكُمۡ وَوَٰعَدۡنَٰكُمۡ جَانِبَ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنَ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰ 80
A si sọ fun awọn ọmọ isirẹli lẹyin igbati a ti la wọn ni ọwọ fir'aona ati awọn ogun rẹ: irẹ ọmọ isirẹli, paapaa a ti la yin kuro nibi ọta yin, a si se adehun fun yin lati ba Musa sọrọ ni abala ọtun kan ninu koto ti o wa ni ẹgbẹ oke tuuri, a si sọkalẹ fun ọ ninu abata naa idẹkun Wa ti o jẹ nkan mimu ti o dun gẹgẹ bi oyin ati ẹyẹ kekere ti ekiri rẹ dun, ti o da gẹgẹbi ẹyẹle.
كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ وَلَا تَطۡغَوۡاْ فِيهِ فَيَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبِيۖ وَمَن يَحۡلِلۡ عَلَيۡهِ غَضَبِي فَقَدۡ هَوَىٰ 81
Ẹ maa jẹ ninu nkan adun ti a se fun yin ninu ounjẹ ti o jẹ ẹtọ, ẹ ma si se kọja ẹnu aala nibi ohun ti a fun yin ni anfaani rẹ lọsi ibi nkan ti a se leewọ fun yin, ki ibinu Mi ma ba sọkalẹ le yin lori, ẹniti ibinu Mi ba sọkalẹ le lori ti parun, o si ti se oriibu aye ati ọrun.
وَإِنِّي لَغَفَّارٞ لِّمَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا ثُمَّ ٱهۡتَدَىٰ 82
Dajudaju Emi si jẹ ọlọpọlọpọ aforijin ati amojukuro fun ẹniti o ba ronu piwada si ọdọ Mi, ti o si nigbagbọ, ti o nse isẹẹre lẹyin igba naa ti o si duro deedee lori ododo.
۞وَمَآ أَعۡجَلَكَ عَن قَوۡمِكَ يَٰمُوسَىٰ 83
Kinii o mu ọ kanju kuro lọdọ ijọ rẹ -irẹ Musa- ti o gbawaju wọn, ti o si fi wọn silẹ si ẹyin wọn?
قَالَ هُمۡ أُوْلَآءِ عَلَىٰٓ أَثَرِي وَعَجِلۡتُ إِلَيۡكَ رَبِّ لِتَرۡضَىٰ 84
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: awọn nii lẹyin mi, wọn yoo ba mi, mo si gbawaju awọn ijọ mi si ọdọ Rẹ ki o le yọnu si mi lori gbigbawaju mi wa si ọdọ Rẹ.
قَالَ فَإِنَّا قَدۡ فَتَنَّا قَوۡمَكَ مِنۢ بَعۡدِكَ وَأَضَلَّهُمُ ٱلسَّامِرِيُّ 85
Ọlọhun Allah sọpe: paapaa awa ti dan awọn ijọ rẹ wo eyiti o fi si ẹyin rẹ pẹlu ijọsin ogedegbe maalu, paapaa samiriyu ti pe wọn lọ si ibi ijọsin rẹ, o si fi eleyi sọ wọn nu.
فَرَجَعَ مُوسَىٰٓ إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ غَضۡبَٰنَ أَسِفٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَمۡ يَعِدۡكُمۡ رَبُّكُمۡ وَعۡدًا حَسَنًاۚ أَفَطَالَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡعَهۡدُ أَمۡ أَرَدتُّمۡ أَن يَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبٞ مِّن رَّبِّكُمۡ فَأَخۡلَفۡتُم مَّوۡعِدِي 86
Bayi ni Musa sẹri pada si ọdọ awọn ijọ niti ibinu si sinsin ogedegbe maalu wọn ni ẹniti o nbanujẹ le wọn lori, Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: ẹyin ijọ mi, se kii se wipe Ọlọhun Ọba Allah se adehun daadaa fun yin lati sọ taoreeta kalẹ fun yin, ki O si fi yin wọ Alujannah, se asiko ti pẹ naa ni ti ẹ fi waa gbagbe? Njẹ ẹ gbero pẹlu oun ti ẹ nse yii ki ibinu sọkalẹ le yin lori lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin, ki iya Rẹ si sẹlẹ le yin lori, tori eleyi ni ẹ fi waa yapa adehun Mi lori ki ẹ tẹle asẹ titi ti maa fi waa sẹri waa ba yin?!
قَالُواْ مَآ أَخۡلَفۡنَا مَوۡعِدَكَ بِمَلۡكِنَا وَلَٰكِنَّا حُمِّلۡنَآ أَوۡزَارٗا مِّن زِينَةِ ٱلۡقَوۡمِ فَقَذَفۡنَٰهَا فَكَذَٰلِكَ أَلۡقَى ٱلسَّامِرِيُّ 87
Awọn ijọ Musa sọpe: a ko yapa adehun rẹ - irẹ Musa - pẹlu yiyan ohun ti a yan laayo yii, taalo ni wa, paapaa a ti gbe eru wiwo ninu nkan ọsọ fir'aona, a si ju u si inu iho ki a le bọpa bọsẹ kuro nibẹ, gẹgẹ bi a se gu u sinu iho naa ni samiriyu ju nkan ti o wa pẹlu rẹ ninu oju patako ẹsẹ ẹsin Jibril ti ọla nbẹ fun.
Ninu isesi Ọlọhun Ọba ni ki o gba ẹsan lara awọn ẹlẹsẹ pẹlu ohun ti yoo mu igbaaya awọn olugbagbọ ododo san, ti yoo si mu itutu ba oju wọn, ti yoo si mu ilekoko ọkan wọn jinna.
Ikọja ẹnu aala jẹ aburu ẹmin rẹ ati si awọn ijọ rẹ; nitoripe o sọ wọn nu kuro nibi imọna, ko si tọ wọn si ibi rere ati ọla.
Idẹkun ko isọ ati ọpẹ eyiti o sọ papọ mọ alekun sinu, bẹẹni jija a niyan ma nsọ ibinu Allah di ẹtọ ati sisọkalẹ rẹ.
Ọlọhun Allah jẹ oluforijinni fun ẹniti o ba ronu piwada kuro nibi ẹbọ ati ẹsẹ, ti o si nigbagbọ pẹlu Rẹ, ti o si nsisẹẹre lẹyin igba naa ti o wa duro le lori titi ti o fi ku.
Dajudaju ikanju koda ki o ja si wipe apapọ ni jẹ nkan eebu, o si jẹ nkan ẹyin nibi ẹsin.