أَوَ لَا يَعۡلَمُونَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَ 77
Awọn Yahuudi yii, wọn ma ntọ oju ọna ti ko dara yii, o da gẹgẹ bi wipe wọn fọnufọra nipa wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Mọ ohun ti wọn nfi pamọ ninu awọn gbolohun wọn ati awọn isẹ wọn, ati eyi ti wọn fi han ninu rẹ, Yoo si fi han fun awọn ẹrusin Rẹ, Yoo si doju ti wọn.
وَمِنۡهُمۡ أُمِّيُّونَ لَا يَعۡلَمُونَ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّآ أَمَانِيَّ وَإِنۡ هُمۡ إِلَّا يَظُنُّونَ 78
O nbẹ ninu awọn yahuudi, ijọ kan ti wọn ko mọ Taoreeta ayaafi kika lasan, ti wọn ko si gbọ agbọye ohun ti ntọka si, ko si nkankan ni ọdọ wọn ayaafi awọn irọ eyiti wọn gba lati ọdọ awọn olori wọn, ti wọn si nlero wipe dajudaju ohun gan ni Taoreeta eyiti Ọlọhun Ọba sọkalẹ.
فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ يَكۡتُبُونَ ٱلۡكِتَٰبَ بِأَيۡدِيهِمۡ ثُمَّ يَقُولُونَ هَٰذَا مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ لِيَشۡتَرُواْ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلٗاۖ فَوَيۡلٞ لَّهُم مِّمَّا كَتَبَتۡ أَيۡدِيهِمۡ وَوَيۡلٞ لَّهُم مِّمَّا يَكۡسِبُونَ 79
Iparun ati iya ti o le koko o nreti awọn wọnyi, awọn ti wọn jẹ wipe wọn ma nkọ tira pẹlu ọwọ wọn, lẹyin igbanaa ni wọn yoo waa sọ wipe - ni irọ pipa - eleyi wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba; ki wọn le ba paarọ ododo ati titẹle imọna pẹlu owo tasọrẹ niti wiwa aye gẹgẹ bi owo ati isejọba, iparun ati iya ti o le koko nbẹ fun wọn lori ohun ti ọwọ wọn kọ yii ninu nkan ti wọn fi nparọ mọ Ọlọhun Ọba, iparun ati iya ti o le koko nbẹ fun wọn lori ohun ti wọn fi ọwọ ara wọn fa lẹyin nkan naa ninu owo ati isejọba.
وَقَالُواْ لَن تَمَسَّنَا ٱلنَّارُ إِلَّآ أَيَّامٗا مَّعۡدُودَةٗۚ قُلۡ أَتَّخَذۡتُمۡ عِندَ ٱللَّهِ عَهۡدٗا فَلَن يُخۡلِفَ ٱللَّهُ عَهۡدَهُۥٓۖ أَمۡ تَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ 80
Wọn si wipe - niti irọ ati ẹtanjẹ -: ina ko lee fi ọwọ ba wa, a ko si nii wọ ayaafi fun awọn ọjọ diẹ, sọ - irẹ Anọbi - fun awọn ẹni yii : se ẹ gba adehun ti o ni ikanpamọ lati ọdọ Ọlọhun Ọba lori nkan naa, ti o ba jẹ wipe nkan naa nbẹ fun yin; dajudaju Ọlọhun Ọba Ko nii yapa adehun Rẹ; tabi ẹyin nsọ nipa Allah - niti irọ ati eke - ohun ti ẹ ko nimọ nipa rẹ?.
بَلَىٰۚ مَن كَسَبَ سَيِّئَةٗ وَأَحَٰطَتۡ بِهِۦ خَطِيَٓٔتُهُۥ فَأُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 81
Ọrọ ko ri bii awọn eleyi se nlero rẹ; dajudaju Ọlọhun Ọba Yoo fi iya jẹ gbogbo ẹniti o ba fi ọwọ rẹ fa aburu sise aimoore; ti ẹsẹ rẹ si yipo rẹ ni gbogbo ọna; Yoo si san wọn lẹsan pẹlu wiwọ ina ati wiwa nibẹ pẹẹ; ni ẹniti yoo maa wa nibẹ lọ gbere.
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 82
Ẹ ko ri awọn ti wọn ba gba Ọlọhun Ọba gbọ ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si se awọn isẹ daradara; ẹsan wọn lọdọ Ọlọhun Ọba ni wiwọ Alujannah ati wiwa nibẹ pẹẹ, ni ẹniti yoo maa bẹ nibẹ lọ gbere.
وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ لَا تَعۡبُدُونَ إِلَّا ٱللَّهَ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَانٗا وَذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَقُولُواْ لِلنَّاسِ حُسۡنٗا وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ ثُمَّ تَوَلَّيۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنكُمۡ وَأَنتُم مُّعۡرِضُونَ 83
Ẹ ranti - ẹyin ọmọ Isirẹli - adehun ti o ni ikanpamọ eyiti A se fun yin; nipa ki e se Ọlọhun Ọba ni ọkan soso, ki ẹ si ma sin nkan miran pẹlu Rẹ, ati ki ẹ maa se daradara si awọn obi mejeeji ati awọn alasunmọ ati awọn ọmọ orukan ati awọn alaini ti wọn ni bukaata; ati ki ẹ maa sọ ọrọ to dara fun awọn eniyan, niti ipasẹ daradara ati kikọ fun ni kuro nibi aburu laini ibinu abi ilekoko ninu, ati ki ẹ si maa ki irun ni pipe lori ojupọnna bi mo se pa yin lasẹ; ati ki ẹ maa yọ zaka pẹlu fifun awọn ti o lẹtọ sii, ni oun ti ẹmi yin dun sii, lẹyin adehun yii eyiti won se pelu yin, nse ni e pa oju da ni ẹniti o gunri kuro nibi pipe adehun pelu re, ayaafi eniti Olohun Allah ko yo ninu yin, ti o si pe adehun pelu re.
Apakan awọn ti wọn fun ni tira, yoo maa pe apemọra nini imọ nipa ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ; ododo si ni wipe, ko si imọ kankan fun un nipa ohun ti Allah sọkalẹ bikose wipe ero ati aimọkan nii.
Ninu awọn eniyan ti ẹsẹ wọn tobi ju, ni ẹniti o ba nparọ mọ Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) ati ojisẹ Rẹ, yoo si maa se afiti si ọdọ wọn, ohun ti ko wa lati ọdọ wọn.
Pẹlu titobi awọn adehun eyiti Ọlọhun Ọba gba lori awọn Yahuudi ati bi o se ni ikanpamọ ti o le, eleyi ko le wọn kun ni nkankan ayaafi gigunri kuro nibẹ ati kikọọ.