أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي كَفَرَ بَِٔايَٰتِنَا وَقَالَ لَأُوتَيَنَّ مَالٗا وَوَلَدًا 77
Njẹ o ri - irẹ ojisẹ - ẹniti o se keferi si awọn ẹri wa, ti o si tako adehun Wa, ti o wa sọpe: ti nba ku, ti wọn si gbe mi dide, wọn yoo fun mi ni dukia ti o pọ ati awọn ọmọ.
أَطَّلَعَ ٱلۡغَيۡبَ أَمِ ٱتَّخَذَ عِندَ ٱلرَّحۡمَٰنِ عَهۡدٗا 78
Se ọ ma kọkọ ni, ni o fi sọ nkan ti o sọ niti didaju?! Tabi o ti gba adehun lọdọ Ọlọhun Ọba wipe yoo mu wọ ọgba idẹra ati wipe yoo fun ni dukia ati awọn ọmọ?!
كَلَّاۚ سَنَكۡتُبُ مَا يَقُولُ وَنَمُدُّ لَهُۥ مِنَ ٱلۡعَذَابِ مَدّٗا 79
Ọrọ ko ri bi o se lero, a o kọ silẹ ohun ti o sọ ati ohun ti o se, a o si se alekun iya fun lori iya rẹ nitori ohun ti o pe apemọra rẹ ninu ibajẹ.
وَنَرِثُهُۥ مَا يَقُولُ وَيَأۡتِينَا فَرۡدٗا 80
A o si jogun ohun ti o gbe ju silẹ ninu dukia ati ọmọ lẹyin igbati a ba pa a run, yoo si pada wa ba Wa ni ọjọ igbende ni oun nikan, ti a o ti jagba lọwọ rẹ ohun ti o fi ngbadun lowo ati iyi.
وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ ءَالِهَةٗ لِّيَكُونُواْ لَهُمۡ عِزّٗا 81
Awọn ẹlẹbọ mu awọn nkan ijọsin fun miran yatọ si Allah?! Ki wọn le ba jẹ alaranse ati oluranlọwọ ti wọn yoo maa wa aranse lọ si ọdọ rẹ.
كَلَّاۚ سَيَكۡفُرُونَ بِعِبَادَتِهِمۡ وَيَكُونُونَ عَلَيۡهِمۡ ضِدًّا 82
Ọrọ ko ri bi wọn se nlero, awọn ti wọn nsin yatọ si Allah yii yoo ja wọn niyan lori ijọsin awọn ẹlẹbọ ni ọjọ igbende, wọn yoo si bọpa bọsẹ kuro ni ọdọ wọn, wọn yoo pada wa jẹ ọta fun wọn.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّآ أَرۡسَلۡنَا ٱلشَّيَٰطِينَ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ تَؤُزُّهُمۡ أَزّٗا 83
Se iwọ ko mọ ni - irẹ ojisẹ - wipe a gbe awọn esu dide, a si fun wọn ni ijẹgaba lori awọn keferi, ti yoo maa gun wọn ni kẹsẹ lọsi bi sise ẹsẹ ati sisẹri kuro nibi ẹsin Allah niti igunni nikẹsẹ?
فَلَا تَعۡجَلۡ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّمَا نَعُدُّ لَهُمۡ عَدّٗا 84
Mase kanju - irẹ ojisẹ - lati wa ikanju iparun wọn lọdọ Allah, dajudaju a nse onka ọjọ ori wọn niti sise onka titi ti ilọnilara wọn yoo fi tan, a o wa fi iya jẹ wọn pẹlu ohun ti wọn lẹtọ si.
يَوۡمَ نَحۡشُرُ ٱلۡمُتَّقِينَ إِلَى ٱلرَّحۡمَٰنِ وَفۡدٗا 85
Tun ranti - irẹ ojisẹ - ni ọjọ igbende ti a o ko awọn olupaya Ọlọhun wọn jọ - pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijina si awọn oun ti O kọ - ni dida wọn lọsi ọdọ Ọlọhun wọn niti apọnle ati iyi.
وَنَسُوقُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ وِرۡدٗا 86
A o si maa da awọn keferi lọsi inu ina jahannamo ni tongbẹ tongbẹ.
لَّا يَمۡلِكُونَ ٱلشَّفَٰعَةَ إِلَّا مَنِ ٱتَّخَذَ عِندَ ٱلرَّحۡمَٰنِ عَهۡدٗا 87
Awọn keferi wọnyi ko nii nikapa ipẹ sise fun apakan wọn ayaafi ẹniti o ba ti gba adehun ni ọdọ Ọlọhun Ọba ni ile aye pẹlu igbagbọ si I ati si awọn ojisẹ Rẹ.
وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَلَدٗا 88
Awọn yahuudi, awọn nasaara ati apakan ninu awọn ẹlẹbọ sọ wipe: Ọba Ajọkẹ Aye ni ọmọ.
لَّقَدۡ جِئۡتُمۡ شَيًۡٔا إِدّٗا 89
Paapaa ẹ ti mu nkan ti o tobi wa - ẹtyin ti ẹ nsọ eleyi -.
تَكَادُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ يَتَفَطَّرۡنَ مِنۡهُ وَتَنشَقُّ ٱلۡأَرۡضُ وَتَخِرُّ ٱلۡجِبَالُ هَدًّا 90
Sanmọ naa fẹ le faya nitori ọrọ ikorira yii, bẹẹni ilẹ naa fẹ le lanu, bakanna ni oke naa fẹ le walẹ ki o si da wo.
أَن دَعَوۡاْ لِلرَّحۡمَٰنِ وَلَدٗا 91
Gbogbo eleyi nitori fifi afiti ọmọ ti si ọdọ Ọba Ajọkẹ Aye, giga Ọlọhun Ọba kuro nibi eleyi niti giga ti o tobi.
وَمَا يَنۢبَغِي لِلرَّحۡمَٰنِ أَن يَتَّخِذَ وَلَدًا 92
Ko si tọ ki Ọba Ajọkẹ Aye ni ọmọ nitori mimọ kanga Rẹ kuro nibẹ.
إِن كُلُّ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ إِلَّآ ءَاتِي ٱلرَّحۡمَٰنِ عَبۡدٗا 93
Gbogbo ounti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ bi Malaika, eniyan ati Alujannu ni wọn yoo wa ni ọjọ igbende si ọdọ Ọlọhun wọn niti itẹriba.
لَّقَدۡ أَحۡصَىٰهُمۡ وَعَدَّهُمۡ عَدّٗا 94
Paapaa imọ Rẹ rikirika wọn, O mọ onka wọn niti mimọ onka, nkankan ko pamọ fun ninu wọn.
وَكُلُّهُمۡ ءَاتِيهِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَرۡدًا 95
Gbogbo ikọọkan wọn ninu wọn ni yoo wa ni ọjọ igbende ni aaso, ko si nii si alaranse fun wọn pẹlu dukia.
Awọn aayah yii ntọka si gigọ keferi ati yiyẹpẹrẹ ironu rẹ ati riran kan rẹ eyiti o jẹ irankan oloyin sugbọn ti o ja si wipe yoo ri idakeji rẹ nigbati o ba di igbagede ọrun.
Ọlọhun Ọba Allah fun awon esu ni ijẹgaba lori awọn keferi pẹlu sisọ wọn nu ati fifi aburu tan wọn jẹ, ati mimu wọn jade kuro nibi itẹle asẹ lọsi ibi ẹsẹ.
Awọn ọlọla ati imọ ati ẹniire wọn yoo ri isipẹ pẹlu iyọnda Allah ni ọjọ igbende.