وَمَا لَكُمۡ لَا تُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلۡوِلۡدَٰنِ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا مِنۡ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلظَّالِمِ أَهۡلُهَا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ نَصِيرًا 75
Kinni ohun ti o kọ fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - kuro nibi igbiyanju si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah nitori giga gbolohun Rẹ, ati lati yọ awọn ọlẹ ninu ọkunrin ati obinrin ati awọn ọmọ keekeeke ti wọn npe Ọlọhun Ọba Allah ni ẹniti nsọ bati wipe: Irẹ Ọlọhun Ọba wa, muwa jade kuri ni Mẹkka nitori abosi awọn ẹni ibẹ, pẹlu sise ẹbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ati kikọja ẹnu aala si awọn ẹru Rẹ, se fun wa lati ọdọ Rẹ ọniti yoo la ọrọ wa bọrun pẹlu akiyesi ati isọ, ati aranse ti yoo ti aburu kuro fun wa.
ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱلطَّٰغُوتِ فَقَٰتِلُوٓاْ أَوۡلِيَآءَ ٱلشَّيۡطَٰنِۖ إِنَّ كَيۡدَ ٱلشَّيۡطَٰنِ كَانَ ضَعِيفًا 76
Awọn olugbagbọ ododo tootọ, wọn jagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah nitori gbigbe gbolohun ga, bẹẹni awọn keferi na njagun si oju ọna ọlọhun ọba wọn, ki ẹ ya gbogun ti awọn oluranlọwọ ẹsu, dajudaju ti ẹ ba gbogun ti wọn, ẹ yoo bori wọn; nitori wipe ete esu jẹ ọlẹ, ko le ko inira ba awọn ti wọn gbe ara le Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga.
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ قِيلَ لَهُمۡ كُفُّوٓاْ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقِتَالُ إِذَا فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ يَخۡشَوۡنَ ٱلنَّاسَ كَخَشۡيَةِ ٱللَّهِ أَوۡ أَشَدَّ خَشۡيَةٗۚ وَقَالُواْ رَبَّنَا لِمَ كَتَبۡتَ عَلَيۡنَا ٱلۡقِتَالَ لَوۡلَآ أَخَّرۡتَنَآ إِلَىٰٓ أَجَلٖ قَرِيبٖۗ قُلۡ مَتَٰعُ ٱلدُّنۡيَا قَلِيلٞ وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لِّمَنِ ٱتَّقَىٰ وَلَا تُظۡلَمُونَ فَتِيلًا 77
Se o ko mọ ni - ire ojise - isesi awọn ẹni rẹ, awọn ti wọn nbeere fun ki wọn se igbiyanju ni ọranyan le wọn lori, wọn wa sọ fun wọn: ẹ ko ọwọ yin kuro nibi ogun jija, ki ẹ si maa gbe irun duro, ki ẹ si maa yọ saka, - o jẹ siwaju ki igbiyanju too di ọranyan - nigbati wọn waa se irin-ajo lọ si Mọdinah, tiidiwọ waa wa fun ẹsin Islam, ti wọn si se ogun jija ni ọranyan; o soro fun apakan wọn, wọn wa npaya awọn eniyan gẹgẹ bi ipaya ti wọn ni fun Ọlọhun Ọba Allah, tabi eyi ti o le ju lọ, wọn wa nsọ wipe: irẹ Ọlọhun Ọba wa, nitori kinni O fi se ogun jija ni ọranyan le wa lori? Oo ya lọ lara fun igba diẹ, ki a le gbadun aye, sọ fun wọn - ire ojise -: igbadun aye bioti wulẹ ki o to, nkan kekere ti yoo yẹ kuro ni, bẹẹni ọrun loore fun ẹniti npaya Ọlọhun Ọba Allah ti o ga, nitori mimaa bẹ lọ gbere idẹkun bẹ, wọn ko si nii din nkankan ku ninu isẹẹre yin, kibaa ma ju odiwọn okun ẹnu eso tamuru lọ.
أَيۡنَمَا تَكُونُواْ يُدۡرِككُّمُ ٱلۡمَوۡتُ وَلَوۡ كُنتُمۡ فِي بُرُوجٖ مُّشَيَّدَةٖۗ وَإِن تُصِبۡهُمۡ حَسَنَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِكَۚ قُلۡ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ فَمَالِ هَٰٓؤُلَآءِ ٱلۡقَوۡمِ لَا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ حَدِيثٗا 78
Ibikibi ti ẹ ba wa, iku yoo pade yin ni igbati asiko yin ba to, koda ki ẹ wa ninu ile ti o jẹ odi isọ ti o jinna fun gbigba ogun laaye, ti o ba de ọdọ awọn sọbẹselu nkan ti o dun wọn ninu ninu ọmọ tabi arisiki ti o pọ, wọn yoo sọ wipe: eleyi wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, sugbọn ilekoko ba kan wọn lati ara ọmọ, tabi arisiki, wọn yoo fi aburu naa ti si ọdọ Anọbi (ti ikẹ ati ọla nbẹ fun) , wọn yoo sọ wipe: aburu yii jẹ titori rẹ, sọ wipe - ire ojise - ni ifesi pada fun awọn eniyan yii: gbogbo irọra ati ẹnira wa pẹlu fifẹ Ọlọhun Ọba Allah ati akọsilẹ Rẹ, kinni o se awọn eniyan wọnyi, awọn ti gbolohun yii njade ni ẹnu wọn, wọn ko fẹẹ gbọ agbọye ọrọ rẹ ti o sọ fun wọn? !
مَّآ أَصَابَكَ مِنۡ حَسَنَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ وَمَآ أَصَابَكَ مِن سَيِّئَةٖ فَمِن نَّفۡسِكَۚ وَأَرۡسَلۡنَٰكَ لِلنَّاسِ رَسُولٗاۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدٗا 79
Ohun ti o tẹ lọwọ - irẹ ọmọ Aadamọ - ninu ohun ti ndun ọ ninu, ni arisiki, ni ọmọ, ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni o ti wa, O fi se ọla fun ọ ni, ohun ti o si tẹ ọ lọwọ ninu ohun ti nba ọ lọkan jẹ, ni arisiki, tabi ọmọ rẹ, ninu ohun ti o ti ọdọ rẹ wa ni, latara ẹsẹ eyi ti o da. Paapaa a ti gbe ọ dide - irẹ Anọbi - si gbogbo eniyan gẹgẹ bi ojisẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ki o mu isẹ Ọlọhun Ọba rẹ de etigbọ wọn, Ọlọhun Ọba Allah tio ni olujẹri si ododo rẹ eyiti o nmu de etigbọ wọn nipa Ọlọhun Ọba Allah, pẹlu ẹri ati awijare ti Ọlọhun fun ọ.
Jijẹ ọranyan jijagun nitori gbigbe gbolohun Ọlọhun Ọba Allah ga ati sise aranse fun awọn ọlẹ, nini aleebu ipaya ati ojo, ati igun ri si awọn idajọ Ọlọhun Ọba Allah.
Ile Ọrun loore ju aye lọ, ati idẹkun ati awọn igbadun bẹ fun ẹniti npaya Ọlọhun Ọba Allah, ti o si nse itẹle asẹ Rẹ
Oore ati aburu, gbogbo rẹ wa pẹlu akọsilẹ Ọlọhun Ọba Allah, paapaa Ọlọhun Ọba Allah le dan awọn ẹru Rẹ wo pẹlu awọn aburu ni ile aye nitori awọn idi kan, ninu rẹ: awọn ẹsẹ wọn ati awọn asise wọn.