وَتَرَى ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ حَآفِّينَ مِنۡ حَوۡلِ ٱلۡعَرۡشِ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡۚ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡحَقِّۚ وَقِيلَ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 75
Awọn Malaaika ni ọjọ yii eyiti a fi oju ri, wọn yoo yipo itẹ naa, wọn yoo maa fọ Allah mọ kuro nibi ohun ti awọn keferi nsọ, Allah yoo si se idajọ laarin gbogbo ẹda pẹlu deedee, yoo se apọnle ẹniti O fẹ pọn le, yoo si fi iya jẹ ẹniti O ba fẹ fi iya jẹ, wọn yoo sọpe: ọpẹ ni fun Allah olutọju gbogbo ẹda lori awọn ọgbọn Rẹ ti o fi se idajọ ninu ikẹ Rẹ fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo ati iya Rẹ fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ keferi.
سورة (MAKIYYAH)
Alaye isesi awọn olujiyan nipa awọn aayah Allah, ati dida esi ọrọ pada fun wọn.
حمٓ 1
(حمٓ) (Aa mim) ọrọ ti gbawaju lori iran iru rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah.
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ 2
Sisọkalẹ Alukuraani fun ojisẹ Rẹ Muhammad - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun - jẹ lati ọdọ Allah alagbara ẹniti ẹnikankan ko le bori Rẹ, Onimimọ nipa awọn anfaani awọn ẹru Rẹ.
غَافِرِ ٱلذَّنۢبِ وَقَابِلِ ٱلتَّوۡبِ شَدِيدِ ٱلۡعِقَابِ ذِي ٱلطَّوۡلِۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ إِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ 3
O jẹ alaforijin gbogbo ẹsẹ dẹsẹdẹsẹ, O si jẹ olugba ironu piwada ẹniti o ba sẹri lọ si ọdọ Rẹ ninu awọn ẹru Rẹ, O jẹ Oniya lile fun ẹniti ko sẹri kuro nibi awọn ẹsẹ rẹ, Onidaadaa ati Olusọla, ẹni ijọsin fun tootọ ko si yatọ si I, ọdọ Rẹ nikan ni ibusẹri si awọn ẹru ni ọjọ igbende, yoo si san wọn lẹsan ohun ti wọn lẹtọ si.
مَا يُجَٰدِلُ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَا يَغۡرُرۡكَ تَقَلُّبُهُمۡ فِي ٱلۡبِلَٰدِ 4
Ẹnikan ko nii ma ja si awọn aayah Allah ti o ntọka si ijọkan soso Rẹ ati gbigba awọn ojisẹ Rẹ lododo ayaafi awọn ti wọn se keferi si Allah nitori ibajẹ laakaye wọn, mase banujẹ le wọn lori, masi se gba itanjẹ pẹlu titẹ arisiki ati idẹkun silẹ ti o nbẹ fun wọn, lilọ wọn lara jẹ idẹnilẹkẹ ati ete si wọn.
كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۖ وَهَمَّتۡ كُلُّ أُمَّةِۢ بِرَسُولِهِمۡ لِيَأۡخُذُوهُۖ وَجَٰدَلُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّ فَأَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ عِقَابِ 5
Ijọ Nuha ti parọ siwaju awọn wọnyi, lẹyin ijọ Nuha awọn ijọ miran naa ti parọ siwaju wọn, Haadi naa parọ, Samuudu naa parọ ati ijọ Luuth ati awọn eniyan Madiyana, fir'aona naa si parọ, gbogbo ijọ ni o gbero ninu awọn ijọ si ojisẹ rẹ lati gba a mun, ki o si pa a, wọn si ja ibajẹ ti o nbẹ lọdọ wọn niyan, ki wọn le mu ododo yẹ kuro, gbogbo awọn ijọ ni wọn gbamu lapapọ, ki o ya ronu bawo ni iya Mi yoo se ri fun wọn, paapaa yoo jẹ iya ti o le koko.
وَكَذَٰلِكَ حَقَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ 6
Gẹgẹbi Allah se dajọ iparun fun awọn ijọ opurọ naa, gbolohun Ọlọhun Ọba rẹ di dandan - irẹ ojisẹ - lori awọn ti o se keferi wipe dajudaju ẹni ina ni wọn.
ٱلَّذِينَ يَحۡمِلُونَ ٱلۡعَرۡشَ وَمَنۡ حَوۡلَهُۥ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيُؤۡمِنُونَ بِهِۦ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْۖ رَبَّنَا وَسِعۡتَ كُلَّ شَيۡءٖ رَّحۡمَةٗ وَعِلۡمٗا فَٱغۡفِرۡ لِلَّذِينَ تَابُواْ وَٱتَّبَعُواْ سَبِيلَكَ وَقِهِمۡ عَذَابَ ٱلۡجَحِيمِ 7
Awọn Malaaika ti wọn ngbe itẹ Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - ati awọn ti o nbẹ lẹgbẹ rẹ, wọn sne afọmọ Ọlọhun wọn kuro nibi ohun ti ko lẹtọ si I, wọn si gba A gbọ, wọn si nwa aforijin fun awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ni ẹniti wọn nsọ ninu adera wọn: Ọlọhun wa, imọ Rẹ ati ikẹ Rẹ gbaaye lori gbogbo nkan, fi ori jin awọn ti o sẹri pada kuro nibi awọn ẹsẹ wọn, ti wọn si tẹle ẹsin Rẹ, la wọn ki iya ina mase gba wọn mu.
Sise apapọ laarin iseni loju kokoro si ikẹ Allah ati ikilọ fun ni kuro nibi ilekoko iya Rẹ: jẹ ọna ti o dara.
Yinyin Allah pẹlu mimu U lọkan soso ati sise afọmọ didupẹ fun Un jẹ ẹkọ kan ninu awọn ẹkọ adura.
Apọnle olugbagbọ ododo wa ni ọdọ Allah; nitoripe O rọ awọn Malaaika ti wọn nwa aforijin fun un.