۞وَلَوۡ رَحِمۡنَٰهُمۡ وَكَشَفۡنَا مَا بِهِم مِّن ضُرّٖ لَّلَجُّواْ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ 75
Ti a ba kẹ wọn, ti a si mu ọda ati ebi kuro fun wọn, wọn ko ba maa ba niso nibi ọna anu wọn kuro nibi ododo, ti wọn yoo maa lọ maa bọ, ti wọn yoo si maa ti ẹsẹ bọ ẹsẹ.
وَلَقَدۡ أَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡعَذَابِ فَمَا ٱسۡتَكَانُواْ لِرَبِّهِمۡ وَمَا يَتَضَرَّعُونَ 76
Paapa a ti se idanwo fun wọn pẹlu oniranran awọn adanwo, bẹẹni wọn ko rọ fun Ọlọhun Ọba wọn, wọn ko si tẹriba fun Un, wọn si maa pe ni ẹniti o npaya ki o mu awọn adanwo naa kuro fun wọn.
حَتَّىٰٓ إِذَا فَتَحۡنَا عَلَيۡهِم بَابٗا ذَا عَذَابٖ شَدِيدٍ إِذَا هُمۡ فِيهِ مُبۡلِسُونَ 77
Titi ti a fi si oju ọna kan ninu awọn iya ti o le fun wọn nigbati wọn ti ja kan kuro nibi isipaya ati oore. Nigbati itako igbende ko nii sẹlẹ lọdọ ẹniti o ba nse anfaani pẹlu gbigbọ rẹ ati iriran rẹ ati laakaye rẹ, Ọlọhun Ọba Allah ran wọn leti idẹkun ti o se le wọn lori lati ara rẹ, O si sọpe:
Nigbati itako igbende ko nii sẹlẹ lọdọ ẹniti o ba nse anfaani pẹlu gbigbọ rẹ ati iriran rẹ ati laakaye rẹ, Ọlọhun Ọba Allah ran wọn leti idẹkun ti o se le wọn lori lati ara rẹ, O si sọpe:
وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنشَأَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفِۡٔدَةَۚ قَلِيلٗا مَّا تَشۡكُرُونَ 78
Allah ti mimọ nbẹ fun si ni Ẹniti O da yin -ẹyin olupe ijinde nirọ- igbọran ki ẹ le maa fi gbọ ọrọ ati iriran ki ẹ le maa fi riran ati awọn ọkan ki ẹ le ma fi ronu, sugbọn pẹlu eleyi naa ẹ kii dupẹ fun Un lori idẹkun ayaafi ni igba kekere.
وَهُوَ ٱلَّذِي ذَرَأَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَإِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ 79
O nni ẹniti o da yin - ẹyin eniyan - ni ori ilẹ, ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o si kojọ si fun isiro ati ẹsan ni ọjọ igbende.
وَهُوَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُ وَلَهُ ٱخۡتِلَٰفُ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 80
Oun nikan ti mimọ nbẹ fun ni ẹniti O nji ni, ko si olutaniji yatọ si I, Oun nikan si ni ẹniti o npani, ko si olupani yatọ si I, ọdọ Rẹ nikan si ni pipa ebubu yiyapa oru ati ọsan, niti sisookun ati titan imọlẹ ati gigun ati kikuru, se ẹ ko se laakaye si agbara rẹ ni, ati sise aaso Rẹ nibi idẹda ati sise eto?!
بَلۡ قَالُواْ مِثۡلَ مَا قَالَ ٱلۡأَوَّلُونَ 81
Bikosepe wọn sọ iru ohun ti awọn baba wọn yi ati ẹniti o ti siwaju wọn ninu keferi.
قَالُوٓاْ أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ 82
Wọn nsọ ọ ni ojupọnna imunisin ati atako: wipe ti a ba ku, ti a si di yeepẹ ati eegun ti o ti kẹfun, se wọn yoo gbe wa dide ni alaaye fun isiro bi?!
لَقَدۡ وُعِدۡنَا نَحۡنُ وَءَابَآؤُنَا هَٰذَا مِن قَبۡلُ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 83
Paapa a ti se adehun eyi - ohun si ni ajibde lẹyin iku -, wọn si ti se adehun yi fun awọn ti o ti siwaju wa, a ko si ri adehun yi ni ohun ti o ni imusẹ, eleyi ko jẹ nkankan ju ibajẹ awọn ẹni isaaju ati irọ wọn lọ.
قُل لِّمَنِ ٱلۡأَرۡضُ وَمَن فِيهَآ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 84
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn keferi olutako ijinde yii: ti taani ilẹ yii ati ohun ti o nbẹ ni ori rẹ ti ẹ ba ni imọ?
سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ 85
Wọn yoo sọ wipe: ilẹ ati ohun ti o nbẹ ni ori rẹ jẹ ti Allah ki o sọ fun wọn: se ẹ ko ranti ni wipe dajudaju ẹniti o ni ilẹ ati ohun ti o wa nibẹ lagbara lori tita yin ji lẹyin iku yin?
قُلۡ مَن رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ ٱلسَّبۡعِ وَرَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡعَظِيمِ 86
Sọ fun wọn: taani o ni sanmọ mejeeji? Taani o ni laarasi ti o tobi ju, ti ko si si ẹda ti o tobi to?
سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ أَفَلَا تَتَّقُونَ 87
Wọn yoo sọ wipe: sanmọ mejeeje ati al'arashi ti o tobi jẹ ti Allah, ki o sọ fun wọn: ẹ ko paya Allah ni pẹlu mimu awọn ẹsẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti O kọ, ki ẹ le ba la kuro nibi ijiya Rẹ?
قُلۡ مَنۢ بِيَدِهِۦ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيۡءٖ وَهُوَ يُجِيرُ وَلَا يُجَارُ عَلَيۡهِ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 88
Sọ fun wọn: taani ikapa gbohbo nkan nbẹ ni ọwọ rẹ, ti nkankan ko le tayọ kuro nibi ọla Rẹ, Oun ni ẹniti o nran ẹniti o ba wu U ninu ẹru Rẹ lọwọ, ko si ẹniti o le kọ fun ẹniti O ba gbero aburu ro, ti yoo si mu iya kuro fun un ti ẹ ba ni imọ.
سَيَقُولُونَ لِلَّهِۚ قُلۡ فَأَنَّىٰ تُسۡحَرُونَ 89
Wọn yoo sọ wipe: ikapani gbogbo nkan wa ni ọwọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun Un, ki o sọ fun wọn: bawo ni laakaye yin se waa lọ, ti ẹ wa nsin ohun ti o yatọ si I, ti ẹ si tun fi eleyi rinlẹ?!
Aiwoye awọn keferi si idẹkun tabi ijiya eyiti o nsẹlẹ le wọn lori jẹ itọka lori bibajẹ adamọ wọn.
Sise aimoore idẹkun jẹ iroyin kan ninu iroyin awọn keferi.
Gbigba ikọse ifọju mu ma nkọ fun ni lati de ibi ododo.
Fifi itọju rinlẹ laisi fifi ẹniti ijọsin fun rinlẹ ko le la ẹni naa.