۞قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكَ إِنَّكَ لَن تَسۡتَطِيعَ مَعِيَ صَبۡرٗا 75
khadiru sọ fun Musa ẹniti ọla nbẹ fun: dajudaju emi ti sọ fun ọ: dajudaju iwọ - irẹ Musa - o ko nikapa suuru lori ohun ti mo ba se.
قَالَ إِن سَأَلۡتُكَ عَن شَيۡءِۢ بَعۡدَهَا فَلَا تُصَٰحِبۡنِيۖ قَدۡ بَلَغۡتَ مِن لَّدُنِّي عُذۡرٗا 76
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: ti mo ba beere nkankan kan lẹyin igba yii, ki o pinya pẹlu mi, paapaa o ti de ogongo nibi awijare re nibi gbigbe ibasepọ mi ju silẹ; nitoripe mo yapa asẹ rẹ ni igba meji.
فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَآ أَتَيَآ أَهۡلَ قَرۡيَةٍ ٱسۡتَطۡعَمَآ أَهۡلَهَا فَأَبَوۡاْ أَن يُضَيِّفُوهُمَا فَوَجَدَا فِيهَا جِدَارٗا يُرِيدُ أَن يَنقَضَّ فَأَقَامَهُۥۖ قَالَ لَوۡ شِئۡتَ لَتَّخَذۡتَ عَلَيۡهِ أَجۡرٗا 77
Wọn bẹrẹ si nii lọ titi ti wọn fi de ọdọ awọn ara abule kan, wọn si beere onjẹ lọdọ wọn bayi ni awọn ara abule naa kọ lati fun wọn ni ounjẹ ati sise ẹtọ alejo fun wọn, wọn wa ri ogiri kan ni abule ti o fẹ yẹ, ti o ti sun mọ lati wo, ki o si subu lulẹ, bayi ni kadiru waa gbe naro lati gbe e dide, Musa ẹniti ọla nbẹ fun wa sọ fun kadiru: ti o ba fẹ gba owo ọya lori titunse rẹ, ki o kuku gba; nitoripe a ni bukaata si lẹyin igbati wọn ti kọ lati se wa ni alejo.
قَالَ هَٰذَا فِرَاقُ بَيۡنِي وَبَيۡنِكَۚ سَأُنَبِّئُكَ بِتَأۡوِيلِ مَا لَمۡ تَسۡتَطِع عَّلَيۡهِ صَبۡرًا 78
Khadir sọ fun Musa: itako yii lori aigba owo ọya nipa gbigbe ogiri dide ni yoo jẹ aaye onpinya laarin emi ati iwọ, emi yoo fun ọ niro alaye ohun ti o ko le se suuru rẹ ninu ohun ti o nri pẹlu mi.
أَمَّا ٱلسَّفِينَةُ فَكَانَتۡ لِمَسَٰكِينَ يَعۡمَلُونَ فِي ٱلۡبَحۡرِ فَأَرَدتُّ أَنۡ أَعِيبَهَا وَكَانَ وَرَآءَهُم مَّلِكٞ يَأۡخُذُ كُلَّ سَفِينَةٍ غَصۡبٗا 79
Se ori ọkọ oju omin eyiti o tako mi lori fifi apa si lara; o jẹ ti awọn ọlẹ kan ti wọn nsisẹ lori omin, ti wọn ko si nikapa lati daabobo o, mo wa gbero ki o ni aleebu lara pẹlu ohun ti mo se si i; titi ọba ti o wa niwaju lati jẹ gaba lori gbigba gbogbo ọkọ oju omin ti o dara ni agidi lọwọ awọn ti wọn ni i, ti o si ma ngbe gbogbo ọkọ oju omin ti o ni aleebu lara ju silẹ.
وَأَمَّا ٱلۡغُلَٰمُ فَكَانَ أَبَوَاهُ مُؤۡمِنَيۡنِ فَخَشِينَآ أَن يُرۡهِقَهُمَا طُغۡيَٰنٗا وَكُفۡرٗا 80
Sugbọn arakunrin eyiti o tako mi lori gbigba ẹmin rẹ, awọn obi rẹ mejeeji jẹ olugbagbọ ododo, o si wa ninu imọ Ọlọhun Ọba wipe keferi ni, a wa npaya wipe ti o ba dagba o le gbe awọn mejeeji di keferi si Allah ati ki awọn ifẹ ti awọn mejeeji ni si i ma ba kọ ẹnu aala ati ki bukaata wọn si i ma ba kọja ẹnu aala.
فَأَرَدۡنَآ أَن يُبۡدِلَهُمَا رَبُّهُمَا خَيۡرٗا مِّنۡهُ زَكَوٰةٗ وَأَقۡرَبَ رُحۡمٗا 81
A wa ngbero ki Ọlọhun Allah fi ọmọ miran ti o loore julọ lẹsin, ni daadaa ati ni mimọra kuro ni bi ẹsẹ ati eyiti yoo sun mọ ikẹ awọn obi rẹ mejeeji julọ.
وَأَمَّا ٱلۡجِدَارُ فَكَانَ لِغُلَٰمَيۡنِ يَتِيمَيۡنِ فِي ٱلۡمَدِينَةِ وَكَانَ تَحۡتَهُۥ كَنزٞ لَّهُمَا وَكَانَ أَبُوهُمَا صَٰلِحٗا فَأَرَادَ رَبُّكَ أَن يَبۡلُغَآ أَشُدَّهُمَا وَيَسۡتَخۡرِجَا كَنزَهُمَا رَحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَۚ وَمَا فَعَلۡتُهُۥ عَنۡ أَمۡرِيۚ ذَٰلِكَ تَأۡوِيلُ مَا لَمۡ تَسۡطِع عَّلَيۡهِ صَبۡرٗا 82
Sugbọn ogiri eyiti mo tun se ti o si ta ko mi lori titunse rẹ jẹ ti awọn ọmọ keekeke meji ninu inu eyiti a de ibẹ ti baba awọn mejeeji si ti ku, bẹẹni owo ti wọn ri mọlẹ si wa ni abẹ ogiri naa fun wọn, baba awọn ọmọ keekeeke mejeeji si jẹ ẹniire, bayi ni Ọlọhun rẹ gbero - irẹ Musa - ki awọn mejeeji de ọjọ ori ọgbọn ati agba, ki wọn le mu dukia awọn mejeeji ti wọn ti se jade; nigbati o jasi wipe ti ogiri naa ba subu nisinyii, owo awọn mejeeji yoo hande, yoo si sẹri sibi iralare, sise eto yii jẹ ikẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ fun awọn mejeeji eyiti mo si se ninu igbiyanju mi ni; eleyi alaye nkan ti o ko le se suuru rẹ.
Nigbati Ọlọhun Allah sọ itan kadiru, O si tun sọ itan Dhul-Qarnayn nitori asopọ ti nbẹ laarin mejeeji; nitoripe ikini keji wọn wa lori idaabobo awọn ti ko lagbara, O wa sọpe:
وَيَسَۡٔلُونَكَ عَن ذِي ٱلۡقَرۡنَيۡنِۖ قُلۡ سَأَتۡلُواْ عَلَيۡكُم مِّنۡهُ ذِكۡرًا 83
Awọn ẹlẹbọ ati awọnm yahuudi yoo bi ọ leere - irẹ ojisẹ - ni ẹniti yoo dan ọ wo nipa iro ẹni Kọrnayn sọpe: maa ka fun yin nipa iro rẹ abala kan ti ẹ o woye si, ti ẹ o si maa ranti.
Jijẹ dandan sise pẹlẹpẹlẹ ati mimọ amọdaju ati ainima gbawaju lọsi ibi sise idajọ lori ohunkihun.
Dajudaju awọn alamọri idajọ rẹ yoo maa lọ lori bi o ba se hande, wọn yoo si so pọ mọ awọn idajọ aye lori awọn dukia ati ẹjẹ ati ohun ti o yatọ si i.
Gigunle aburu kekere ma nti aburu ti o tobi danu, wọn ma nkiye si eyiti o ba ni anfaani ju pẹlu ki eyiti o kere rẹ bọ.
O tọ fun ọrẹ ki o ma fi ẹnikeji rẹ silẹ tabi gbe ibasepọ ju silẹ titi yoo fi bu u tabi wi awijare lọdọ rẹ.
Lilo ẹkọ pẹlu Allah ti o ga nibi awọn gbolohun pẹlu sise afiti daadaa si ọdọ Rẹ, ki a si mase afiti aburu si I lọdọ.
Dajudaju ẹru rere Ọlọhun Ọba Allah yo maa sọ ọ, yoo si tun maa sọ awọn arọmọdọmọ rẹ.