۞وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ ءَازَرَ أَتَتَّخِذُ أَصۡنَامًا ءَالِهَةً إِنِّيٓ أَرَىٰكَ وَقَوۡمَكَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 74
Ranti - ire ojise - nigbati Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun baba rẹ ẹlẹbọ Haṣarọ: irẹ baba mi, se oosa ni iwọ yoo maa sin ni yatọ si Allah? ! Mo ri iwọ ati ijọ rẹ ti ẹ nsin oosa ni oju ọna anu ti o fi oju han, idaamu kuro nibi oju ọna ododo nitori sinsin ohun ti o yats si Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba Allah nikan ti mimọ nbẹ fun ni ẹniti a njọsin fun niti ododo, sugbọn sinsin ẹniti o yatọ sii jẹ ibajẹ.
وَكَذَٰلِكَ نُرِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ مَلَكُوتَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلِيَكُونَ مِنَ ٱلۡمُوقِنِينَ 75
Gẹgẹ bi a se fi ninu baba rẹ ati ijọ rẹ han an, a tun fi ijọba sanmọ ati ilẹ ti o gbaaye han an, ki ọla ti o gbaaye naa le maa jẹri si ijọkan soso Ọlọhun Ọba Allah, ati lilẹtọ si ijọsin fun Oun nikan, ki o le ba wa ninu awọn ti o ni amọdaju wipe Ọlọhun Ọba Allah ọkan soso ni, ko si orogun fun Un, ati wipe O ni agbara lori gbogbo nkan.
فَلَمَّا جَنَّ عَلَيۡهِ ٱلَّيۡلُ رَءَا كَوۡكَبٗاۖ قَالَ هَٰذَا رَبِّيۖ فَلَمَّآ أَفَلَ قَالَ لَآ أُحِبُّ ٱلۡأٓفِلِينَ 76
Nigbati ilẹ su ba a, o ri irawọ, o wa sọ wipe: eleyi ni Ọlọhun mi, nigbati irawọ pamọ, o sọ pe, nko nifẹ si ẹniti yoo maa pamọ; tori wipe Ọlọhun Ọba ododo yoo maa bẹ ni, ko nii maa pamọ.
فَلَمَّا رَءَا ٱلۡقَمَرَ بَازِغٗا قَالَ هَٰذَا رَبِّيۖ فَلَمَّآ أَفَلَ قَالَ لَئِن لَّمۡ يَهۡدِنِي رَبِّي لَأَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلضَّآلِّينَ 77
Nigbati o ri osupa ti o yọ, o sọ wipe: eleyi ni Ọlọhun Ọba mi, nigbati o pamọ, o sọ wipe: ti Ọlọhun Ọba mi ko ba fi mi mọ ijọkan soso Rẹ ati mima jọsin fun Un laaso, emi yoo wa ninu awọn ijọ ti o jinna si ẹsin ododo.
فَلَمَّا رَءَا ٱلشَّمۡسَ بَازِغَةٗ قَالَ هَٰذَا رَبِّي هَٰذَآ أَكۡبَرُۖ فَلَمَّآ أَفَلَتۡ قَالَ يَٰقَوۡمِ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ 78
Nigbati o ri oorun ti o yọ, o sọ wipe: eyiti o yọ yii ni Ọlọhun mi, eleyi ti o yọ yii tobi ju irawọ ati osupa lọ, nigbati o pamọ, o sọ wipe: ẹyin ijọ mi, mo bọpa-bọsẹ kuro nibi ohun ti ẹ nse ẹbọ rẹ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah.
Nigbati o bọpa-bọsẹ kuro nibi ohun ti wọn nsin yatọ si Allah, o da bi eni wipe wọn bi leere: ki ni o waa fẹ maa sin gan an? O sọ wipe:
إِنِّي وَجَّهۡتُ وَجۡهِيَ لِلَّذِي فَطَرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ حَنِيفٗاۖ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ 79
Mo se afọmọ ẹsin mi fun ẹniti o da sanmọ ati ilẹ laisi apejuwe Rẹ siwaju, ni ẹniti o yẹra kuro nibi ẹbọ lọ si ibi ọkan soso Ọlọhun Ọba Allah nikan, emi ko si ninu awọn ọlọsẹbọ ti wọn nsin nkan miran mọ Ọlọhun Ọba Allah.
وَحَآجَّهُۥ قَوۡمُهُۥۚ قَالَ أَتُحَٰٓجُّوٓنِّي فِي ٱللَّهِ وَقَدۡ هَدَىٰنِۚ وَلَآ أَخَافُ مَا تُشۡرِكُونَ بِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَشَآءَ رَبِّي شَيۡٔٗاۚ وَسِعَ رَبِّي كُلَّ شَيۡءٍ عِلۡمًاۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ 80
Awọn ijọ ọlọsẹbọ baa ja nibi mimu Ọlọhun Ọba Allah lọkan soso, wọn fi oosa wọn dẹru ba a, o wa sọ fun wọn wipe: se ẹ o maa ba mi nibi mimọ Ọlọhun Ọba Allah lọkan soso ati sise ni aaso nibi ijọsin, Ọlọhun Ọba mi ti tọ mi sọna ni ibẹ, emi ko paya ẹbọ yin kankan, toripe wọn ko lagbara inira kankan ti wọn le fi se mi, tabi idẹkun kan ti wọn le fi se mi ni anfaani, ayaafi ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ, ohun ti O ba fẹ ni o ma nri bẹẹ nitori imọ Ọlọhun Ọba Allah kari gbogbo nkan, nkan ko pamọ fun ninu ilẹ ati sanmọ, se ẹ ko se iranti ni, - ẹyin ijọ mi - ori ki ni ẹ tun wa lori sise keferi si Ọlọhun Ọba Allah ati ẹbọ siI, se ẹ ko nii gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ ni Oun nikan soso ni? !
وَكَيۡفَ أَخَافُ مَآ أَشۡرَكۡتُمۡ وَلَا تَخَافُونَ أَنَّكُمۡ أَشۡرَكۡتُم بِٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ عَلَيۡكُمۡ سُلۡطَٰنٗاۚ فَأَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ أَحَقُّ بِٱلۡأَمۡنِۖ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 81
Bawo ni maa se waa maa pawa nkan ti ẹ nsin ninu oosa, ti ẹyin ko si paya Ọlọhun Ọba Allah nitori wipe ẹ nse ẹbọ pẹlu Rẹ lori awọn nkan ti o da laisi awijare fun yin lori rẹ? ! E wo ni ikojọpọ meji yii: kiko awọn ti wọn mu Ọlọhun lọkan pọ ati kiko awọn ọsẹbọ pọ, ewo ni o lẹtọ si ifọkanbalẹ ati alaafia? Ti ẹ ba mọ eyiti o lọla ju, ki ẹ yaa tẹlee, sugbọn eyiti o lọla ju ninu wọn –laisi iyemeji- ohun ni akojọ awọn olugbagbọ ododo ti wọn mu Ọlọhun Ọba Allah lọkan.
Wiwa ẹri lori rire ti Ọlọhun Ọba Allah re gbogbo ẹda wa nibi wiwo awọn ẹda ti Ọlọhun Ọba Allah da, o jẹ ojupọnna Alukuraani.
Ẹri laakaye ti o yanju le muni de ibi itọju Ọlọhun Ọba Allah.