Nigbati Allah sọ ẹsan awọn olupaya, O tun sọ ẹsan idakeji wọn ninu awọn ẹlẹsẹ, O sọpe:
إِنَّ ٱلۡمُجۡرِمِينَ فِي عَذَابِ جَهَنَّمَ خَٰلِدُونَ 74
Dajudaju awọn ẹlẹsẹ lati ibi sise keferi ati awọn ẹsẹ dida yoo wa ninu iya jahannamọ ni ọjọ igbende, wọn yoo si ma gbe ibẹ gbere.
لَا يُفَتَّرُ عَنۡهُمۡ وَهُمۡ فِيهِ مُبۡلِسُونَ 75
Wọn ko nmii fuyẹ iya fun wọn, wọn yoo si wa nibẹ ni olujakan kuro nibi ikẹ Allah.
وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُواْ هُمُ ٱلظَّٰلِمِينَ 76
A ko se abosi wọn nigbati a fi wọn wọ si inu ina, sugbọn awọn ni wọn jẹ olusabosi fun ẹmin ara wọn lati ibi keferi sise.
وَنَادَوۡاْ يَٰمَٰلِكُ لِيَقۡضِ عَلَيۡنَا رَبُّكَۖ قَالَ إِنَّكُم مَّٰكِثُونَ 77
Wọn yoo pe olumojuto ina tii se Malik ni ẹniti o nsọpe: irẹ Malik, ki Ọlọhun rẹ kuku pa wa ki a le sin mi kuro nibi iya naa, Malik yoo wa fesi fun wọn pẹlu gbolohun rẹ: dajudaju ẹyin yoo maa wa ninu iya gbere lailai ti ẹ ko nii ku, iya ko si nii ja kuro fun yin.
لَقَدۡ جِئۡنَٰكُم بِٱلۡحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَكُمۡ لِلۡحَقِّ كَٰرِهُونَ 78
Paapaa a ti mo ododo wa ba yin ni ile aye ti ko si iyemeji nibẹ sugbọn ọpọ yin jẹ olukorira ododo.
أَمۡ أَبۡرَمُوٓاْ أَمۡرٗا فَإِنَّا مُبۡرِمُونَ 79
Ti wọn ba dete si anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ti wọn si mura ete fun un, dajudaju awa ni a o se idajọ fun wọn pẹlu didari eto ti yoo bori ete wọn.
أَمۡ يَحۡسَبُونَ أَنَّا لَا نَسۡمَعُ سِرَّهُمۡ وَنَجۡوَىٰهُمۚ بَلَىٰ وَرُسُلُنَا لَدَيۡهِمۡ يَكۡتُبُونَ 80
Tabi wọn nlero wipe awa ko gbọ kọkọ wọn eyiti wọn fi pamọ si inu ọkan wọn ni, tabi kọkọ wọn eyiti wọn nsọ jade ni kẹlẹkẹlẹ, ọrọ ko ri bẹẹ, dajudaju awa gbọ gbogbo eleyi, bbẹni awọn malaika si nkọ gbogbo ohun ti wọn se silẹ lọdọ wọn.
قُلۡ إِن كَانَ لِلرَّحۡمَٰنِ وَلَدٞ فَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡعَٰبِدِينَ 81
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ti o nse afiti ọmọbinrin si ọdọ Allah, Allah ga ju gbolohun wọn yii lọ ni giga ti o tobi: ko si ọmọ fun Allah; o mọ kuro nibi eleyi, O si mọ kanga, emi ni akọkọ awọn olujọsin fun Allah ti O ga, awọn oluse afọmọ fun Un.
سُبۡحَٰنَ رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ رَبِّ ٱلۡعَرۡشِ عَمَّا يَصِفُونَ 82
Ọba ti O ni gbogbo sanmọ ati ilẹ mọ kanga, Oun ni Ọba itẹ naa kuro nibi ohun ti awọn ẹlẹbọ nsọ nipa fif akẹgbẹ ati ọrẹ ati ọmọ ti si ọdọ Rẹ.
فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ 83
Fi wọn silẹ - irẹ ojisẹ - ki wọn tẹri sinu ibajẹ ti wọn wa lori rẹ, ki wọn si mu sere titi wọn yoo fi pade ọjọ wọn ti wọn se ni adehun fun wọn, ohun si ni ọjọ igbende.
وَهُوَ ٱلَّذِي فِي ٱلسَّمَآءِ إِلَٰهٞ وَفِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَٰهٞۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ 84
Oun ti mimọ nbẹ fun ẹniti a njọsin fun ni sanmọ pẹlu ododo, Oun naa si ni ẹniti a njọsin fun ni ilẹ pẹlu ododo, Oun si ni ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati idari eto Rẹ, onimimọ nipa isesi awọn ẹru Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ.
وَتَبَارَكَ ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 85
Daadaa Ọlọhun Ọba Allah nlekun bẹẹni ibukun Rẹ ti mimọ nbẹ fun naa, ẹniti Oun nikan nikapa gbogbo sanmọ ati ikapa ilẹ ati ikapa ohun ti o wa laarin mejeeji, ọdọ Rẹ nikan si ni imọ asiko ikẹyin wa eyiti igbende yoo to nibẹ, ẹlomiran ko mọ ọ, ọdọ Rẹ nikan si ni ẹ o sẹri si ni ọrun fun isiro ati ẹsan.
وَلَا يَمۡلِكُ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِ ٱلشَّفَٰعَةَ إِلَّا مَن شَهِدَ بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ 86
Awọn ti awọn ẹlẹbọ nsin yatọ si Allah ko nikapa isipẹ ni ọdọ Allah ayaafi ẹniti o ba jẹri pe ko si ọba kan ayaafi Allah, ti o si nimọ nipa ohun ti o jẹri; gẹgẹ bbi Isa ati husayr ati awọn malaika.
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَهُمۡ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ 87
Ti o ba bi wọn leere: taani o da wọn? Paapaa wọn yoo sọpe: Allah ni O da wa, bawo ni wọn se wa ngbe ijọsin Rẹ lẹyin ijẹwọ yii?!
وَقِيلِهِۦ يَٰرَبِّ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ قَوۡمٞ لَّا يُؤۡمِنُونَ 88
Ọdọ Rẹ nikan ti mimọ nbẹ fun ni imọ ikegbajari ojisẹ Rẹ lori irọ awọn ijọ Rẹ wa, gbolohun rẹ nibẹ: irẹ Ọlọhun mi, dajudaju awọn ijọ wọnyii ko nigbagbọ pẹlu ohun ti ẹ fi ran mi si wọn.
فَٱصۡفَحۡ عَنۡهُمۡ وَقُلۡ سَلَٰمٞۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ 89
Ki o ya gunri kuro ni ọdọ wọn, ki o si wọn ohun ti iwọ yoo fi ti aburu wọn danu - eleyi si jẹ ni ilu Mẹkkah - wọn yo pada mọ ohun ti wọn yoo ba pade ninu iya.
Kikorira ododo jẹ ewu ti o tobi.
Ete awọn keferi yoo pada si ọdọ wọn ki baa se lẹyin asiko pipẹ.
Gbogbo igbati imọ ẹru ba nlekun nipa Ọlọhun Ọba rẹ ni igbarale Ọlọhun rẹ na yoo lekun ati ijupa jusẹ silẹ fun ofin rẹ.
Jijẹ aaso nibi imọ asiko ikẹyin fun Allah.