يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ جَٰهِدِ ٱلۡكُفَّارَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱغۡلُظۡ عَلَيۡهِمۡۚ وَمَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ 73
ire ojise, ja awọn keferi logun pẹlu fifi ida pa wọn, ki o si ja awọn sọbẹ selu logun pẹlu ahọn ati awijare, ki o si le mọ ipin kini-keji; toripe wọn lẹtọ si i, ibusẹri si wọn ni ọjọ igbende jẹ jahannamo, ibusẹrisi wọnyi buru.
يَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ مَا قَالُواْ وَلَقَدۡ قَالُواْ كَلِمَةَ ٱلۡكُفۡرِ وَكَفَرُواْ بَعۡدَ إِسۡلَٰمِهِمۡ وَهَمُّواْ بِمَا لَمۡ يَنَالُواْۚ وَمَا نَقَمُوٓاْ إِلَّآ أَنۡ أَغۡنَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ مِن فَضۡلِهِۦۚ فَإِن يَتُوبُواْ يَكُ خَيۡرٗا لَّهُمۡۖ وَإِن يَتَوَلَّوۡاْ يُعَذِّبۡهُمُ ٱللَّهُ عَذَابًا أَلِيمٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۚ وَمَا لَهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ 74
Awọn sọbẹ selu yoo maa fi Ọlọhun Ọba Allah bura niti irọ pipa: nkan ti wọn yoo maa sọ ni wipe eebu kankan ko ti ọdọ rẹ de ọdọ wọn nipa wọn, ati aleebu fun ẹsin rẹ, wọn si ohun ti o de ọdọ rẹ nipa wọn ninu ohun ti o sọ wọn di keferi, wọn si se afihan keferi lẹyin isafihan igbagbọ, paapaa wọn ti gbero ohun ti wọn ko jere rẹ, gẹgẹ bi mimu iparun ba anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, wọn ko tako nkankan ju nkan ti ko tọ ki eniyan tako lọ, ohun ni wipe dajudaju Ọlọhun Ọba mu wọn ri ọrọ eyiti o fi se idẹkun fun Anọbi Rẹ, ti wọn ba ronu piwada lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah kuro nibi sọbẹ selu wọn, ironu piwada wọn yoo jẹ oore fun wọn ju ki wọn wa lori rẹ lọ, ti wọn ba se gunri nibi irnu piwada lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba Allah yoo fi iya ti o nira jẹ wọn ni ile aye pẹlu ki o pa wọn ati ki o mu wọn lẹru, yoo si fi iya ti o nira jẹ wọn ni ọrun pẹlu ki o fi wọn wọ ina, ko si alatilẹyin ti yoo ran wọn lọwọ lati yọ wọn kuri nibi iya, ko si si alaranse ti yoo la wọn kuro nibi iya.
۞وَمِنۡهُم مَّنۡ عَٰهَدَ ٱللَّهَ لَئِنۡ ءَاتَىٰنَا مِن فَضۡلِهِۦ لَنَصَّدَّقَنَّ وَلَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 75
O nbẹ ninu awọn sọbẹ selu ẹniti o se adehun fun Allah, ti o si nsọ bayi wipe: ti Ọlọhun Ọba Allah ba fun wa ninu ọla Rẹ, a o fi tọrọ fun awọn ti o ni bukaata si, a o si wa ninu awọn ẹniire ti isẹ wọn dara.
فَلَمَّآ ءَاتَىٰهُم مِّن فَضۡلِهِۦ بَخِلُواْ بِهِۦ وَتَوَلَّواْ وَّهُم مُّعۡرِضُونَ 76
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun ninu ọla Rẹ, wọn ko pe adehun ti wọn se fun Allah, bikose wipe wọn kọ dukia wọn, wọn ko fi tọrẹ kankan, wọn pẹ yin da wọn si gunri kuro nibi igbagbọ.
فَأَعۡقَبَهُمۡ نِفَاقٗا فِي قُلُوبِهِمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ يَلۡقَوۡنَهُۥ بِمَآ أَخۡلَفُواْ ٱللَّهَ مَا وَعَدُوهُ وَبِمَا كَانُواْ يَكۡذِبُونَ 77
O wa sọ igbẹyin wọn di sọbẹ selu ti o rinlẹ ninu ọkan wọn titi ọjọ igbende; ni ijiya fun wọn lori yiyapa adehun wọn ati lori irọ pipa wọn.
أَلَمۡ يَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ سِرَّهُمۡ وَنَجۡوَىٰهُمۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ عَلَّٰمُ ٱلۡغُيُوبِ 78
Se awọn sọbẹ selu ko wa mọ ni wipe Ọlọhun Ọba mọ ohun ti o pamọ ninu itanjẹ ati ete ni awọn aaye wọn ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun ni O mọ kọkọ? Nkankan ko pamọ fun ninu isẹ wọn, yoo si san wọn lẹsan le lori.
ٱلَّذِينَ يَلۡمِزُونَ ٱلۡمُطَّوِّعِينَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ فِي ٱلصَّدَقَٰتِ وَٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ إِلَّا جُهۡدَهُمۡ فَيَسۡخَرُونَ مِنۡهُمۡ سَخِرَ ٱللَّهُ مِنۡهُمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ 79
Awọn ti wọn nbu awọn olugbagbọ ododo ti wọn nfi ifẹ inu wọn na ohun ti wọn ni ti o kere, awọn ti ko ri nkankan ju nkan kekere lọ, ohun ni nkan ti wọn lagbara, wọn wa nfi wọn se yẹyẹ ni ẹniti o nsọ bayi wipe: kinni ohun ti saara yin yii fẹẹ se?! Ọlọhun Ọba Allah yoo da yẹyẹ wọn silẹ ni ẹsan lori yẹyẹ ti wọn fi awọn olugbagbọ ododo se, bẹẹ ni iya atani lara nbẹ fun wọn.
Jijẹ dandan jija awọn keferi logun ati awọn sọbẹ selu, jija awọn keferi logun pẹlu ọwọ ati oniranran ijagun, ati jija awọn sọbẹ selu logun pẹlu awijare ati ahọn.
Awọn sọbẹ selu jẹ ẹniti o buru ju ninu eniyan toripe wọn jẹ ẹniti o ma ndalẹ, wọn ma nfi aidara pade daadaa.
Ẹri lori jija adehun ati yiyapa rẹ ti yoo sokunfa sọbẹ selu wa ninu awọn aayah naa, o wa di dandan fun olugbafa ki o sọra kuro nibẹ.
Yinyin agbara ti ara ati ti isẹ wa ninu awọn aayah naa, ati wipe o ma nwa ni ipo dukia eleyi si jẹ ipilẹ ti o tobi nibi wiwoyesi ipilẹ ọrọ gbogboogbo ati kiko aleebu ba latara isesi ilusisẹ.