يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٞ فَٱسۡتَمِعُواْ لَهُۥٓۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَن يَخۡلُقُواْ ذُبَابٗا وَلَوِ ٱجۡتَمَعُواْ لَهُۥۖ وَإِن يَسۡلُبۡهُمُ ٱلذُّبَابُ شَيۡٔٗا لَّا يَسۡتَنقِذُوهُ مِنۡهُۚ ضَعُفَ ٱلطَّالِبُ وَٱلۡمَطۡلُوبُ 73
Ẹyin ẹniyan wọn fi apejuwe lelẹ ki ẹ si tẹti gbọ, ki ẹ si woye pẹlu rẹ, dajudaju awọn ẹniti nsin ni oosa ati nkan miran naa yatọ si Allah, wọn ko lee da eesin bi o se kere to nitori ikagara wọn, koda ki gbogbo wọn kojọ lori dida a wọn ko le se ẹda rẹ, ti esinsin ba si mu nkankan ninu ohun ti o dara tabi ohun ti o jọ ọ, wọn ko lagbara lati gba a lọwọ rẹ nitori ikagara wọn lati sẹda esinsin ati gbigba ohunkihun lọwọ rẹ; ikagara wọn hande lori ohun ti o tobi ju eleyi lọ, bawo ni ẹ se wa nsin wọn - pẹlu ikagara wọn - yatọ si Allah?! ẹniti nwa nkan yii lẹ, ohun si ni oosa ti wọn nsin ti ko lagbara lati gba ohun ti esinsin ba mu lọwọ rẹ, bẹẹ ni ẹniti a nwa nkan lọdọ rẹ naa lẹ eyiti se esinsin yii.
مَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ 74
Wọn ko pataki Allah ni paapa pipataki rẹ nitori sinsin apakan ẹda rẹ mọ, dajudaju Allah jẹ alagbara, ninu agbara rẹ ati ogo rẹ ni dida sanmọ ati ilẹ ati ohun ti o nbẹ ninu wọn, Oniyi ni, ẹnikankan ko le bori Rẹ ki a to waa sọ awọn oosa ẹlẹbọ, o lẹ, o si yẹpẹrẹ ko le da nkankan.
ٱللَّهُ يَصۡطَفِي مِنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلٗا وَمِنَ ٱلنَّاسِۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٞ 75
Allah ti mimọ nbẹ fun ma nsẹsa awọn ojisẹ ninu awọn Malaika, o si ma nsẹsa awọn ojisẹ ninu awọn eniyan, O si ma nran apakan awọn Malaika si awọn Anọbi, gege bi Jibril ti O ran si awọn ojisẹ ninu awọn abara, O si nran awọn ojisẹ ninu abara si awọn eniyan, dajudaju Allah jẹ olugbọ ohun ti awọn ẹlẹbọ nsọ nipa awọn ojisẹ Rẹ, O si riran ri ẹniti o sa lẹsa fun isẹ Rẹ.
يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ 76
Ọba ti mimọ nbẹ fun mọ ohun ti awọn ojisẹ ninu Malaika ati awọn eniyan wa lori rẹ siwaju ki o to da wọn ati lẹyin iku wọn, ọdọ Allah nikan si ni gbogbo alamọri yoo sẹri si ni ọjọ igbende nigbati yoo gbe awọn ẹru dide, yoo si san wọn lẹsan lori ohun ti wọn ti siwaju ninu isẹ. ẹri le yin lo
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱرۡكَعُواْ وَٱسۡجُدُواْۤ وَٱعۡبُدُواْ رَبَّكُمۡ وَٱفۡعَلُواْ ٱلۡخَيۡرَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ۩ 77
Ẹyin ti ẹ gba Ọlohun Ọba Allah gbọ, ti wọn si sisẹ pẹlu ounti wọn se lofin fun wọn, ẹ yaa tẹriba ki ẹ si fi ori kanlẹ ninu irun yin fun Allah nikan soso, ki ẹ si maa se rere gẹgẹ bi saara ati ida ibi pọ; ni irankan ki ẹ le jere pẹlu ounti ẹ nwa, ki ẹ si la kuro nibi ounti ẹ nbẹru.
وَجَٰهِدُواْ فِي ٱللَّهِ حَقَّ جِهَادِهِۦۚ هُوَ ٱجۡتَبَىٰكُمۡ وَمَا جَعَلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلدِّينِ مِنۡ حَرَجٖۚ مِّلَّةَ أَبِيكُمۡ إِبۡرَٰهِيمَۚ هُوَ سَمَّىٰكُمُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ مِن قَبۡلُ وَفِي هَٰذَا لِيَكُونَ ٱلرَّسُولُ شَهِيدًا عَلَيۡكُمۡ وَتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِۚ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱعۡتَصِمُواْ بِٱللَّهِ هُوَ مَوۡلَىٰكُمۡۖ فَنِعۡمَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَنِعۡمَ ٱلنَّصِيرُ 78
Ki ẹ si maa gbiyanju si oju ọna Allah ni igbiyanju isafọmọ nitori tiRẹ, Oun ni O sa yin lẹsa, O si se ẹsin yin ni fifuyẹ ti ko si inira nibẹ tabi ilekoko, oju ọna ti o fuyẹ yii ni oju ọna baba yin Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun, paapa julọ Allah ti sọ yin ni olugbafa ninu awọn tira ti o siwaju ati ninu Alukuraani; ki ojisẹ naa le jẹ ẹlẹri le yin lori wipe oun mu de etigbọ yin ohun ti wọn pa lasẹ pe ki o mu de ogongo rẹ ati ki ẹyin naa si le ẹlẹri lori awọn ijọ ti o siwaju, wipe dajudaju awọn ojisẹ wọn mu detigbọ wọn, ki ẹ yaa maa dupẹ fun Allah lori eleyi pẹlu mima kirun ni ojupọnna ti o pe, ki ẹ si maa sọ saka ninu owo yin, ki ẹ si sẹri si ọdọ Allah, ki ẹ tun gbara le E nibi alamọri yin, Oun ti mimọ nbẹ fun ni O to ni olugbẹkẹle fun ẹniti o ba gbẹkẹle ninu awọn olugbagbọ ododo, O si to ni alaranse fun ẹniti o ba wa A ni olusaranse, ki ẹ yaa gbara le E, yoo gba yin, ki ẹ wa aranse lọsi ọdọ Rẹ yoo ran yin se.
Pataki fifi apejuwe lelẹ ki itumọ le hande, o si jẹ oju ọna ikọnilẹkọ ti o gbọngbọ.
Kikagara awọn oosa nipa ẹda ti o kere julọ jẹ itọka lori kikagara rẹ nipa ẹda miran ti o yatọ si.
Okunfa mimu nkan miran mọ Allah ni aigbe titobi fun Allah.
Fifi iroyin agbara ati iyi ti si Allah rinlẹ ati pataki ki olugbagbọ ododo mu awọn itumọ iroyin yii si tosi.