وَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَئِمَّةٗ يَهۡدُونَ بِأَمۡرِنَا وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡهِمۡ فِعۡلَ ٱلۡخَيۡرَٰتِ وَإِقَامَ ٱلصَّلَوٰةِ وَإِيتَآءَ ٱلزَّكَوٰةِۖ وَكَانُواْ لَنَا عَٰبِدِينَ 73
A sọ wọn di asiwaju ti awọn eniyan ntẹle nibi rere, wọn npe awọn eniyan lọ si ibi ijọsin Allah nikan soso pẹlu iyọnda lati ọdọ Rẹ ti o ga julọ, a si ransẹ imisi si wọn ki wọn le se rere, ki wọn si le maa kirun ni ojupọnna pipe, ki wọn si maa yọ saka, wọn si jẹ ẹniti o ntẹriba fun Wa.
وَلُوطًا ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗا وَنَجَّيۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلَّتِي كَانَت تَّعۡمَلُ ٱلۡخَبَٰٓئِثَۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمَ سَوۡءٖ فَٰسِقِينَ 74
A ko Luth ni iyanju ọrọ nibi ija, a si tun fun ni imọ nipa ọrọ ẹsin rẹ, bẹẹ ni a la a kuro nibi iya eyiti a sọkalẹ fun awọn ara abule rẹ (saduumi) eyiti awọn eniyan bẹ nse ibajẹ, dajudaju wọn jẹ ijọ ibajẹ ti wọn jade kuro nibi itẹle asẹ Ọlọhun Ọba wọn.
وَأَدۡخَلۡنَٰهُ فِي رَحۡمَتِنَآۖ إِنَّهُۥ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 75
A si fi wọ sinu ikẹ Wa nigbati a la a kuro nibi iya eyiti o sẹlẹ si awọn ijọ rẹ, dajudaju o wa ninu awọn ẹniire ti nronu nipa asẹ Wa, ti wọn si njawọ kuro nibi ẹkọ Wa.
وَنُوحًا إِذۡ نَادَىٰ مِن قَبۡلُ فَٱسۡتَجَبۡنَا لَهُۥ فَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ 76
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nipa itan Nuha; nigbati o pe Ọlọhun Ọba Allah siwaju Ibrahim ati Luth, a si jẹpe rẹlori fifun ni ohun ti o nbeere fun, bẹẹni a la a, a si la awọn ara ile rẹ kuro nibi ibanujẹ ti o tobi.
وَنَصَرۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَآۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمَ سَوۡءٖ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ أَجۡمَعِينَ 77
A la a kuro nibi ete awọn ijọ eyiti wọn pe awọn amin ti o ntọka si otitọ rẹ ti A fi kun lọwọ ni irọ, dajudaju wọn jẹ ijọ ibajẹ ati aburu, a si fi itẹri pa wọn run ni apapọ.
وَدَاوُۥدَ وَسُلَيۡمَٰنَ إِذۡ يَحۡكُمَانِ فِي ٱلۡحَرۡثِ إِذۡ نَفَشَتۡ فِيهِ غَنَمُ ٱلۡقَوۡمِ وَكُنَّا لِحُكۡمِهِمۡ شَٰهِدِينَ 78
Tun ranti - irẹ ojisẹ - itan Dawud ati ọmọrẹ Sulayman ti ọla nbẹ fun wọn nigbati awọn mejeeji dajọ nibi isẹlẹ ti wọn gbe wa ba wọn nipa ọrọ isẹlẹ awọn onija meji; ikan ninu wọn ni aguntan ti o fan ka ni oru si inu oko ẹnikeji rẹ, ti o si ba a jẹ, awa si jẹ olujẹri si idajọ dauda ati Sulayman, nkankan ko pamọ fun wa nibi idajọ awọn mejeeji.
فَفَهَّمۡنَٰهَا سُلَيۡمَٰنَۚ وَكُلًّا ءَاتَيۡنَا حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَسَخَّرۡنَا مَعَ دَاوُۥدَ ٱلۡجِبَالَ يُسَبِّحۡنَ وَٱلطَّيۡرَۚ وَكُنَّا فَٰعِلِينَ 79
A fun Sulayman ni agboye idajọ naa yatọ si baba rẹ Dawud, ati Dawud ati Sulayman ni a fun ni ijanọbi ati imọ nipa idajọ ẹsin, a ko fi sẹsa fun Sulayman nikan soso, a si mu oke di ohun ti o ntẹle Dawud nibi sise afọmọ iru afọmọ rẹ, bẹẹ ni A mu ẹyẹ tẹ le e, Awa ni a se igbagbọye yii ati fifun ni idajọ, imọ ati imusin.
وَعَلَّمۡنَٰهُ صَنۡعَةَ لَبُوسٖ لَّكُمۡ لِتُحۡصِنَكُم مِّنۢ بَأۡسِكُمۡۖ فَهَلۡ أَنتُمۡ شَٰكِرُونَ 80
A si mọ Dawud yatọ si Sulayman rirọ asọ irin ki o le ma daabobo yin nibi ipani nkan ija ni ara yin, njẹ ẹyin yoo - ẹyin eniyan - jẹ oludupẹ fun awọn idẹkun eyiti Ọlọhun Allah se le yin lori yii?!
وَلِسُلَيۡمَٰنَ ٱلرِّيحَ عَاصِفَةٗ تَجۡرِي بِأَمۡرِهِۦٓ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَاۚ وَكُنَّا بِكُلِّ شَيۡءٍ عَٰلِمِينَ 81
A si tun rẹ atẹgun ti fifẹ rẹ le fun Sulayman, ti o nfẹ lati ibi asẹ Rẹ, ti o ba pasẹ fun un lọsi ilẹ samu eyiti a fi ibukun si ori rẹ nitori awọn Anọbi ti a gbe dide nibẹ ati ati rere ti a tẹ pẹrẹsẹ sibẹ, Awa si jẹ onimimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun wa nibẹ.
Sise rere ati irun kiki ati saka yiyọ wa ninu ohun ti gbogbo ofin sanmọ pa ẹnu pọ le lori.
Gigunle ibajẹ jẹ okunfa sisẹlẹ iya yanyan.
Isatunse jẹ okunfa kiko sinu ikẹ Allah.
Adua jẹ okunfa nibi lila kuro nibi isoro.