قَالَتۡ يَٰوَيۡلَتَىٰٓ ءَأَلِدُ وَأَنَا۠ عَجُوزٞ وَهَٰذَا بَعۡلِي شَيۡخًاۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٌ عَجِيبٞ 72
Saarata sọ lẹyin igbati awọn Malaika fun ni iro idunnu ti o jọ ọ loju yii: bawo ni mo se fẹ bimọ, ti mo si ti jẹ agbalagba ti o ti jakan kuro nibi ọmọ, ọkọ mi yii naa si ti de ọjọ ori agbalagba?! Dajudaju bibimọ nibi iru ipo yii jẹ nkan eemọ, bẹẹ ni ko ba adamọ mu.
قَالُوٓاْ أَتَعۡجَبِينَ مِنۡ أَمۡرِ ٱللَّهِۖ رَحۡمَتُ ٱللَّهِ وَبَرَكَٰتُهُۥ عَلَيۡكُمۡ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِۚ إِنَّهُۥ حَمِيدٞ مَّجِيدٞ 73
Awọn malaika sọ fun sarata nigbati o se eemọ nibi iro idunnu yii: se iwọ yoo maa se eemọ nibi akọsilẹ Ọlọhun Ọba ati kadara Rẹ ni? Iro rẹ ko yẹ ki o pamọ fun wipe dajudaju Allah ni agbara lori eleyi, ikẹ Allah ati awọn ibukun rẹ wa le yin lori - ẹyin ara ile Ibrahim -, dajudaju Allah jẹ gbọpẹgbọpẹ nibi awọn iroyin rẹ ati isẹ Rẹ, ọlọla ati agbega.
فَلَمَّا ذَهَبَ عَنۡ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلرَّوۡعُ وَجَآءَتۡهُ ٱلۡبُشۡرَىٰ يُجَٰدِلُنَا فِي قَوۡمِ لُوطٍ 74
Nigbati ko si ipaya fun Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun eyiti o ri lati ọdọ awọn alejo rẹ ti wọn ko le jẹ onjẹ rẹ, ti o si ti mọ wipe malaika ni wọn, ti iro idunnu si waa ba wipe yoo bi mọ, tii se Ishaaq, lẹyin igba naa ni yakub, o wa bẹrẹ si ni jiyan pẹlu awọn ojisẹ wa lori ọrọ ijọ awọn Luth; boya wọn le lọra iya kuro fun wọn tabi o seese ki wọn la Luth ati ijọ rẹ.
إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ لَحَلِيمٌ أَوَّٰهٞ مُّنِيبٞ 75
Dajudaju Ibrahim jẹ onitẹmọra, o si nifẹ si lilọ iya lara, ọlọpọ ifara rolẹ fun Ọlọhun Ọba ati ọlọpọ adua ni ẹniti nsẹri si ọdọ Rẹ.
يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَآۖ إِنَّهُۥ قَدۡ جَآءَ أَمۡرُ رَبِّكَۖ وَإِنَّهُمۡ ءَاتِيهِمۡ عَذَابٌ غَيۡرُ مَرۡدُودٖ 76
Awọn Malaika sọpe, irẹ Ibrahim gunri kuro nibi iyan jija lori ijọ Luth, paapaa asẹ ti wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ wipe iya ti o ti kọ yoo sẹlẹ ti wọn lori, ati wipe dajudaju iya ti o tobi yoo waa ba ijọ Luth, iyan jija tabi adua ko le mu kuro fun wọn.
وَلَمَّا جَآءَتۡ رُسُلُنَا لُوطٗا سِيٓءَ بِهِمۡ وَضَاقَ بِهِمۡ ذَرۡعٗا وَقَالَ هَٰذَا يَوۡمٌ عَصِيبٞ 77
Nigbati awọn Malaika de ba Luth ni isesi ọkunrin, wiwa wọn buru, igbaaya rẹ si pin nitori ipaya rẹ lori awọn ijọ rẹ ti o nba ọkunrin lopọ niti adun dipo awọn obinrin, Luth waa sọ wipe: ọjọ yii jẹ ọjọ lile; nitori ero rẹ wipe awọn ijọ rẹ yoo bori awọn alejo rẹ.
وَجَآءَهُۥ قَوۡمُهُۥ يُهۡرَعُونَ إِلَيۡهِ وَمِن قَبۡلُ كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّئَِّاتِۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ هَٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِي هُنَّ أَطۡهَرُ لَكُمۡۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُخۡزُونِ فِي ضَيۡفِيٓۖ أَلَيۡسَ مِنكُمۡ رَجُلٞ رَّشِيدٞ 78
Bakanna awọn ijọ Luth lọọ ba Luth ni yarayara ni ẹniti o ngbero lati se ibajẹ pẹlu awọn alejo rẹ, siwaju eleyi isesi wọn ni ki wọn o maa ba awọn ọkunrin lopọ niti adun dipo awọn obinrin, Luth sọ ni ẹniti o ndaabobo awọn ijọ rẹ, ni ẹniti o si nwi awijare fun ara rẹ niwaju awọn alejo rẹ: awọn wọnyi ni awọn ọmọbinrin mi ninu awọn ọmọbinrin yin ki ẹ yaa fẹ wọn, awọn wọnyi mọ fun yin ju ki ẹ se ibajẹ lọ, ki ẹ ya paya Allah, ẹ mase se agbere pẹlu awọn alejo mi, kii waa se wipe -ẹyin ijọ mi- ọkunrin ti o ni laakaye gidi wa ninu yin ni, ti o le kọ fun yin kuro nibi isẹ ibajẹ yii?!
قَالُواْ لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَا لَنَا فِي بَنَاتِكَ مِنۡ حَقّٖ وَإِنَّكَ لَتَعۡلَمُ مَا نُرِيدُ 79
Awọn ijọ rẹ sọ fun wipe: paapaa, o ti mọ -irẹ Luth- dajudaju a ko ni bukaata si awọn ọmọbinrin rẹ ati awọn ọmọbinrin inu ijọ rẹ, ko si si adun kankan paapaa o ti mọ nkan ti a nfẹ, awa ko fẹ ju awọn ọmọkunrin lọ.
قَالَ لَوۡ أَنَّ لِي بِكُمۡ قُوَّةً أَوۡ ءَاوِيٓ إِلَىٰ رُكۡنٖ شَدِيدٖ 80
Luth sọpe: ko si agbara kankan fun mi ti mo fi le kọ fun yin tabi mọlẹbi kan ti yoo kọ fun mi, ti maa fi waa se gaga laarin yin ati awọn alejo mi.
قَالُواْ يَٰلُوطُ إِنَّا رُسُلُ رَبِّكَ لَن يَصِلُوٓاْ إِلَيۡكَۖ فَأَسۡرِ بِأَهۡلِكَ بِقِطۡعٖ مِّنَ ٱلَّيۡلِ وَلَا يَلۡتَفِتۡ مِنكُمۡ أَحَدٌ إِلَّا ٱمۡرَأَتَكَۖ إِنَّهُۥ مُصِيبُهَا مَآ أَصَابَهُمۡۚ إِنَّ مَوۡعِدَهُمُ ٱلصُّبۡحُۚ أَلَيۡسَ ٱلصُّبۡحُ بِقَرِيبٖ 81
Awọn Malaika sọ fun Luth ẹniti ọla nbẹ fun wipe: irẹ Luth, awa jẹ ojisẹ ti Ọlọhun Ọba Allah ran nisẹ, awọn ijọ rẹ ko le fi suta kankan se ọ, yara mu awọn eniyan rẹ jade kuro ninu abule yii loru ni asiko ti okunkun biribiri wa, ki ẹnikẹni ninu yin ma se woye ni ohun ti yoo waye lẹyin rẹ ayaafi obinrin rẹ ni yoo gboju kuro niti iyapa; nitori wipe iya ti o ba sẹlẹ si ijọ rẹ yoo sẹlẹ si i, dajudaju adehun iparun wọn jẹ owurọ kutukutu, o si jẹ adehun ti o sun mọ.
Alaye ọla ti nbẹ fun ipo aayo Ọlọhun Ọba Allah anọbi Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun ati awọn ara ile rẹ.
Sise lofin iyan jija pẹlu ẹniti a ba rankan igbagbọ ni ọdọ rẹ siwaju ki a to gbe lọ si ọdọ adajọ.
Sise alaye aburu ati ibajẹ isẹ ijọ Luth.