وَحَسِبُوٓاْ أَلَّا تَكُونَ فِتۡنَةٞ فَعَمُواْ وَصَمُّواْ ثُمَّ تَابَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ ثُمَّ عَمُواْ وَصَمُّواْ كَثِيرٞ مِّنۡهُمۡۚ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ 71
Wọn nlero wipe jade adehun ati asọtẹlẹ ati irọ pipa wọn pẹlu pipa ti wọn npa awọn Anọbi, inira kankan ko lee ti ẹyin rẹ yọ fun awọn, bayi nkan ti wọn ko lero ti ẹyin rẹ yọ jade, wọn wa fọju kuro nibi ododo, wọn ko mọ ọna de ibẹ, wọn diti kuro nibi gbigbọ gbigba, lẹyin igba naa Ọlọhun Ọba Allah waa gba ironu piwada wọn, niti sise ọla lati ọdọ Rẹ, lẹyin igba naa ni wọn tun waa fọju kuro nibi ododo, wọn tun diti kuro nibi gbigbọ ọ, eleyi sẹlẹ si ọpọlọpọ ninu wọn, Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluri nkan ti wọn nse ni isẹ, nkankan ko pamọ ni ọdọ Rẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
لَقَدۡ كَفَرَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡمَسِيحُ ٱبۡنُ مَرۡيَمَۖ وَقَالَ ٱلۡمَسِيحُ يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمۡۖ إِنَّهُۥ مَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدۡ حَرَّمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ ٱلۡجَنَّةَ وَمَأۡوَىٰهُ ٱلنَّارُۖ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٖ 72
Paapaa awọn nasaara ti di keferi, ti wọn nsọ wipe, Ọlọhun Ọba Allah ni Isa ọmọ Maryam; nitori wipe wọn se afiti ẹniti a nsin si ọdọ ẹniti kii se Ọlọhun Ọba Allah, ti o si jẹ wipe ẹni mimọ ọmọ Maryam funraarẹ sọ wọn wipe: ẹyin arọmọdọmọ Israheel, ẹ maa sin Ọlọhun Ọba Allah nikan, Oun ni Ọlọhun mi ati Ọlọhun yin, awa nibi sinsin bakanna ni a se ri, eleyi ri bẹẹ nitori wipe ẹniti o ba mu ẹbọ mọ Ọlọhun Ọba Allah, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti se wiọ Alujannah ni eewọ fun lailai, ibudari rẹ ni inu ina jahanamọ, ko si alaranse tabi oluranlọwọ fun ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah tabi oluyọni tii yoo yọ ninu iya ti o nreti rẹ.
لَّقَدۡ كَفَرَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ ثَالِثُ ثَلَٰثَةٖۘ وَمَا مِنۡ إِلَٰهٍ إِلَّآ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۚ وَإِن لَّمۡ يَنتَهُواْ عَمَّا يَقُولُونَ لَيَمَسَّنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ 73
Paapaa, awọn nassaara ti di keferi, awọn ti wọn nsọ bayi wipe: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah kojọ lati ibi nkan mẹta, awọn nkan naa ni yii: baba, ọmọ ati ẹmin mimọ, giga Ọlọhun Ọba Allah kuro nibi gbolohun wọn yii, ti giga naa si tobi, Ọlọhun Ọba Allah kii se onka ti a nka, dajudaju Oun jẹ ọba aaso, ti ko si orogun fun Un, ti wọn ko ba tako ọrọ eyiti o buru yii, iya tii tani lara yoo kan wọn.
أَفَلَا يَتُوبُونَ إِلَى ٱللَّهِ وَيَسۡتَغۡفِرُونَهُۥۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 74
Se awọn wọnyi ko nii sẹri kuro nibi ọrọ wọn, ni ẹniti yoo sẹri pada si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ninu rẹ, ti wọn yoo si wa aforijin lori nkan ti wọn se pẹlu ẹbọ ninu rẹ? ! Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluforijini fun ẹniti o ba ronu piwada kuro nibi eyikeyi ẹsẹ ti o wu ki o jẹ, koda ki baa se ẹsẹ isekeferi siI, O si tun jẹ olukẹni fun gbogbo awọn olugbagbọ ododo.
مَّا ٱلۡمَسِيحُ ٱبۡنُ مَرۡيَمَ إِلَّا رَسُولٞ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِ ٱلرُّسُلُ وَأُمُّهُۥ صِدِّيقَةٞۖ كَانَا يَأۡكُلَانِ ٱلطَّعَامَۗ ٱنظُرۡ كَيۡفَ نُبَيِّنُ لَهُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ ثُمَّ ٱنظُرۡ أَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ 75
Ẹni mimọ Isa ọmọ Maryam ko jẹ nkankan ju ojisẹ kan ninu awọn ojisẹ lọ, yoo sẹlẹ sii, iku ti yoo sẹlẹ si awọn naa, iya rẹ Maryam jẹ ọlọpọlọ ootọ, ati ẹniti awọn eniyan ngba ọrọ rẹ lododo, awọn mejeeji a maa jẹhun nitori wipe wọn ni bukaata sii, bawo ni awọn mejeeji se fẹẹ jẹ ọlọhun meji, ti wọn si ni bukaata si ounjẹ jijẹ? ! Woye - ire ojise - ni iwoye ti jindo: bawo ni a se le salaye fun ọ awọn amin ti o ntọka si ijọkan soso ati jijẹ aidara ikọja ẹnu aala wọn nibi fifi ẹniti a njọsin fun ti si ẹniti kii se Ọlọhun Ọba Allah, pẹlu bẹẹ naa, wọn jẹ ẹniti o nse bi ẹniti ko mọ awọn amin wọnyi, lẹyin igba naa ki o wuye ni iwoye ti o jindo: bi wọn se nyi kuro nibi ododo ni yiyi gidi, ti awọn amin yii si fi oju han ti o ntọka si ijọkan soso Allah.
قُلۡ أَتَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَمۡلِكُ لَكُمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗاۚ وَٱللَّهُ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 76
Sọ wipe ire ojise - ni ẹniti nwi awijare le wọn lori nibi ijọsin wọn fun ẹniti o yatọ si Ọlọhun Ọba Allah: se ọ o maa se nkan ti ko le mu anfaani wa fun yin, ti ko si le mu aburu kuro fun yin? ! O jẹ ẹniti o kagara, Ọlọhun Ọba Allah si mọ kanga kuro nibi ikagaara, Ọlọhun Ọba Allah nikan ni olugbọ gbogbo ọrọ yin, nkankan ko ta danu fun yin nibẹ, Oun ni onimiọ pẹlu gbogbo ise yin, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, Yoo si san yin lẹsan le lori.
قُلۡ يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا تَغۡلُواْ فِي دِينِكُمۡ غَيۡرَ ٱلۡحَقِّ وَلَا تَتَّبِعُوٓاْ أَهۡوَآءَ قَوۡمٖ قَدۡ ضَلُّواْ مِن قَبۡلُ وَأَضَلُّواْ كَثِيرٗا وَضَلُّواْ عَن سَوَآءِ ٱلسَّبِيلِ 77
Sọpe - ire ojise - fun awọn nasaara, ẹ mase kọja ẹnu aala nibi nkan ti wọn pa yin lasẹ rẹ, nibi itẹle ododo, ẹ ma si se kọja aala nibi gbigbe titobi ẹniti o payin lasẹ ki ẹ pataki Ọlọhun – gẹgẹ bi awọn Anọbi, ki ẹ wa di adisọkan ijọsin fun wọn gẹgẹ bi ẹ se se pẹlu Isa ọmọ Maryam, nitori ikọse awọn ẹni isaaju yin, ninu awọn ẹni anu, awọn ti wọn ti sọ ọpọlọpọ eniyan nu, wọn si ti sina kuro ni oju ọna ootọ.
Sise alaye ijẹ keferi awọn nasaara pẹlu didi adisọkan ẹniti a njọsin fun si ẹni mimọ ki ọla maa ba ati alaye nipa aidara rẹ ati pipepe fun ironu piwada nibẹ.
Ninu ẹri jijẹ abara ẹni mimọ ati iya rẹ: ohun ni jijẹ ounjẹ awọn mejeeji, ati sise nkan ti yoo ti ẹyin ounjẹ jijẹ jade.
Aisi agbara lori mimu inira duro ati mimu anfaani bani wa ninu ẹri ti o fi oju han lori ailẹtọ si mima iroyin ijọsin fun apakan ninu wọn; nitori wipe wọn jẹ ẹniti o kagara.
Ikọ fun ni kuro nibi sise aseju ati ikọja ẹnu aala nibi iba awọn ẹniire lopọ ninu awọn ẹda Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.