يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لِمَ تَلۡبِسُونَ ٱلۡحَقَّ بِٱلۡبَٰطِلِ وَتَكۡتُمُونَ ٱلۡحَقَّ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 71
Ẹyn ti ẹ ni tira, kinni o de ti nda ododo ti A sọkalẹ si inu awọn tira yin papọ mọ ibajẹ lati ọdọ ara yin, ti ẹ si tun nfi ohun ti o jẹ ododo nibẹ ati imọna pamọ, ati wipe ninu rẹ ni nini alaafia jijẹ ti Muhammad jẹ Anọbi, ti o si jẹ wipe ẹyin mọ ododo yatọ si irọ, ati imọna yatọ si anu.
وَقَالَت طَّآئِفَةٞ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ ءَامِنُواْ بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَجۡهَ ٱلنَّهَارِ وَٱكۡفُرُوٓاْ ءَاخِرَهُۥ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 72
Awọn ikọ kan ninu awọn alufa awọn yahuudi waa sọ wipe: ẹ ni igbagbọ nita pẹlu Alukuraani eyiti wọn sọkalẹ fun awọn olugbagbọ ododo ni akọkọ ọjọ, ki ẹ si se aigbagbọ pẹlu rẹ ni igbẹyin rẹ, oseese ki wọn ke gbajari nibi ẹsin wọn pẹlu idi aini igbagbọ yin pẹlu rẹ, lẹyin ini igbagbọ yin, ti wọn yoo wa pada kuro nibẹ ni ẹniti nsọ wipe: awọn ni o ni imọ ju wa lọ pẹlu awọn tira Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe ni paapaa wọn ti sẹri pada kuro nibẹ.
وَلَا تُؤۡمِنُوٓاْ إِلَّا لِمَن تَبِعَ دِينَكُمۡ قُلۡ إِنَّ ٱلۡهُدَىٰ هُدَى ٱللَّهِ أَن يُؤۡتَىٰٓ أَحَدٞ مِّثۡلَ مَآ أُوتِيتُمۡ أَوۡ يُحَآجُّوكُمۡ عِندَ رَبِّكُمۡۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡفَضۡلَ بِيَدِ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ 73
Wọn tun sọ bakanna wipe: ẹ mase gba lododo ayaafi ẹniti o ba jẹ olutẹle ẹsin yin, sọ - irẹ ojisẹ - wipe: imọna lọsi bi ododo oun ni imọna Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) kii se oun ti ẹ wa lori rẹ ninu ikurọmọni ati igbẹrugbọnri niti ibẹru ki wọn fun ẹnikan ninu ọla iru oun ti wọn fun yin, tabi ibẹru ki wọn ja yin niyan ni ọdọ Ọlọhun Ọba yin, ti o bajẹ wipe ẹ se afirinlẹ oun ti wọn sọkalẹ fun wọn, sọ - irẹ ojisẹ - dajudaju ọla, ọwọ Ọlọhun Ọba Allah ni o wa, o si ma nfun ẹniti o ba fẹ ninu awọn ẹru rẹ, ọla Rẹ ko dawa lori ijọ kan yatọ si ijọ kan, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Olugbaaye ọla, Olumọ ẹniti o ni ẹtọ sii.
يَخۡتَصُّ بِرَحۡمَتِهِۦ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ 74
O ma nse ẹsa ẹniti O ba wu U pẹlu ikẹ Rẹ ninu awọn ẹda Rẹ, Yoo waa se ọla fun un pẹlu imọna ati jijẹ anọbi ati oniranran ọrẹ, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Ọlọla ti o tobi, ti ko si aala fun un.
۞وَمِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مَنۡ إِن تَأۡمَنۡهُ بِقِنطَارٖ يُؤَدِّهِۦٓ إِلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّنۡ إِن تَأۡمَنۡهُ بِدِينَارٖ لَّا يُؤَدِّهِۦٓ إِلَيۡكَ إِلَّا مَا دُمۡتَ عَلَيۡهِ قَآئِمٗاۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُواْ لَيۡسَ عَلَيۡنَا فِي ٱلۡأُمِّيِّۧنَ سَبِيلٞ وَيَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ 75
Ati wipe o nbẹ ninu wọn ni tira, ẹniti o jẹ wipe ti o ba fi ọkan tan lori owo ti o pọ, yoo da ohun ti o fi ọkan tan lori rẹ pada si ọdọ rẹ, ati wipe o si nbẹ ninu wọn ẹniti o jẹ wipe ti o ba wa ifọkantan lori owo kekere, ko nii da ohun ti o fi ọkan tan lori rẹ pada si ọdọ rẹ, ayaafi ti o ba nlọ lori itẹpẹlẹ mọ pẹlu bibeere ati idajọ, nkan naa waye nitori idi gbolohun wọn ati ero wọn eyiti ko dara: ko si fun wa ni ọdọ awọn larubawa ati jijẹ owo wọn ẹsẹ kankan; toripe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah O se ni ẹtọ fun wa, wọn nsọ irọ yii, ti o si jẹ wipe wọn mọ dida adapa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah.
بَلَىٰۚ مَنۡ أَوۡفَىٰ بِعَهۡدِهِۦ وَٱتَّقَىٰ فَإِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُتَّقِينَ 76
Alamọri ki ri bi wọn se lero bikose wipe inira nbẹ fun wọn, ati wipe sugbọn ẹniti o ba pe adehun rẹ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ninu nini igbagbọ pẹlu Rẹ ati pẹlu awọn ojisẹ Rẹ, ti o si tun pẹ adehun rẹ pẹlu awọn eniyan, ti o waa da ifọkantan pada, ti o si tun pawa Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ, ati jijina si awọn ohun ti O kọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ma nnifẹ awọn olupaya, ati wipe Yoo pada san wọn lẹsan lori nkan naa, ni ẹsan ti o ni apọnle ju.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَشۡتَرُونَ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ وَأَيۡمَٰنِهِمۡ ثَمَنٗا قَلِيلًا أُوْلَٰٓئِكَ لَا خَلَٰقَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ ٱللَّهُ وَلَا يَنظُرُ إِلَيۡهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 77
Dajudaju awọn ti wọn nse pasi-paarọ pẹlu asọtẹlẹ Ọlọhun Ọba Allah fun wọn pẹlu titẹle ohun ti o sọkalẹ ninu tira Rẹ, ti O si tun ran awọn ojisẹ Rẹ pẹlu rẹ ati awọn ibura wọn eyiti wọn ja pẹlu pipe adehun Ọlọhun Ọba Allah, wọn nse pasi-paarọ pẹlu rẹ ni ipaarọ kan ti o kere ninu igbadun aye, ti ko si si ipin kankan fun wọn ninu ẹsan ọjọ ikẹyin, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ko nii ba wọn sọrọ pẹlu oun ti yoo dun wọn ninu, ko si tun nii wo ọdọ wọn, ni wiwo ti ikẹ ni Ọjọ Igbende, kosi ni fowon mo ninu idoti ese won ati aigbagbo won, ati wipe iya ẹlẹta-elero nbẹ fun wọn.
O nbẹ ninu awọn aafa awọn ti wọn ni tira, ẹniti yoo maa tan awọn ti wọn tẹle ilana wọn, ti ko si ni se alaye ododo fun wọn eyiti awọn tira wọn tọka si, ti awọn ojisẹ wọn si mu wa.
Ninu awọn atẹgun aini igbagbọ ni wiwọle si inu ẹsin ati dida iyemeji sibẹ lati inu.
Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) Oun ni Olutani lọrẹ, Olugbọla fun ni, O ma nfun ẹniti O ba wu U pẹlu ọla Rẹ, O si ma nkọ fun ẹniti o ba wu U pẹlu deede Rẹ ati oye Rẹ, ọwọ wọn ko si nii tẹ ọla Rẹ ayaafi pẹlu titẹle.
Gbogbo pasipaarọ ni ile aye nipa nini igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ati pipẹ adehun Rẹ - koda ko tobi - ohun ti o yẹpẹrẹ ni ni iwaju ẹsan ọjọ ikẹyin ati igbega rẹ.